- English
- King James KJV
- Complete Jewish CJB
- World English WEBM
- Berean Standard BSB
- American Standard ASV
- Geneva GNV
- Young's Literal YLT
- Douay-Rheims DRC
- International
- Shqip ALB
- العربية SVD
- বাংলা BN-IRV
- မြန်မာ Judson
- 简体文 CUV-S
- 繁體中文 CUV-T
- Čeština BKR
- Nederlands STVE
- Français LSG
- Deutsch SCH
- Ελληνικά Vamvas
- ગુજરાતી GU-IRV
- Hausa HCB
- עברית Hebrew
- हिन्दी HCV
- Magyar KAROLI
- Bahasa Indonesia INDO-TB
- Italiano Diodati
- 日本語 Kougo
- 한국어 Korean
- മലയാളം MAL
- मराठी MRCV
- Norsk DNB
- فارسی OPV
- Polski BG
- Português Almeida
- Română Cornilescu
- Русский Synodal
- Español RVG
- Kiswahili Neno
- Svenska SV1917
- Tagalog TAG-ADB
- தமிழ் TCV
- తెలుగు TSA
- ภาษาไทย THAI-KJV
- Українська Ohienko
- Tiếng Việt CADMAN
- Yorùbá YCB
circa AD 48–96
Letters to the Churches
Paul and other apostles write to strengthen, correct, and encourage the scattered churches across the Roman world.
Àwọn ẹsẹ láti sáà yìí
- 2 Timotiu 3:3nǹkan bí 66 lẹ́yìn Kristi
Aláìnífẹ̀ẹ́, aláìlèdáríjì, abanijẹ́, aláìlè-kó-aràwọn-níjánu, òǹrorò, aláìnífẹ̀ẹ́ ohun rere,
- 2 Timotiu 3:4nǹkan bí 66 lẹ́yìn Kristi
oníkúpani, alágídí, ọlọ́kàn gíga, olùfẹ́ fàájì ju olùfẹ́ Ọlọ́run lọ.
- 2 Timotiu 3:5nǹkan bí 66 lẹ́yìn Kristi
Àwọn tí wọn ní àfarawé ìwà-bí-Ọlọ́run, ṣùgbọ́n tí wọn sẹ́ agbára rẹ̀; yẹra kúrò lọ́dọ̀ àwọn wọ̀nyí pẹ̀lú.
- 2 Timotiu 3:6nǹkan bí 66 lẹ́yìn Kristi
Nítorí nínú irú èyí ni àwọn ti ń rákò wọ inú ilé, tí wọ́n sì ń di àwọn obìnrin aláìlọ́gbọ́n tí a di ẹ̀ṣẹ̀ rù ní ìgbèkùn, tí a sì ń fi onírúurú ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ fà kiri.
- 2 Timotiu 3:7nǹkan bí 66 lẹ́yìn Kristi
Wọ́n ń fi ìgbà gbogbo kẹ́kọ̀ọ́, wọ́n kò sì lè dé ojú ìmọ̀ òtítọ́.
- 2 Timotiu 3:8nǹkan bí 66 lẹ́yìn Kristi
Ǹjẹ́ gẹ́gẹ́ bí Janesi àti Jamberi ti kọ ojú ìjà sí Mose náà ni wọ́n kọjú ìjà sí òtítọ́: àwọn ènìyàn tí inú wọn díbàjẹ́, àwọn ẹni ìtanù ní ti ọ̀ràn ìgbàgbọ́.
- 2 Timotiu 3:9nǹkan bí 66 lẹ́yìn Kristi
Ṣùgbọ́n wọn kì yóò lọ síwájú ju bẹ́ẹ̀ lọ, nítorí òmùgọ̀ wọn yóò farahàn fún gbogbo ènìyàn gẹ́gẹ́ bí ti àwọn méjì yìí náà, ti yọrí si.
- 2 Timotiu 3:10nǹkan bí 66 lẹ́yìn Kristi
Ṣùgbọ́n ìwọ ti mọ ẹ̀kọ́ mi, ìgbésí ayé mi, ìpinnu, ìgbàgbọ́, ìpamọ́ra, ìfẹ́ sùúrù.
- 2 Timotiu 3:11nǹkan bí 66 lẹ́yìn Kristi
Inúnibíni, ìyà; àwọn ohun tí ó dé bá mi ní Antioku, ní Ikoniomu ní Lysra; àwọn inúnibíni tí mo faradà: Olúwa sì gbà mi kúrò nínú gbogbo wọn.
- 2 Timotiu 3:12nǹkan bí 66 lẹ́yìn Kristi
Nítòótọ́, gbogbo àwọn tí ó fẹ́ máa gbé ìgbé ayé ìwà-bí-Ọlọ́run nínú Kristi Jesu yóò faradà inúnibíni.
