- English
- King James KJV
- Complete Jewish CJB
- World English WEBM
- Berean Standard BSB
- American Standard ASV
- Geneva GNV
- Young's Literal YLT
- Douay-Rheims DRC
- International
- Shqip ALB
- العربية SVD
- বাংলা BN-IRV
- မြန်မာ Judson
- 简体文 CUV-S
- 繁體中文 CUV-T
- Čeština BKR
- Nederlands STVE
- Français LSG
- Deutsch SCH
- Ελληνικά Vamvas
- ગુજરાતી GU-IRV
- Hausa HCB
- עברית Hebrew
- हिन्दी HCV
- Magyar KAROLI
- Bahasa Indonesia INDO-TB
- Italiano Diodati
- 日本語 Kougo
- 한국어 Korean
- മലയാളം MAL
- मराठी MRCV
- Norsk DNB
- فارسی OPV
- Polski BG
- Português Almeida
- Română Cornilescu
- Русский Synodal
- Español RVG
- Kiswahili Neno
- Svenska SV1917
- Tagalog TAG-ADB
- தமிழ் TCV
- తెలుగు TSA
- ภาษาไทย THAI-KJV
- Українська Ohienko
- Tiếng Việt CADMAN
- Yorùbá YCB
circa 800–400 BC
The Hebrew Prophets
God speaks through Isaiah, Jeremiah, and the minor prophets—calling Israel to repentance and foretelling the coming Messiah.
Àwọn ẹsẹ láti sáà yìí
- Sefaniah 2:9nǹkan bí 630 ṣáájú Kristi
Nítorí náà, bí Èmi tí wà,” ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun, Ọlọ́run àwọn Israẹli wí, “nítòótọ́ Moabu yóò dàbí Sodomu, àti Ammoni yóò sì dàbí Gomorra, ibi tí ó kún fún yèrèpè, àti ìhó iyọ̀ àti ìdahoro títí láéláé. Ìyókù àwọn ènìyàn mi yóò kó wọn; àwọn tí ó sì yọ nínú ewu ní orílẹ̀-èdè mi ni yóò jogún ilẹ̀ wọn.”
- Sefaniah 2:10nǹkan bí 630 ṣáájú Kristi
Èyí ni ohun tí wọn yóò gbà padà nítorí ìgbéraga wọn, nítorí wọ́n kẹ́gàn, wọn sì ti fi àwọn ènìyàn Olúwa àwọn ọmọ-ogun ṣe ẹlẹ́yà.
- Sefaniah 2:11nǹkan bí 630 ṣáájú Kristi
Olúwa yóò jẹ́ ìbẹ̀rù fún wọn; nígbà tí Òun bá pa gbogbo òrìṣà ilẹ̀ náà run. Orílẹ̀-èdè láti etí odò yóò máa sìn, olúkúlùkù láti ilẹ̀ rẹ̀ wá.
- Sefaniah 2:12nǹkan bí 630 ṣáájú Kristi
“Ẹ̀yin Etiopia pẹ̀lú, a ó fi idà mi pa yín.”
- Sefaniah 2:13nǹkan bí 630 ṣáájú Kristi
Òun yóò sì na ọwọ́ rẹ̀ sí apá àríwá, yóò sì pa Asiria run, yóò sì sọ Ninefe di ahoro, àti di gbígbẹ bí aginjù.
- Sefaniah 2:14nǹkan bí 630 ṣáájú Kristi
Agbo ẹran yóò sì dùbúlẹ̀ ni àárín rẹ̀, àti gbogbo ẹranko àwọn orílẹ̀-èdè. Òwìwí aginjù àti ti n kígbe ẹyẹ òwìwí yóò wọ bí ẹyẹ ni ọwọ̀n rẹ̀. Ohùn wọn yóò kọrin ni ojú fèrèsé, ìdahoro yóò wà nínú ìloro ẹnu-ọ̀nà, òun yóò sì ṣẹ́ ọ̀pá kedari sílẹ̀.
