Skip to content

Tabor

5 verses

32.6800, 35.3900 Wo lórí Google Maps

Àwọn ẹsẹ tí ó mẹ́nu kan Tabor

  1. Ààlà náà sì dé Tabori, Ṣahasuma, àti Beti-Ṣemeṣi, ó sì pin ní Jordani. Wọ́n sì jẹ́ ìlú mẹ́rìndínlógún àti ìletò wọn.

  2. Gideoni bi Seba àti Salmunna pé, “Irú ọkùnrin tí ẹ pa ní Tabori, báwo ni wọ́n ṣe rí?” “Àwọn ọkùnrin náà dàbí rẹ ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn dàbí ọmọ ọba,” ní ìdáhùn wọn.

  3. Gúúsù àti àríwá ìwọ ni ó dá wọn; Tabori àti Hermoni ń fi ayọ̀ yin orúkọ rẹ.

  4. “Bí èmi ti wà láààyè,” ni ọba, ẹni tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí pé, “Nítòótọ́ gẹ́gẹ́ bí Tabori láàrín àwọn òkè àti gẹ́gẹ́ bi Karmeli lẹ́bàá Òkun bẹ́ẹ̀ ni òun yóò dé.

  5. “Ẹ gbọ́ èyí, ẹ̀yìn àlùfáà! Ẹ fetísílẹ̀ ẹ̀yin ọmọ Israẹli! Ẹ gbọ́, ẹ̀yìn ilé ọba! Ìdájọ́ yìí kàn yín. Ẹ ti jẹ́ ẹ̀bìtì ní Mispa àwọ̀n ti a nà sílẹ̀ lórí Tabori.