- 2 Timotiu 3:13nǹkan bí 66 lẹ́yìn Kristi
Ṣùgbọ́n àwọn ènìyàn búburú, àti àwọn ẹlẹ́tàn yóò máa burú síwájú sí i, wọn ó máa tannijẹ, a ó sì máa tàn wọ́n jẹ.
- 2 Timotiu 3:14nǹkan bí 66 lẹ́yìn Kristi
Ṣùgbọ́n ìwọ dúró nínú nǹkan wọ̀nyí tí ìwọ ti kọ́, tí a sì ti jẹ́ kí ojú rẹ dá ṣáṣá sí, kí ìwọ sì mọ̀ ọ̀dọ̀ ẹni tí ìwọ gbé kọ́ wọn.
- 2 Timotiu 3:15nǹkan bí 66 lẹ́yìn Kristi
Àti pé láti ìgbà ọmọdé ni ìwọ ti mọ Ìwé Mímọ́, tí ó lè sọ ọ́ di ọlọ́gbọ́n sí ìgbàlà nípasẹ̀ ìgbàgbọ́ nínú Kristi Jesu.
- 2 Timotiu 3:16nǹkan bí 66 lẹ́yìn Kristi
Gbogbo ìwé mímọ́ ni ó ní ìmísí Ọlọ́run tí ó sì ní èrè fún ẹ̀kọ́, fún ìbániwí, fún ìtọ́ni, fún ìkọ́ni tí ó wà nínú òdodo.
- 2 Timotiu 3:17nǹkan bí 66 lẹ́yìn Kristi
Kí ènìyàn Ọlọ́run lè pé, tí a ti múra sílẹ̀ pátápátá fun iṣẹ́ rere gbogbo.
- 2 Timotiu 4:1nǹkan bí 66 lẹ́yìn Kristi
Nítorí náà mo pàṣẹ fún ọ níwájú Ọlọ́run, àti Kristi Jesu, ẹni tí yóò ṣe ìdájọ́ alààyè àti òkú, àti nítorí ìfarahàn rẹ̀ àti ìjọba rẹ̀.
- 2 Timotiu 4:2nǹkan bí 66 lẹ́yìn Kristi
Wàásù ọ̀rọ̀ náà, ṣe àìsimi ní àkókò tí ó wọ̀, àti àkókò ti kò wọ̀; bá ni wí, ṣe ìtọ́ni, gbani níyànjú pẹ̀lú ìpamọ́ra àti ẹ̀kọ́ gbogbo.
- 2 Timotiu 4:3nǹkan bí 66 lẹ́yìn Kristi
Nítorí pé ìgbà yóò dé, tí wọn kì yóò lè gba ẹ̀kọ́ tí ó yè kooro, ṣùgbọ́n bí wọ́n ti jẹ́ ẹni tí etí ń rin, wọn ó lọ kó olùkọ́ jọ fún ara wọn nínú ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ara wọn.
- 2 Timotiu 4:4nǹkan bí 66 lẹ́yìn Kristi
Wọ́n ó sì yí etí wọn padà kúrò nínú òtítọ́, wọn ó sì yípadà sí ìtàn asán.
- 2 Timotiu 4:5nǹkan bí 66 lẹ́yìn Kristi
Ṣùgbọ́n máa faradà ìpọ́njú, ṣe iṣẹ́ efangelisti, ṣe iṣẹ́ rẹ láṣepé.
- 2 Timotiu 4:6nǹkan bí 66 lẹ́yìn Kristi
Nítorí à ń fi mi rú ẹbọ nísinsin yìí, àtilọ mi sì súnmọ́ etílé.
- 2 Timotiu 4:7nǹkan bí 66 lẹ́yìn Kristi
Èmi ti ja ìjà rere, èmi tí parí iré-ìje mi, èmi ti pa ìgbàgbọ́ mọ́.
- 2 Timotiu 4:8nǹkan bí 66 lẹ́yìn Kristi
Láti ìsinsin yìí lọ a fi adé òdodo lélẹ̀ fún mi, tí Olúwa onídàájọ́ òdodo, yóò fífún mi ni ọjọ́ náà kì í sì í ṣe kìkì èmi nìkan ṣùgbọ́n pẹ̀lú fún gbogbo àwọn tí ó ti fẹ́ ìfarahàn rẹ̀.
- 2 Timotiu 4:9nǹkan bí 66 lẹ́yìn Kristi
Sa ipá rẹ láti tètè tọ̀ mí wá.
- 2 Timotiu 4:10nǹkan bí 66 lẹ́yìn Kristi
Nítorí Dema ti kọ̀ mí sílẹ̀, nítorí ó ń fẹ́ ayé yìí, ó sì lọ sí Tẹsalonika; Kreskeni sí Galatia, Titu sí Dalimatia.