Skip to content

Zalmunna

9 ẹsẹ

Àwọn ẹsẹ tí ó mẹ́nu kan Zalmunna

  1. Ó wí fún àwọn ọkùnrin Sukkoti pé, “Ẹ fún àwọn ọmọ-ogun mi ní oúnjẹ díẹ̀, nítorí ó ti rẹ̀ wọ́n, èmi sì ń lépa Seba àti Salmunna àwọn ọba Midiani.”

  2. Ṣùgbọ́n àwọn ìjòyè Sukkoti fèsì pé ṣé ọwọ́ rẹ ti tẹ Seba àti Salmunna náà ni? Èéṣe tí àwa yóò ṣe fún àwọn ológun rẹ ní oúnjẹ?

  3. Gideoni dá wọn lóhùn pé, “Ó dára, nígbà tí Olúwa bá fi Seba àti Salmunna lé mi lọ́wọ́ tán èmi yóò fi ẹ̀gún ijù àti ẹ̀gún òṣùṣú ya ẹran-ara yín.”

  4. Ní àsìkò náà Seba àti Salmunna wà ní Karkori pẹ̀lú ọmọ-ogun wọn tí ó tó ẹgbẹ̀rún mẹ́ẹ̀ẹ́dógún (15,000) ọkùnrin, àwọn wọ̀nyí ni ó ṣẹ́kù nínú gbogbo ogun àwọn ènìyàn apá ìlà-oòrùn, nítorí ọ̀kẹ́ mẹ́fà (120,000) ọkùnrin tí ó fi idà jà ti kú ní ojú ogun.

  5. Seba àti Salmunna, àwọn ọba Midiani méjèèjì sá, ṣùgbọ́n Gideoni lépa wọn ó sì mú wọn, ó run gbogbo ogun wọn.

  6. Nígbà náà ni Gideoni wá ó sọ fún àwọn ọkùnrin Sukkoti pé, “Seba àti Salmunna nìwọ̀nyí nípa àwọn tí ẹ̀yin fi mí ṣẹ̀fẹ̀ nígbà tí ẹ wí pé, ‘Ṣé ó ti ṣẹ́gun Seba àti Salmunna? Èéṣe tí àwa ó fi fún àwọn ọmọ-ogun rẹ tí ó ti rẹ̀ ní oúnjẹ?’ ”

  7. Gideoni bi Seba àti Salmunna pé, “Irú ọkùnrin tí ẹ pa ní Tabori, báwo ni wọ́n ṣe rí?” “Àwọn ọkùnrin náà dàbí rẹ ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn dàbí ọmọ ọba,” ní ìdáhùn wọn.

  8. Seba àti Salmunna dá Gideoni lóhùn pé, “Wá pa wá fún raàrẹ, ‘Nítorí bí ènìyàn bá ti rí bẹ́ẹ̀ ni agbára rẹ̀ yóò rí.’ ” Gideoni bọ́ síwájú ó sì pa wọ́n, ó sì mú ohun ọ̀ṣọ́ tí ó wà ní ọrùn àwọn ìbákasẹ wọn.

  9. Ṣe àwọn ọlọ́lá wọn bí Orebu àti Seebu, àwọn ọmọ-aládé wọn bí Seba àti Salmunna,