Fò sí àkóónú

circa 800–400 BC

The Hebrew Prophets

God speaks through Isaiah, Jeremiah, and the minor prophets—calling Israel to repentance and foretelling the coming Messiah.

3,706 ẹsẹ · 14 ìwé tí a bo

Àwọn ẹsẹ láti sáà yìí

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Habakuku 2:16nǹkan bí 626 ṣáájú Kristi

    Ìtìjú yóò bò ọ́ dípò ògo, ìwọ náà mu pẹ̀lú kí ìhòhò rẹ kí ó lè hàn, ago ọwọ́ ọ̀tún Olúwa, yóò yípadà sí ọ, ìtìjú yóò sì bo ògo rẹ.

  2. Habakuku 2:17nǹkan bí 626 ṣáájú Kristi

    Nítorí ìwà ipá tí ó tí hù sí Lebanoni yóò bò ọ́, àti ìparun àwọn ẹranko yóò dẹ́rùbà ọ́ mọ́lẹ̀. Nítorí ìwọ tí ta ẹ̀jẹ̀ ènìyàn sílẹ̀; ìwọ tí pa ilẹ̀ náà àti ìlú ńlá run àti gbogbo àwọn tí ń gbé inú rẹ̀.

  3. Habakuku 2:18nǹkan bí 626 ṣáájú Kristi

    “Èrè kí ni òrìṣà ni, tí oníṣọ̀nà rẹ̀ fi gbẹ́ ẹ, ère dídá ti ń kọ ni èké? Nítorí ti ẹni ti ó dá a gbẹ́kẹ̀ rẹ̀ lé ohun tí ó fúnra rẹ̀ dá; ó sì mọ ère tí kò le fọhùn.

  4. Habakuku 2:19nǹkan bí 626 ṣáájú Kristi

    Ègbé ni fún ẹni ti ń sọ fún igi pé, ‘Di alààyè?’ Fún òkúta tí kò lè fọhùn pé, ‘Dìde.’ Ǹjẹ́ òun lè tọ́ ni sí ọ̀nà? Wúrà àti fàdákà ni a fi bò ó yíká; kò sì sí èémí kan nínú rẹ.”

  5. Habakuku 2:20nǹkan bí 626 ṣáájú Kristi

    Ṣùgbọ́n Olúwa wà nínú tẹmpili mímọ́ rẹ̀; ẹ jẹ́ kí gbogbo ayé parọ́rọ́ níwájú rẹ.

  6. Habakuku 3:1nǹkan bí 626 ṣáájú Kristi

    Àdúrà wòlíì Habakuku gẹ́gẹ́ bí sígónótì. Ohun èlò orin.

  7. Habakuku 3:2nǹkan bí 626 ṣáájú Kristi

    Olúwa mo tí gbọ́ ohùn rẹ; ẹ̀rù sì ba mi fún iṣẹ́ rẹ Olúwa sọ wọn di ọ̀tún ní ọjọ́ ti wa, ní àkókò tiwa, jẹ́ kó di mí mọ̀; ni ìbínú, rántí àánú.

  8. Habakuku 3:3nǹkan bí 626 ṣáájú Kristi

    Ọlọ́run yóò wa láti Temani, ibi mímọ́ jùlọ láti òkè Parani ògo rẹ̀ sí bo àwọn ọ̀run, ilé ayé sì kún fún ìyìn rẹ.

  9. Habakuku 3:4nǹkan bí 626 ṣáájú Kristi

    Dídán rẹ sí dàbí ìmọ́lẹ̀ oòrùn ìtànṣán ìmọ́lẹ̀ jáde wa láti ọwọ́ rẹ, níbi tí wọn fi agbára rẹ̀ pamọ́ sí.

  10. Habakuku 3:5nǹkan bí 626 ṣáájú Kristi

    Àjàkálẹ̀-ààrùn ń lọ ni iwájú rẹ; ìyọnu sí ń tọ ẹsẹ̀ rẹ lọ.

  11. Habakuku 3:6nǹkan bí 626 ṣáájú Kristi

    Ó dúró, ó sì mi ayé; ó wò, ó sì mú àwọn orílẹ̀-èdè wárìrì a sì tú àwọn òkè ńlá ayérayé ká, àwọn òkè kéékèèké ayérayé sì tẹríba: ọ̀nà rẹ ayérayé ni.

  12. Habakuku 3:7nǹkan bí 626 ṣáájú Kristi

    Mo rí àgọ́ Kuṣani nínú ìpọ́njú àti àwọn ibùgbé Midiani nínú ìrora.

