Fò sí àkóónú

circa 800–400 BC

The Hebrew Prophets

God speaks through Isaiah, Jeremiah, and the minor prophets—calling Israel to repentance and foretelling the coming Messiah.

3,706 ẹsẹ · 14 ìwé tí a bo

Àwọn ẹsẹ láti sáà yìí

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Habakuku 1:8nǹkan bí 626 ṣáájú Kristi

    Ẹṣin wọn yára ju ẹkùn lọ, wọ́n sì gbóná jú ìkookò àṣálẹ́ lọ àwọn ẹlẹ́ṣin wọn yóò sí tan ara wọn ká; wọn yóò sì wá láti ọ̀nà jíjìn réré, wọn yóò sí fò bí ẹyẹ igún tí ń wá láti jẹrun,

  2. Habakuku 1:9nǹkan bí 626 ṣáájú Kristi

    gbogbo wọn sì wà fún ìwà ipá ìwò ojú wọn yóò sì wá síwájú; wọn sì ko ìgbèkùn jọ bí iyanrìn.

  3. Habakuku 1:10nǹkan bí 626 ṣáájú Kristi

    Wọn ó si máa fi àwọn ọba ṣẹ̀sín wọn ó sì tún kẹ́gàn àwọn aládé. Wọn yóò sì fi gbogbo ìlú odi alágbára nì rẹ́rìn-ín; nítorí pé, wọn yóò ko erùpẹ̀ jọ, wọn yóò sì gbà á.

  4. Habakuku 1:11nǹkan bí 626 ṣáájú Kristi

    Nígbà náà ni inú rẹ̀ yóò yípadà, yóò sì rékọjá, yóò si ṣẹ̀ ní kíka agbára rẹ̀ yìí sí iṣẹ́ òrìṣà rẹ̀.”

  5. Habakuku 1:12nǹkan bí 626 ṣáájú Kristi

    Olúwa, ǹjẹ́ láti ayérayé kọ ni ìwọ tí wà? Olúwa Ọlọ́run mi. Ẹni mímọ́ mi, àwa kì yóò kú Olúwa, ìwọ tí yàn wọn fún ìdájọ́; Ọlọ́run alágbára, ìwọ tí fi ẹsẹ̀ wọn múlẹ̀ fún ìbáwí.

  6. Habakuku 1:13nǹkan bí 626 ṣáájú Kristi

    Ojú rẹ mọ́ tónítóní láti wo ibi; ìwọ kò le gbà ìwà ìkà nítorí kí ni ìwọ ṣe gba àwọn alárékérekè láààyè? Nítorí kí ni ìwọ ṣe dákẹ́ nígbà tí ẹni búburú ń pa ẹni tí i ṣe olódodo ju wọn lọ run?

  7. Habakuku 1:14nǹkan bí 626 ṣáájú Kristi

    Ìwọ sì tí sọ ènìyàn di bí ẹja inú Òkun, bí ohun tí ń rákò tí wọn ko ni alákòóso.

  8. Habakuku 1:15nǹkan bí 626 ṣáájú Kristi

    Àwọn ènìyàn búburú fi àwọ̀n wọn gbé wọn sókè ó sì kó wọn jọ nínú àwọ̀n ńlá rẹ̀; nítorí náà, ó dunnú, ó sì yọ̀ pẹ̀lú.

  9. Habakuku 1:16nǹkan bí 626 ṣáájú Kristi

    Nítorí náà, ó rú ẹbọ sí àwọ̀n rẹ̀, ó sì ń sun tùràrí fún àwọ̀n ńlá rẹ̀ nítorí pẹ̀lú àwọ̀n rẹ̀ ni ó fi ń gbé ní ìgbádùn tí ó sì ń gbádùn pẹ̀lú oúnjẹ tí ó bá wù ú.

  10. Habakuku 1:17nǹkan bí 626 ṣáájú Kristi

    Ǹjẹ́ wọn yóò ha máa pa àwọ̀n wọn mọ́ ní òfìfo bí, tí wọn yóò sì pa orílẹ̀-èdè run láìsí àánú?

  11. Habakuku 2:1nǹkan bí 626 ṣáájú Kristi

    Èmi yóò dúró lórí ibusọ́ mi láti máa wòye, èmi yóò sì gbé ara mi ka orí alóre, èmi yóò si ṣọ́ láti gbọ́ ohun tí yóò sọ fún mi àti èsì ti èmi yóò fún ẹ̀sùn yìí nígbà tó bá ń bá mi wí.

  12. Habakuku 2:2nǹkan bí 626 ṣáájú Kristi

    Nígbà náà ni Olúwa dáhùn pé, “Kọ ìṣípayá náà sílẹ̀ kí o sì fi hàn ketekete lórí wàláà kí ẹni tí ń kà á, lè máa sáré.