- Sefaniah 2:15nǹkan bí 630 ṣáájú Kristi
Èyí ni ìlú aláyọ̀ tí ó ń gbé láìléwu. Ó sì sọ fun ara rẹ̀ pé, “Èmi ni, kò sì sí ẹnìkan tí ó ń bẹ lẹ́yìn mi.” Irú ahoro wo ni òun ha ti jẹ́, ibùgbé fún àwọn ẹranko igbó! Gbogbo ẹni tí ó bá kọjá ọ̀dọ̀ rẹ̀ yóò fi rẹ́rìn-ín ẹlẹ́yà, wọ́n yóò sì gbọn ẹsẹ̀ wọn.
- Sefaniah 3:1nǹkan bí 630 ṣáájú Kristi
Ègbé ni fún ìlú aninilára, ọlọ̀tẹ̀ àti aláìmọ́.
- Sefaniah 3:2nǹkan bí 630 ṣáájú Kristi
Òun kò gbọ́rọ̀ sí ẹnikẹ́ni, òun kò gba ìtọ́ni, òun kò gbẹ́kẹ̀lé Olúwa, bẹ́ẹ̀ ni òun kò súnmọ́ ọ̀dọ̀ Ọlọ́run rẹ̀.
- Sefaniah 3:3nǹkan bí 630 ṣáájú Kristi
Àwọn olórí rẹ̀ jẹ́ kìnnìún tí ń ké ramúramù, àwọn onídàájọ́ rẹ̀, ìkookò àṣálẹ́ ni wọn, wọn kò sì fi nǹkan kan kalẹ̀ fún òwúrọ̀.
- Sefaniah 3:4nǹkan bí 630 ṣáájú Kristi
Àwọn wòlíì rẹ̀ gbéraga, wọ́n sì jẹ́ alárékérekè ènìyàn. Àwọn àlùfáà rẹ̀ ti ba ibi mímọ́ jẹ́, wọ́n sì rú òfin.
- Sefaniah 3:5nǹkan bí 630 ṣáájú Kristi
Olúwa ni àárín rẹ̀ jẹ́ olódodo; kì yóò ṣe ohun tí kò tọ̀nà. Àràárọ̀ ni ó máa ń mú ìdájọ́ rẹ̀ wá sí ìmọ́lẹ̀, kì í sì kùnà ní gbogbo ọjọ́ tuntun, síbẹ̀ àwọn aláìṣòótọ́ kò mọ ìtìjú.
- Sefaniah 3:6nǹkan bí 630 ṣáájú Kristi
“Èmi ti ké àwọn orílẹ̀-èdè kúrò, ilé gíga wọn sì ti bàjẹ́. Mo ti fi ìgboro wọn sílẹ̀ ní òfo tó bẹ́ẹ̀ tí ẹnìkankan kò kọjá níbẹ̀. Ìlú wọn parun tó bẹ́ẹ̀ tí kò sí ẹnìkan tí yóò ṣẹ́kù, kò sì ní sí ẹnìkan rárá.
- Sefaniah 3:7nǹkan bí 630 ṣáájú Kristi
Èmi wí fún ìlú náà wí pé, ‘Nítòótọ́, ìwọ yóò bẹ̀rù mi, ìwọ yóò sì gba ìtọ́ni!’ Bẹ́ẹ̀ ni, a kì yóò ké ibùgbé rẹ̀ kúrò bí ó ti wù kí ń jẹ wọ́n ní yà tó. Ṣùgbọ́n síbẹ̀ wọ́n sì tún ní ìtara láti ṣe ìbàjẹ́.
- Sefaniah 3:8nǹkan bí 630 ṣáájú Kristi
Nítorí náà ẹ dúró dè mí,” ni Olúwa wí, “títí di ọjọ́ náà tí èmi yóò fi jẹ́rìí sí yin. Nítorí ìpinnu mi ni láti kó orílẹ̀-èdè jọ kí èmi kí ó lè kó ilẹ̀ ọba jọ àti láti da ìbínú mi jáde sórí wọn, àní gbogbo ìbínú gbígbóná mi. Nítorí gbogbo ayé ni a ó fi iná owú mi jẹ run.
