- English
- King James KJV
- Complete Jewish CJB
- World English WEBM
- Berean Standard BSB
- American Standard ASV
- Geneva GNV
- Young's Literal YLT
- Douay-Rheims DRC
- International
- Shqip ALB
- العربية SVD
- বাংলা BN-IRV
- မြန်မာ Judson
- 简体文 CUV-S
- 繁體中文 CUV-T
- Čeština BKR
- Nederlands STVE
- Français LSG
- Deutsch SCH
- Ελληνικά Vamvas
- ગુજરાતી GU-IRV
- Hausa HCB
- עברית Hebrew
- हिन्दी HCV
- Magyar KAROLI
- Bahasa Indonesia INDO-TB
- Italiano Diodati
- 日本語 Kougo
- 한국어 Korean
- മലയാളം MAL
- मराठी MRCV
- Norsk DNB
- فارسی OPV
- Polski BG
- Português Almeida
- Română Cornilescu
- Русский Synodal
- Español RVG
- Kiswahili Neno
- Svenska SV1917
- Tagalog TAG-ADB
- தமிழ் TCV
- తెలుగు TSA
- ภาษาไทย THAI-KJV
- Українська Ohienko
- Tiếng Việt CADMAN
- Yorùbá YCB
circa 1900–1700 BC
Jacob, Joseph & Egypt
Jacob wrestles with God and becomes Israel; Joseph is sold into slavery yet rises to save the world from famine.
Àwọn ẹsẹ láti sáà yìí
- Gẹnẹsisi 33:8nǹkan bí 1739 ṣáájú Kristi
Esau sì béèrè pé, “Kí ni èrò rẹ tí o fi to àwọn ọ̀wọ̀ọ̀wọ́ tí mo pàdé wọ̀nyí?” Jakọbu dáhùn pé, “Kí n ba le rí ojúrere rẹ ni olúwa mi.”
- Gẹnẹsisi 33:9nǹkan bí 1739 ṣáájú Kristi
Ṣùgbọ́n Esau wí pé, “Tèmi ti tó mi, pa èyí tí o ní mọ́ fún ara rẹ.”
- Gẹnẹsisi 33:10nǹkan bí 1739 ṣáájú Kristi
Jakọbu bẹ̀ ẹ́ wí pé, “Rárá bẹ́ẹ̀ kọ́, bí ó bá ṣe pé, mo rí ojúrere rẹ, jọ̀wọ́ gba ọrẹ lọ́wọ́ mi. Bí mo ṣe rí ojú rẹ̀ yìí, ó dàbí wí pé mo rí ojú Ọlọ́run ni báyìí, tí inú rẹ̀ ti dùn sí mi.
- Gẹnẹsisi 33:11nǹkan bí 1739 ṣáájú Kristi
Jọ̀wọ́ gba àwọn ohun tí mo mú wá wọ̀nyí lọ́wọ́ mi. Nítorí Ọlọ́run ti fi oore-ọ̀fẹ́ rẹ̀ hàn sí mi, gbogbo ohun tí mo fẹ́ sì ni mo ní.” Nígbà tí Jakọbu sì rọ̀ ọ́ pé Esau gbọdọ̀ gbà wọ́n, Esau sì gbà á.
- Gẹnẹsisi 33:12nǹkan bí 1739 ṣáájú Kristi
Nígbà náà ni Esau wí pé, “Jẹ́ kí a máa lọ, n ó sìn ọ.”
- Gẹnẹsisi 33:13nǹkan bí 1739 ṣáájú Kristi
Ṣùgbọ́n Jakọbu wí fún un pé, “Ṣe ìwọ náà ṣe àkíyèsí pé ọ̀pọ̀ nínú àwọn ọmọ wọ̀nyí kéré, àwọn màlúù àti àgùntàn pẹ̀lú sì ní àwọn ọmọ kéékèèké. Bí a bá dà wọ́n rìn jìnnà ju bí agbára wọn ṣe mọ lọ, wọ́n lè kú.
- Gẹnẹsisi 33:14nǹkan bí 1739 ṣáájú Kristi
Èmi bẹ̀ ọ́, máa lọ síwájú ìránṣẹ́ rẹ, àwọn ó sì máa rọra bọ̀, títí èmi àti àwọn ọmọ yóò fi dé ọ̀dọ̀ olúwa mi ní Seiri.”
- Gẹnẹsisi 33:15nǹkan bí 1739 ṣáájú Kristi
Esau wí pé, “Jẹ́ kí n fi díẹ̀ sílẹ̀ fún ọ nínú àwọn ọkùnrin mi nígbà náà.” Jakọbu wí pé, “Èéṣe, àní kí n sá à rí ojúrere olúwa mi?”
- Gẹnẹsisi 33:16nǹkan bí 1739 ṣáájú Kristi
Ní ọjọ́ náà gan an ni Esau padà lọ sí Seiri.
- Gẹnẹsisi 33:17nǹkan bí 1739 ṣáájú Kristi
Jakọbu sì lọ sí Sukkoti, ó sì kọ́ ilé fún ara rẹ̀, ó sì ṣe ọgbà fún àwọn ẹran. Ìdí èyí ní a fi ń pe ibẹ̀ ní Sukkoti.