  13. Habakuku 2:3nǹkan bí 626 ṣáájú Kristi

    Nítorí ìṣípayá náà jẹ́ tí ìgbà kan tí a múra sílẹ̀ dè; yóò máa yára sí ìgbẹ̀yìn kí yóò sìsọ èké. Bí o tilẹ̀ lọ́ra, dúró dè é; nítorí, dájúdájú, yóò dé, kí yóò sí pẹ́.”

  14. Habakuku 2:4nǹkan bí 626 ṣáájú Kristi

    “Kíyèsi, ọkàn rẹ tí ó gbéga, ìfẹ́ rẹ̀ kò dúró ṣinṣin nínú rẹ̀, ṣùgbọ́n olódodo yóò wa nípa ìgbàgbọ́ rẹ̀.

  15. Habakuku 2:5nǹkan bí 626 ṣáájú Kristi

    Bẹ́ẹ̀ ni pẹ̀lú, nítorí tí ọtí wáìnì ni ẹ̀tàn, agbéraga ènìyàn òun, kò sì ní sinmi ẹni tí ó sọ ìwọra rẹ di gbígbòòrò bí isà òkú, ó sì dàbí ikú, a kò sì le tẹ́ ẹ lọ́rùn, ó kó gbogbo orílẹ̀-èdè jọ sí ọ̀dọ̀ ó sì gba gbogbo ènìyàn jọ sí ọ̀dọ̀ rẹ̀.

  16. Habakuku 2:6nǹkan bí 626 ṣáájú Kristi

    “Gbogbo àwọn wọ̀nyí kì yóò máa pa òwe sí i tí wọn yóò sì máa kọ orin òwe sí i wí pé, “ ‘Ègbé ni fún ẹni tí ń mu ohun tí kì í ṣe tirẹ̀ pọ̀ sí i! Tí ó sì sọ ara rẹ̀ di ọlọ́rọ̀ nípasẹ̀ ìlọ́nilọ́wọ́gbà! Eléyìí yóò ha ti pẹ́ tó?’

  17. Habakuku 2:7nǹkan bí 626 ṣáájú Kristi

    Ǹjẹ́ ẹni ti ó yọ ọ́ lẹ́nu, kí yóò ha dìde ní òjijì? Àti àwọn tí ó wàhálà rẹ kì yóò jí, kí wọn ó sì dẹ́rùbà ọ́? Nígbà náà ni ìwọ yóò wa dí ìkógun fún wọn.

  18. Habakuku 2:8nǹkan bí 626 ṣáájú Kristi

    Nítorí ìwọ ti kó Orílẹ̀-èdè púpọ̀, àwọn ènìyàn tókù yóò sì kó ọ nítorí ìwọ tí ta ẹ̀jẹ̀ ènìyàn sílẹ̀; nítorí ẹ̀jẹ̀, ìwọ tí pa ilẹ̀ àti ìlú ńlá run àti gbogbo ènìyàn to ń gbé inú rẹ̀.

  19. Habakuku 2:9nǹkan bí 626 ṣáájú Kristi

    “Ègbé ni fún ẹni tí ń jẹ èrè ìjẹkújẹ sí ilé rẹ̀, tí o sí gbé ìtẹ́ rẹ̀ lórí ibi gíga, kí a ba le gbà á sílẹ̀ kúrò lọ́wọ́ ibi!

  20. Habakuku 2:10nǹkan bí 626 ṣáájú Kristi

    Ìwọ ti gbìmọ̀ ìtìjú sí ilé rẹ nípa kíké ènìyàn púpọ̀ kúrò; ìwọ sì ti pàdánù ẹ̀mí rẹ.

  21. Habakuku 2:11nǹkan bí 626 ṣáájú Kristi

    Nítorí tí òkúta yóò kígbe jáde láti inú ògiri wá, àti ìtí igi láti inú igi rírẹ́ wá yóò sì dá a lóhùn.

  22. Habakuku 2:12nǹkan bí 626 ṣáájú Kristi

    “Ègbé ni fún ẹni tí ó fi ẹ̀jẹ̀ kọ́ ìlú, tí o sì fi àìṣedéédéé tẹ ìlú ńlá dó?

  23. Habakuku 2:13nǹkan bí 626 ṣáájú Kristi

    Olúwa àwọn ọmọ-ogun kò ha ti ṣètò rẹ̀ pé làálàá àwọn ènìyàn jẹ́ epo fún iná kí àwọn orílẹ̀-èdè náà sì máa ṣe wàhálà fún asán?

  24. Habakuku 2:14nǹkan bí 626 ṣáájú Kristi

    Nítorí tí ayé yóò kún fún ìmọ̀ ògo Olúwa, bí omi ti bo Òkun.

  25. Habakuku 2:15nǹkan bí 626 ṣáájú Kristi

    “Ègbé ni fún ẹni tí ó fi ohun mímu fún aládùúgbò rẹ̀, tí ó sì fi ọtí-lílé rẹ̀ fún un, tí o sì jẹ́ kó mu àmupara, kí ìwọ kí ó ba lè wo ìhòhò wọn.”