Fò sí àkóónú

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa The Tribe Of Issachar

13 ẹsẹ · 20 abala

Àwọn ẹsẹ Bíbélì pàtàkì

  1. Ní ọjọ́ kejì ni Netaneli ọmọ Suari olórí àwọn ọmọ Isakari mú ọrẹ tirẹ̀ wá.

  2. Ọrẹ tí ó kó wá ní: àwo fàdákà kan tí ìwọ̀n rẹ̀ jẹ́ àádóje ṣékélì àti àwokòtò tí ìwọ̀n rẹ̀ jẹ́ àádọ́rin ṣékélì, méjèèjì gẹ́gẹ́ bí iye owó ibi mímọ́, àwo kọ̀ọ̀kan sì kún fún ìyẹ̀fun kíkúnná dáradára tí á fi òróró pò gẹ́gẹ́ bí ẹbọ ohun jíjẹ;

  3. àwo wúrà kan tí ìwọ̀n rẹ̀ jẹ́ ṣékélì mẹ́wàá tí ó kún fún tùràrí,

  4. ọ̀dọ́ akọ màlúù kan, àgbò kan, àti akọ ọ̀dọ́-àgùntàn ọlọ́dún kan, fún ẹbọ sísun;

  5. akọ ewúrẹ́ kan fún ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀;

  6. Màlúù méjì, àgbò márùn-ún, akọ ewúrẹ́ márùn-ún àti akọ ọ̀dọ́-àgùntàn ọlọ́dún kan márùn-ún tí wọn ó fi rú ẹbọ àlàáfíà. Èyí ni ọrẹ Netaneli ọmọ Suari.

  7. Kèké kẹrin jáde fún Isakari, agbo ilé ní agbo ilé.

  8. Lára ilẹ̀ wọn ni èyí: Jesreeli, Kesuloti, Ṣunemu,

  9. Hafraimu, Ṣihoni, Anaharati,

  10. Rabiti, Kiṣioni, Ebesi,

  11. Remeti, Eni-Gannimu, Eni-Hada àti Beti-Pasesi.

  12. Ààlà náà sì dé Tabori, Ṣahasuma, àti Beti-Ṣemeṣi, ó sì pin ní Jordani. Wọ́n sì jẹ́ ìlú mẹ́rìndínlógún àti ìletò wọn.

  13. Ìlú wọ̀nyí àti ìletò wọn jẹ́ ìní ẹ̀yà Isakari, ní agbo ilé agbo ilé.