- Sefaniah 3:9nǹkan bí 630 ṣáájú Kristi
“Nígbà náà ni èmi yóò yí èdè àwọn ènìyàn padà sí èdè mímọ́, nítorí kí gbogbo wọn bá a lè máa pe orúkọ Olúwa, láti fi ọkàn kan sìn ín.
- Sefaniah 3:10nǹkan bí 630 ṣáájú Kristi
Láti òkè odò Etiopia, àwọn olùjọsìn mi, àwọn ènìyàn mi tí ó ti fọ́nká, yóò mú ọrẹ wá fún mi.
- Sefaniah 3:11nǹkan bí 630 ṣáájú Kristi
Ní ọjọ́ náà ni a kì yóò sì dójútì nítorí gbogbo iṣẹ́ ibi ni tí ó ti ṣẹ̀ sí mi, nígbà náà ni èmi yóò mu kúrò nínú ìlú yìí, àwọn tí ń yọ̀ nínú ìgbéraga wọn. Ìwọ kì yóò sì gbéraga mọ́ ní òkè mímọ́ mi.
- Sefaniah 3:12nǹkan bí 630 ṣáájú Kristi
Ṣùgbọ́n Èmi yóò fi àwọn ọlọ́kàn tútù àti onírẹ̀lẹ̀ sílẹ̀ pẹ̀lú ni àárín rẹ̀, wọn yóò sì gbẹ́kẹ̀lé orúkọ Olúwa.
- Sefaniah 3:13nǹkan bí 630 ṣáájú Kristi
Àwọn ìyókù Israẹli kì yóò hùwà ibi, wọn kì yóò sọ̀rọ̀ èké. Bẹ́ẹ̀ ni a kì yóò rí ahọ́n àrékérekè ní ẹnu wọn. Àwọn yóò jẹun, wọn yóò sì dùbúlẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni ẹnikẹ́ni kì yóò dẹ́rùbà wọ́n.”
- Sefaniah 3:14nǹkan bí 630 ṣáájú Kristi
Kọrin, ìwọ ọmọbìnrin Sioni, kígbe sókè, ìwọ Israẹli! Fi gbogbo ọkàn yọ̀, kí inú rẹ kí ó sì dùn, ìwọ ọmọbìnrin Jerusalẹmu.
- Sefaniah 3:15nǹkan bí 630 ṣáájú Kristi
Olúwa ti mú ìdájọ́ rẹ wọ̀n-ọn-nì kúrò, ó sì ti ti àwọn ọ̀tá rẹ padà sẹ́yìn. Olúwa, ọba Israẹli wà pẹ̀lú rẹ; ìwọ kì yóò sì bẹ̀rù ibi kan mọ́.
- Sefaniah 3:16nǹkan bí 630 ṣáájú Kristi
Ní ọjọ́ náà, wọn yóò sọ fún Jerusalẹmu pé, “Má ṣe bẹ̀rù Sioni; má sì ṣe jẹ́ kí ọwọ́ rẹ kí ó dẹ̀.
- Sefaniah 3:17nǹkan bí 630 ṣáájú Kristi
Olúwa Ọlọ́run rẹ wà pẹ̀lú rẹ, Ó ní agbára láti gbà ọ là. Yóò yọ̀ ni orí rẹ fún ayọ̀; Yóò tún ọ ṣe nínú ìfẹ́ rẹ̀, Yóò sì fi orin yọ̀ ní orí rẹ.”
- Sefaniah 3:18nǹkan bí 630 ṣáájú Kristi
“Èmi ó kó àwọn tí ó ń banújẹ́ fún àjọ̀dún tí a yàn jọ, àwọn tí ó jẹ́ tirẹ̀; àwọn tí ẹ̀gàn rẹ̀ jásí ẹ̀rù.