- Gẹnẹsisi 33:18nǹkan bí 1739 ṣáájú Kristi
Lẹ́yìn ìgbà tí Jakọbu tí Padani-Aramu dé, àlàáfíà ni Jakọbu dé ìlú Ṣekemu ní ilẹ̀ Kenaani, ó sì pàgọ́ sí itòsí ìlú náà.
- Gẹnẹsisi 33:19nǹkan bí 1739 ṣáájú Kristi
Ó sì ra ilẹ̀ kan tí ó pàgọ́ sí ni ọgọ́rùn-ún owó fàdákà lọ́wọ́ àwọn ọmọ Hamori tí í ṣe baba Ṣekemu.
- Gẹnẹsisi 33:20nǹkan bí 1739 ṣáájú Kristi
Níbẹ̀ ni ó gbé tẹ́ pẹpẹ kan tí ó pè ní El Elohe Israẹli.
- Gẹnẹsisi 34:1nǹkan bí 1732 ṣáájú Kristi
Ní ọjọ́ kan, Dina ọmọbìnrin tí Lea bí fún Jakọbu jáde lọ bẹ àwọn ọmọbìnrin ilẹ̀ náà wò.
- Gẹnẹsisi 34:2nǹkan bí 1732 ṣáájú Kristi
Nígbà tí Ṣekemu ọmọ ọba Hamori ará Hifi rí i, ó mú un, ó sì fi ipá bá a lo pọ̀.
- Gẹnẹsisi 34:3nǹkan bí 1732 ṣáájú Kristi
Ọkàn rẹ sì fà sí Dina ọmọ Jakọbu gan an, ó sì fẹ́ràn rẹ̀ ó sì bá ọmọbìnrin náà sọ̀rọ̀ ìfẹ́.
- Gẹnẹsisi 34:4nǹkan bí 1732 ṣáájú Kristi
Ṣekemu sì wí fún Hamori baba rẹ̀ pé, “Fẹ́ ọmọbìnrin yìí fún mi bí aya.”
- Gẹnẹsisi 34:5nǹkan bí 1732 ṣáájú Kristi
Nígbà tí Jakọbu gbọ́ ohun tí ó ṣẹlẹ̀ pé a fi ipá bá Dina ọmọbìnrin òun ní ògo jẹ́, ṣùgbọ́n àwọn ọmọ rẹ̀ wà nínú pápá níbi tí wọ́n ti ń daran nítorí náà ó mú sùúrù títí tí wọ́n fi dé.
- Gẹnẹsisi 34:6nǹkan bí 1732 ṣáájú Kristi
Hamori baba Ṣekemu sì jáde wá láti bá Jakọbu sọ̀rọ̀.
- Gẹnẹsisi 34:7nǹkan bí 1732 ṣáájú Kristi
Àwọn ọmọ Jakọbu sì ti oko dé, wọ́n sì gbọ́ ohun tí ó ṣẹlẹ̀ inú wọn sì bàjẹ́, ó sì ń bí wọn nínú gidigidi, nítorí tí ó ṣe ohun búburú ní Israẹli, ní ti ó bá ọmọbìnrin ọmọ Jakọbu lòpọ̀—irú ohun tí kò yẹ kí ó ṣẹlẹ̀ rárá.
- Gẹnẹsisi 34:8nǹkan bí 1732 ṣáájú Kristi
Hamori sì bá wọn sọ̀rọ̀ pé, “Ọkàn ọmọ mi Ṣekemu fà sí ọmọ rẹ. Jọ̀wọ́ fi fún un gẹ́gẹ́ bí aya.
- Gẹnẹsisi 34:9nǹkan bí 1732 ṣáájú Kristi
Ẹ jẹ́ kí a máa ṣe ìgbéyàwó láàrín ara wa, kí àwọn ọmọ yín kó máa fẹ́ àwọn ọmọ wa.
- Gẹnẹsisi 34:10nǹkan bí 1732 ṣáájú Kristi
Ẹ lè máa gbé láàrín wa, ibikíbi tí ó bá tẹ́ yín lọ́rùn láàrín wa ni ẹ lè gbé, ẹ máa ṣe òwò yín kí ẹ sì kó ọrọ̀ jọ fún ara yín.”
- Gẹnẹsisi 34:11nǹkan bí 1732 ṣáájú Kristi
Ṣekemu sì wí fún baba àti arákùnrin Dina pé, “Ẹ jọ̀wọ́, ẹ jẹ́ kí n rí ojúrere yín, èmi yóò sì fún yín ní ohunkóhun tí ẹ̀yin bá fẹ́ gbà.
- Gẹnẹsisi 34:12nǹkan bí 1732 ṣáájú Kristi
Iyekíye tí owó orí rẹ̀ bá jẹ́ àti ẹ̀bùn gbogbo tí ẹ bá fẹ́, bí ó ti wù kí ó pọ̀ tó, èmi yóò san án, kí ẹ sá à jẹ́ kí ń fi ọmọ náà ṣe aya.”