Fò sí àkóónú

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa God

662 ẹsẹ · 46 abala

Àwọn ẹsẹ Bíbélì pàtàkì

Sẹ́ nípa ìwé
  1. nítorí pé Ọlọ́run kò fún un ní ọgbọ́n, bẹ́ẹ̀ ni kò sì fi ìpín òye fún un.

  2. Nígbà tí ó gbé ara sókè, ó gan ẹṣin àti ẹlẹ́ṣin.

  3. “Ìwọ ni ó fi agbára fún ẹṣin bí, tàbí ṣé ìwọ ni ó fi gọ̀gọ̀ wọ ọrùn rẹ̀ ní aṣọ?

  4. Ìwọ le mú fò sókè bí ẹlẹ́ǹgà? Ògo èémí imú rẹ ní ẹ̀rù ńlá.

  5. Ó fi ẹsẹ̀ halẹ̀ nínú àfonífojì, ó sì yọ̀ nínú agbára rẹ̀; ó lọ jáde láti pàdé àwọn ìhámọ́ra ogun.

  6. Ó fi ojú kékeré wo ẹ̀rù, àyà kò sì fò ó; bẹ́ẹ̀ ni kì í sì í padà sẹ́yìn kúrò lọ́wọ́ idà.

  7. Lọ́dọ̀ rẹ ni apó-ọfà ń mì pẹkẹpẹkẹ, àti ọ̀kọ̀ dídán àti àpáta.

  8. Ó fi kíkorò ojú àti ìbínú ńlá gbé ilé mi, bẹ́ẹ̀ ni òun kò sì gbà á gbọ́ pé, ìró ìpè ni.

  9. Ó wí nígbà ìpè pé, Háà! Háà! Ó sì gbóhùn ogun lókèèrè réré, igbe àwọn balógun àti ìhó ayọ̀ ogun wọn.

  10. “Àwòdì ha máa ti ipa ọgbọ́n rẹ̀ fò sókè, tí ó sì na ìyẹ́ apá rẹ̀ sí ìhà gúúsù?

  11. Idì ha máa fi àṣẹ rẹ̀ fò sókè, kí ó sì lọ tẹ́ ìtẹ́ rẹ̀ sí òkè gíga?

  12. Ó ń gbé, ó sì ń wò ní orí àpáta, lórí pàlàpálá òkúta àti ibi orí òkè.

  13. Láti ibẹ̀ lọ ni ó ti ń wá oúnjẹ kiri, ojú rẹ̀ sì ríran rí òkè réré.

  14. Àwọn ọmọ rẹ̀ pẹ̀lú a máa mu ẹ̀jẹ̀, níbi tí òkú bá gbé wà, níbẹ̀ ni òun wà pẹ̀lú.”

  15. Olúwa dá Jobu lóhùn sí pẹ̀lú, ó sì wí pé,

  16. “Ẹni tí ń bá Olódùmarè wíjọ́ yóò ha kọ ní ẹ̀kọ́? Ẹni tí ń bá Ọlọ́run wí jẹ́ kí ó dáhùn!”

  17. Nígbà náà ni Jobu dá Olúwa lóhùn wá ó sì wí pé,

  18. “Kíyèsi i, ẹ̀gbin ni èmi—ohun kí ni èmi ó dà? Èmi ó fi ọwọ́ mi le ẹnu mi.

  19. Ẹ̀ẹ̀kan ní mo sọ̀rọ̀, ṣùgbọ́n èmi kì yóò tún sọ mọ́; lẹ́ẹ̀kejì ni, èmi kò sì le ṣe é mọ́.”

  20. Nígbà náà ní Olúwa dá Jobu lóhùn láti inú ìjì àyíká wá, ó sì wí pé,

  21. “Di àmùrè gírí ní ẹgbẹ́ rẹ bí ọkùnrin, èmi ó bi ọ léèrè, kí ìwọ kí ó sì dá mi lóhùn.

  22. “Ìwọ ha fẹ́ mú ìdájọ́ mi di asán? Ìwọ ó sì dá mi lẹ́bi, kí ìwọ lè ṣe olódodo.

  23. Ìwọ ni apá bí Ọlọ́run tàbí ìwọ lè fi ohùn sán àrá bí òun?

  24. Fi ọláńlá àti ọlá ìtayọ rẹ̀ ṣe ara rẹ ní ọ̀ṣọ́, tí ó sì fi ògo àti títóbi ọ̀ṣọ́ bo ara ní aṣọ.

  25. Mú ìrunú ìbínú rẹ jáde; kíyèsí gbogbo ìwà ìgbéraga rẹ kí o sì rẹ̀ ẹ́ sílẹ̀.