- English
- King James KJV
- Complete Jewish CJB
- World English WEBM
- Berean Standard BSB
- American Standard ASV
- Geneva GNV
- Young's Literal YLT
- Douay-Rheims DRC
- International
- Shqip ALB
- العربية SVD
- বাংলা BN-IRV
- မြန်မာ Judson
- 简体文 CUV-S
- 繁體中文 CUV-T
- Čeština BKR
- Nederlands STVE
- Français LSG
- Deutsch SCH
- Ελληνικά Vamvas
- ગુજરાતી GU-IRV
- Hausa HCB
- עברית Hebrew
- हिन्दी HCV
- Magyar KAROLI
- Bahasa Indonesia INDO-TB
- Italiano Diodati
- 日本語 Kougo
- 한국어 Korean
- മലയാളം MAL
- मराठी MRCV
- Norsk DNB
- فارسی OPV
- Polski BG
- Português Almeida
- Română Cornilescu
- Русский Synodal
- Español RVG
- Kiswahili Neno
- Svenska SV1917
- Tagalog TAG-ADB
- தமிழ் TCV
- తెలుగు TSA
- ภาษาไทย THAI-KJV
- Українська Ohienko
- Tiếng Việt CADMAN
- Yorùbá YCB
Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Laban
Àwọn ẹsẹ Bíbélì pàtàkì
Rebeka ní arákùnrin tí ń jẹ́ Labani; Labani sì sáré lọ bá ọkùnrin náà ní etí odò.
Bí ó sì ti rí òrùka imú àti ẹ̀gbà ní ọwọ́ arábìnrin rẹ̀ tí ó sì tún gbọ́ ohun tí Rebeka sọ pé ọkùnrin náà sọ fún òun, ó jáde lọ bá ọkùnrin náà, ó sì bá a, ó dúró ti ìbákasẹ wọ̀n-ọn-nì ní ẹ̀bá ìsun omi.
Ó wí fún ọkùnrin náà pé, “Wá, ìwọ ẹni ìbùkún Olúwa, èéṣe tí o dúró sí ìta níhìn-ín? Mo ti pèsè ààyè sílẹ̀ fún ọ àti ààyè fún àwọn ìbákasẹ rẹ.”
Ọkùnrin náà sì bá Labani lọ ilé, ó sì tú ẹrù orí ìbákasẹ rẹ̀ sílẹ̀, ó sì fún wọn ni koríko àti oúnjẹ. Ó sì bu omi fún ọkùnrin náà àti àwọn arákùnrin rẹ̀ láti wẹ ẹsẹ̀ wọn.
Wọ́n sì gbé oúnjẹ síwájú rẹ̀, ṣùgbọ́n, ó wí pé, “Èmi kò ní jẹun àyàfi bí mo bá sọ ohun tí mo ní í sọ.” Labani sì wí pé, “Kò burú, sọ ọ́.”
Jakọbu sì wí fún Rakeli pé ìbátan baba rẹ̀ ni òun, àti pé, òun jẹ́ ọmọ Rebeka. Rakeli sì sáré lọ sọ fún baba rẹ̀.
Ní kété tí Labani gbúròó Jakọbu ọmọ arábìnrin rẹ̀, ó jáde lọ pàdé Jakọbu, ó dì mọ́ ọn, ó fi ẹnu kò ó ní ẹnu, ó sì mú un lọ sí ilé. Nígbà náà ni Jakọbu ròyìn ohun gbogbo fún un.
Labani sì wí pé, “Ẹran-ara àti ẹ̀jẹ̀ ara mi ni ìwọ jẹ́.” Lẹ́yìn tí Jakọbu sì wà pẹ̀lú rẹ̀ fún odidi oṣù kan,
Labani wí fún Jakọbu pé, “Bí a tilẹ̀ jẹ́ ìbátan, kò yẹ kí o máa ṣiṣẹ́ fún mi lásán láìgba ohun kankan. Sọ ohun tì ìwọ fẹ́ gbà fún iṣẹ́ tí ìwọ ń ṣe fún mi!”
Wàyí o, Labani ní ọmọbìnrin méjì, orúkọ èyí ẹ̀gbọ́n ń jẹ́ Lea, orúkọ àbúrò sì ń jẹ́ Rakeli.
Lea kò ní ẹwà púpọ̀, ṣùgbọ́n Rakeli ní ẹwà gidigidi. Ojú rẹ̀ sì fanimọ́ra.
Jakọbu sì fẹ́ràn Rakeli, ó sì wí fún baba rẹ̀ pé, “Èmi yóò ṣiṣẹ́ sìn ọ fún ọdún méje, bí ìwọ yóò bá fún mi ní Rakeli ọmọ rẹ ní aya.”
Labani sì dáhùn wí pé, “Ó kúkú sàn kí ń fi fún ọ, ju kí ń fi fún ẹlòmíràn lọ, nítorí náà wà ní ọ̀dọ̀ mi.”
Jakọbu sì ṣiṣẹ́ sin Labani fún ọdún méje láti fẹ́ Rakeli. Àwọn ọdún wọ̀nyí sì dàbí ọjọ́ díẹ̀ lára rẹ̀, nítorí ó fẹ́ràn rẹ̀.
Jakọbu sì wí fún Labani pé, “Mo ti parí àsìkò tí a jọ ṣe àdéhùn rẹ̀, nítorí náà fún mi ní aya mi, kí òun lè ṣe aya fún mi.”
Labani sì pe gbogbo ènìyàn ibẹ̀ jọ, ó sì ṣe àsè ìyàwó fún wọ́n.
Ṣùgbọ́n nígbà tí ó di òru, Labani mú Lea tọ Jakọbu lọ. Jakọbu sì bá a lòpọ̀.
Labani sì fi Silipa ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ̀ obìnrin fún Lea gẹ́gẹ́ bí ìránṣẹ́.
Sì kíyèsi, nígbà ti ilẹ̀ mọ́, Jakọbu rí i pé Lea ni! Ó sì wí fún Labani pé, “Èwo ni ìwọ ṣe sí mi yìí? Ṣe bí nítorí Rakeli ni mo ṣe ṣiṣẹ́ sìn ọ, èéṣe tí ìwọ tàn mi?”
Labani sì dáhùn pé, “Kò bá àṣà wa mu láti fi àbúrò fún ọkọ ṣáájú ẹ̀gbọ́n rẹ̀.
Mú sùúrù parí ọ̀sẹ̀ ìgbéyàwó yìí náà, nígbà náà ni èmi yóò fi àbúrò rẹ̀ fún ọ pẹ̀lú, bí ìwọ ó bá ṣiṣẹ́ sìn mi fún ọdún méje mìíràn.”
Jakọbu sì gbà láti sin Labani fún ọdún méje mìíràn. Labani sì fi Rakeli ọmọ rẹ̀ fún un bí aya.
Labani sì fi Biliha ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ̀ obìnrin fún Rakeli bí ìránṣẹ́.
Jakọbu sì bá Rakeli náà lòpọ̀. Ó sì fẹ́ràn Rakeli ju Lea lọ, ó sì ṣiṣẹ́ sin Labani fún ọdún méje mìíràn.
Ṣùgbọ́n Labani wí fún un pé, “Bí o bá ṣe pé mo rí ojúrere rẹ, jọ̀wọ́ dúró, nítorí, mo ti ṣe àyẹ̀wò rẹ, mo sì rí i pé Olúwa bùkún mi nítorí rẹ.