- English
- King James KJV
- Complete Jewish CJB
- World English WEBM
- Berean Standard BSB
- American Standard ASV
- Geneva GNV
- Young's Literal YLT
- Douay-Rheims DRC
- International
- Shqip ALB
- العربية SVD
- বাংলা BN-IRV
- မြန်မာ Judson
- 简体文 CUV-S
- 繁體中文 CUV-T
- Čeština BKR
- Nederlands STVE
- Français LSG
- Deutsch SCH
- Ελληνικά Vamvas
- ગુજરાતી GU-IRV
- Hausa HCB
- עברית Hebrew
- हिन्दी HCV
- Magyar KAROLI
- Bahasa Indonesia INDO-TB
- Italiano Diodati
- 日本語 Kougo
- 한국어 Korean
- മലയാളം MAL
- मराठी MRCV
- Norsk DNB
- فارسی OPV
- Polski BG
- Português Almeida
- Română Cornilescu
- Русский Synodal
- Español RVG
- Kiswahili Neno
- Svenska SV1917
- Tagalog TAG-ADB
- தமிழ் TCV
- తెలుగు TSA
- ภาษาไทย THAI-KJV
- Українська Ohienko
- Tiếng Việt CADMAN
- Yorùbá YCB
circa 1900–1700 BC
Jacob, Joseph & Egypt
Jacob wrestles with God and becomes Israel; Joseph is sold into slavery yet rises to save the world from famine.
Àwọn ẹsẹ láti sáà yìí
- Gẹnẹsisi 34:13nǹkan bí 1732 ṣáájú Kristi
Àwọn ọmọ Jakọbu sì fi ẹ̀tàn dá Ṣekemu àti Hamori baba rẹ̀ lóhùn, wọ́n sì wí pé, nítorí tí ó ti ba ògo Dina arábìnrin wọn jẹ́.
- Gẹnẹsisi 34:14nǹkan bí 1732 ṣáájú Kristi
Wọ́n wí fún wọn pé, “Àwa kò le ṣe nǹkan yìí láti fi arábìnrin wa fún aláìkọlà, nítorí àbùkù ni èyí yóò jẹ́ fún wa.
- Gẹnẹsisi 34:15nǹkan bí 1732 ṣáájú Kristi
Àwa yóò fi ara mọ́ ọn bí ẹ̀yin yóò bá gbà láti dàbí i tiwa, wí pé ẹ̀yin pẹ̀lú yóò kọ gbogbo ọkùnrin yín ní ilà.
- Gẹnẹsisi 34:16nǹkan bí 1732 ṣáájú Kristi
Nígbà náà ni àwa yóò le máa fún yín ní ọmọ wa, tí àwa náà yóò máa fẹ́ ẹ yín. A ó máa gbé láàrín yín, a ó sì di ara kan pẹ̀lú yín.
- Gẹnẹsisi 34:17nǹkan bí 1732 ṣáájú Kristi
Ṣùgbọ́n bí ẹ̀yin bá kọ̀ láti kọlà, àwa yóò mú arábìnrin wa, á ó sì máa lọ.”
- Gẹnẹsisi 34:18nǹkan bí 1732 ṣáájú Kristi
Àbá náà sì dùn mọ́ Hamori àti Ṣekemu ọmọ rẹ̀.
- Gẹnẹsisi 34:19nǹkan bí 1732 ṣáájú Kristi
Ọ̀dọ́mọkùnrin náà, ẹni tí ó jẹ́ ẹni iyì jùlọ ní ilé baba rẹ̀, kò jáfara láti ṣe ohun tí wọ́n wí. Nítorí tí ó fẹ́ràn ọmọbìnrin Jakọbu.
- Gẹnẹsisi 34:20nǹkan bí 1732 ṣáájú Kristi
Hamori àti Ṣekemu ọmọ rẹ̀ sì wá sí ẹnu ibodè ìlú náà wọn sì bá àwọn ará ìlú náà sọ̀rọ̀.
- Gẹnẹsisi 34:21nǹkan bí 1732 ṣáájú Kristi
Wí pé, “Ìwà àwọn ọkùnrin wọ̀nyí dára, ẹ jẹ́ kí wọn máa gbé ní àárín wa, kí wọn sì máa ṣòwò, ilẹ̀ kúkú wà rẹpẹtẹ tó gba ààyè dáradára. A lè fẹ́ àwọn ọmọ wọ́n, ki wọn sì fẹ́ tiwa pẹ̀lú.
- Gẹnẹsisi 34:22nǹkan bí 1732 ṣáájú Kristi
Ṣùgbọ́n kín ní kan ni a lè ṣe kí wọn tó gbà láti gbé pẹ̀lú wa, ìyẹn sì ni pé àwọn ọkùnrin wa yóò kọlà bí i tiwọn.