  13. Habakuku 3:8nǹkan bí 626 ṣáájú Kristi

    Ǹjẹ́ ìwọ ha ń bínú sí àwọn odò nì, Olúwa? Ǹjẹ́ ìbínú rẹ wa lórí àwọn odò ṣíṣàn bí? Ìbínú rẹ ha wá sórí Òkun tí ìwọ fi ń gun ẹṣin, àti kẹ̀kẹ́ ìgbàlà rẹ?

  14. Habakuku 3:9nǹkan bí 626 ṣáájú Kristi

    A ṣí ọrun rẹ sílẹ̀ pátápátá, gẹ́gẹ́ bí ìbúra àwọn ẹ̀yà, àní ọ̀rọ̀ rẹ, ìwọ sì fi odò pín ilẹ̀ ayé.

  15. Habakuku 3:10nǹkan bí 626 ṣáájú Kristi

    Àwọn òkè ńlá ri ọ wọn sì wárìrì àgbàrá òjò ń sàn án kọjá lọ; ibú ń ké ramúramù ó sì gbé irú omi sókè.

  16. Habakuku 3:11nǹkan bí 626 ṣáájú Kristi

    Òòrùn àti Òṣùpá dúró jẹ́ẹ́jẹ́ ni ibùgbé wọn, pẹ̀lú ìmọ́lẹ̀ ọfà rẹ ni wọn yára lọ, àti ni dídán ọ̀kọ̀ rẹ ti ń kọ mànà.

  17. Habakuku 3:12nǹkan bí 626 ṣáájú Kristi

    Ní ìrunú ni ìwọ rin ilẹ̀ náà já, ní ìbínú ni ìwọ tí tẹ́ àwọn orílẹ̀-èdè rẹ.

  18. Habakuku 3:13nǹkan bí 626 ṣáájú Kristi

    Ìwọ jáde lọ láti tú àwọn ènìyàn rẹ sílẹ̀, àti láti gba ẹni àmì òróró rẹ là, Ìwọ ti run àwọn olórí kúrò nínú ilẹ̀ àwọn ènìyàn búburú, ó sì bọ ìhámọ́ra rẹ láti orí de ẹsẹ̀.

  19. Habakuku 3:14nǹkan bí 626 ṣáájú Kristi

    Pẹ̀lú ọ̀kọ̀ rẹ̀ kí ó fi gún orí rẹ nígbà tí àwọn jagunjagun rẹ̀ jáde láti tú wá ká, ayọ̀ wọn sì ni láti jẹ tálákà run ní ìkọ̀kọ̀.

  20. Habakuku 3:15nǹkan bí 626 ṣáájú Kristi

    Ìwọ fi ẹṣin rẹ rìn Òkun já, ó sì da àwọn omi ńlá ru.

  21. Habakuku 3:16nǹkan bí 626 ṣáájú Kristi

    Mo gbọ́, ọkàn mi sì wárìrì, ètè mi sì gbọ̀n sí ìró náà; ìbàjẹ́ sì wọ inú egungun mi lọ, ẹsẹ̀ mi sì wárìrì, mo dúró ni ìdákẹ́ jẹ́ẹ́ fún ọjọ́ ìdààmú láti de sórí àwọn ènìyàn tó ń dojúkọ wá.

  22. Habakuku 3:17nǹkan bí 626 ṣáájú Kristi

    Bí igi ọ̀pọ̀tọ́ ko tilẹ̀ tanná, tí èso kò sí nínú àjàrà; tí igi olifi ko le so, àwọn oko ko sì mú oúnjẹ wá; tí a sì ké agbo ẹran kúrò nínú agbo, tí kò sì sí ọwọ́ ẹran ni ibùso mọ́,

  23. Habakuku 3:18nǹkan bí 626 ṣáájú Kristi

    síbẹ̀, èmi ó láyọ̀ nínú Olúwa, èmi yóò sí máa yọ nínú Ọlọ́run ìgbàlà mi.

  24. Habakuku 3:19nǹkan bí 626 ṣáájú Kristi

    Olúwa Olódùmarè ni agbára mi, òun yóò sí ṣe ẹsẹ̀ mi bí ẹsẹ̀ abo àgbọ̀nrín, yóò sí mú mi rìn lórí ibi gíga. Sí olórí akọrin lórí ohun èlò orin olókùn mi.

  25. Sefaniah 1:1nǹkan bí 630 ṣáájú Kristi

    Ọ̀rọ̀ Olúwa tí ó tọ Sefaniah ọmọ Kuṣi, ọmọ Gedaliah, ọmọ Amariah, ọmọ Hesekiah, ní ìgbà Josiah ọmọ Amoni ọba Juda.