- Gẹnẹsisi 34:23nǹkan bí 1732 ṣáájú Kristi
Ṣe bí àwọn ẹran wọn àti ẹrú wọn àti àwọn ohun ọ̀sìn wọn ni yóò di tiwa bí a bá lè gbà bẹ́ẹ̀, wọn yóò sì máa gbé ni àárín wa.”
- Gẹnẹsisi 34:24nǹkan bí 1732 ṣáájú Kristi
Gbogbo àwọn ọkùnrin tí ń jáde ní ẹnu-bodè ìlú náà sì gbọ́ ti Hamori àti Ṣekemu ọmọ rẹ̀. Gbogbo ọkùnrin ìlú náà sì kọlà.
- Gẹnẹsisi 34:25nǹkan bí 1732 ṣáájú Kristi
Lẹ́yìn ọjọ́ kẹta, nígbà tí gbogbo wọn sì wà nínú ìrora. Àwọn ọmọ Jakọbu méjì, Simeoni àti Lefi tí ó jẹ́ ẹ̀gbọ́n fún Dina, sì mú idà wọn pẹ̀lú ìgboyà, wọ́n sì pa gbogbo ọkùnrin ìlú náà.
- Gẹnẹsisi 34:26nǹkan bí 1732 ṣáájú Kristi
Wọ́n sì fi idà pa Hamori àti Ṣekemu ọmọ rẹ̀, wọ́n mú Dina kúrò ní ilé wọn, wọ́n sì jáde.
- Gẹnẹsisi 34:27nǹkan bí 1732 ṣáájú Kristi
Àwọn ọmọ Jakọbu sì wọlé àwọn tí a pa, wọ́n sì kó ẹrù ìlú tí a ti ba ògo arábìnrin wọn jẹ́.
- Gẹnẹsisi 34:28nǹkan bí 1732 ṣáájú Kristi
Wọ́n kó màlúù wọn àti agbo ẹran wọn àti kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́, àti ohun gbogbo tí ó wà nínú ìlú àti ní oko.
- Gẹnẹsisi 34:29nǹkan bí 1732 ṣáájú Kristi
Gbogbo ọrọ̀ wọn, gbogbo obìnrin ìlú àti àwọn ọmọ wẹẹrẹ pátápátá ni wọ́n kó. Wọ́n sì kó gbogbo ohun tí ó wà nínú ilé wọn bí ìkógun.
- Gẹnẹsisi 34:30nǹkan bí 1732 ṣáájú Kristi
Nígbà náà ni Jakọbu wí fún Simeoni àti Lefi wí pé, “Ẹ̀yin ti kó ìyọnu bá mi nípa sísọ mí di olóòórùn láàrín ará Kenaani àti Peresi, tí ó ń gbé ilẹ̀ yìí. Àwa kò pọ̀, bí wọn bá wá parapọ̀ ṣígun sí wa, gbogbo wa pátápátá ni wọn yóò parun.”
- Gẹnẹsisi 34:31nǹkan bí 1732 ṣáájú Kristi
Ṣùgbọ́n wọ́n dáhùn pé, “Ǹjẹ́ ó yẹ kí ó ṣe arábìnrin wa bí panṣágà?”
Nígbà náà ni Ọlọ́run wí fún Jakọbu pé, “Gòkè lọ sí Beteli kí o sì tẹ̀dó síbẹ̀, kí ó mọ pẹpẹ níbẹ̀ fún Ọlọ́run tó farahàn ọ́ nígbà tí o ń sálọ kúrò níwájú Esau arákùnrin rẹ.”
Nítorí náà, Jakọbu wí fún gbogbo ará ilé rẹ̀ pé, “Ẹ mú gbogbo àjèjì òrìṣà tí ó wà lọ́dọ̀ yín kúrò, kí ẹ ya ara yín sí mímọ́, kí ẹ sì pààrọ̀ aṣọ yín.
Nígbà náà ni kí ẹ wá, kí ẹ jẹ́ kí a lọ sí Beteli, níbi tí n ó ti mọ pẹpẹ fún Ọlọ́run, tí ó dá mi lóhùn ní ọjọ́ ìpọ́njú mi tí ó sì ti ń pẹ̀lú mi níbi gbogbo tí mo ń lọ.”
Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n fún Jakọbu ní gbogbo àjèjì òrìṣà tí ó wà lọ́wọ́ wọn, àti yẹtí etí wọn, Jakọbu sì bo gbogbo wọn mọ́lẹ̀ sábẹ́ igi óákù ní Ṣekemu.
Wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ ìrìnàjò wọn. Ìbẹ̀rù Ọlọ́run sì ń bẹ lára gbogbo ìlú tí ó yí wọn ká, wọ́n kò sì lépa àwọn ọmọ Jakọbu.
Jakọbu àti gbogbo àwọn tí ó wà pẹ̀lú rẹ̀ sì dé sí Lusi (ti o túmọ̀ sí Beteli) tí ó wà ní ilẹ̀ Kenaani.