Fò sí àkóónú

circa 800–400 BC

The Hebrew Prophets

God speaks through Isaiah, Jeremiah, and the minor prophets—calling Israel to repentance and foretelling the coming Messiah.

3,706 ẹsẹ · 14 ìwé tí a bo

Àwọn ẹsẹ láti sáà yìí

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Mika 5:6nǹkan bí 710 ṣáájú Kristi

    Wọn yóò sì fi idà pa ilẹ̀ Asiria run, àti ilẹ̀ Nimrodu pẹ̀lú idà tí a fà. Òun yóò sì gbà wá sílẹ̀ lọ́wọ́ àwọn ará Asiria nígbà tí wọn bá gbógun ti ilẹ̀ wa tí wọ́n sì tún yan wọ ẹnu-bodè wa.

  2. Mika 5:7nǹkan bí 710 ṣáájú Kristi

    Ìyókù Jakọbu yóò sì wà láàrín ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn bí ìrì láti ọ̀dọ̀ Olúwa wa, bí ọ̀wààrà òjò lórí koríko, tí kò gbẹ́kẹ̀lé ènìyàn tàbí kò dúró de àwọn ọmọ ènìyàn.

  3. Mika 5:8nǹkan bí 710 ṣáájú Kristi

    Ìyókù Jakọbu yóò sì wà láàrín àwọn aláìkọlà ní àárín àwọn ọ̀pọ̀ ènìyàn, bí i kìnnìún láàrín àwọn ẹranko inú igbó, bí i ọmọ kìnnìún láàrín agbo àgùntàn, èyí tí ó máa ń fà á ya pẹ́rẹpẹ̀rẹ, tí ó sì máa ń tẹ̀ ẹ́ mọ́lẹ̀, tí kò sì ṣí ẹnìkan tí ó lè gbà á là.

  4. Mika 5:9nǹkan bí 710 ṣáájú Kristi

    A ó gbé ọwọ́ rẹ̀ sókè ní ìṣẹ́gun lórí àwọn ọ̀tá rẹ̀, gbogbo àwọn ọ̀tá rẹ̀ sì ni a ó parun.

  5. Mika 5:10nǹkan bí 710 ṣáájú Kristi

    “Ní ọjọ́ náà,” ni Olúwa wí, “Èmi yóò pa àwọn ẹṣin rẹ̀ run kúrò láàrín rẹ èmi yóò sì pa àwọn kẹ̀kẹ́ ogun rẹ̀ run.

  6. Mika 5:11nǹkan bí 710 ṣáájú Kristi

    Èmi yóò sì pa ilẹ̀ ìlú ńlá rẹ̀ run, èmi ó sì fa gbogbo ibi gíga rẹ̀ ya.

  7. Mika 5:12nǹkan bí 710 ṣáájú Kristi

    Èmi yóò gé ìwà àjẹ́ kúrò lọ́wọ́ rẹ̀, ìwọ kì yóò sì ní aláfọ̀ṣẹ mọ́.

  8. Mika 5:13nǹkan bí 710 ṣáájú Kristi

    Èmi yóò pa àwọn ère fínfín rẹ̀ run, àti ọwọ̀n rẹ̀ kúrò láàrín rẹ̀; ìwọ kì yóò sì le è foríbalẹ̀ fún iṣẹ́ ọwọ́ rẹ mọ́.

  9. Mika 5:14nǹkan bí 710 ṣáájú Kristi

    Èmi yóò fa ère Aṣerah tu kúrò láàrín rẹ̀, èmi yóò sì pa ìlú ńlá rẹ̀ run.

  10. Mika 5:15nǹkan bí 710 ṣáájú Kristi

    Èmi yóò gbẹ̀san ní ìbínú àti ìrunú lórí àwọn orílẹ̀-èdè tí kò ti tẹríba fún mi.”

  11. Mika 6:1nǹkan bí 710 ṣáájú Kristi

    Ẹ fi etí sí ohun tí Olúwa wí: “Dìde dúró, bẹ ẹ̀bẹ̀ fún ẹjọ́ rẹ níwájú òkè ńlá; sì jẹ́ kí àwọn òkè kéékèèké gbọ́ ohun tí ó fẹ́ wí.

  12. Mika 6:2nǹkan bí 710 ṣáájú Kristi

    “Gbọ́, ìwọ òkè ńlá, ẹ̀sùn Olúwa; gbọ́, ìwọ ìpìlẹ̀ ilé ayérayé. Nítorí Olúwa ń bá àwọn ènìyàn rẹ̀ wíjọ́; òun yóò sì bá Israẹli rojọ́.

  13. Mika 6:3nǹkan bí 710 ṣáájú Kristi

    “Ẹ̀yin ènìyàn mi, kí ni mo ṣe fún yín? Àti nínú kí ni mo ti dá yin lágara? Dá mi lóhùn.

  14. Mika 6:4nǹkan bí 710 ṣáájú Kristi

    Nítorí èmi mú un yín gòkè láti ilẹ̀ Ejibiti wá, mo sì rà yín padà láti ilẹ̀ ẹrú wá. Mo rán Mose láti darí yín, bákan náà mo rán Aaroni àti Miriamu síwájú rẹ̀.

  15. Mika 6:5nǹkan bí 710 ṣáájú Kristi

    Ìwọ ènìyàn mi, rántí ohun tí Balaki ọba Moabu gbèrò àti ohun tí Balaamu ọmọ Beori dáhùn. Rántí ìrìnàjò rẹ̀ láti Ṣittimu dé Gilgali, kí ìwọ ba le mọ òdodo Olúwa.”

  16. Mika 6:6nǹkan bí 710 ṣáájú Kristi

    Kí ni èmi yóò ha mú wá síwájú Olúwa tí èmi ó fi tẹ ara mi ba níwájú Ọlọ́run gíga? Kí èmi ha wá sí iwájú rẹ̀ pẹ̀lú ọrẹ ẹbọ sísun, pẹ̀lú ọmọ màlúù ọlọ́dún kan?

  17. Mika 6:7nǹkan bí 710 ṣáájú Kristi

    Ǹjẹ́ Olúwa yóò ní inú dídùn sí ẹgbẹgbàarùn-ún àgbò, tàbí sí ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá ìṣàn òróró? Èmi yóò ha fi àkọ́bí mi sílẹ̀ fún ìré-òfin-kọjá mi, èso inú ara mi fún ẹ̀ṣẹ̀ ọkàn mi?

  18. Mika 6:8nǹkan bí 710 ṣáájú Kristi

    Ó ti fihàn ọ́, ìwọ ènìyàn, ohun tí ó dára, àti ohun tí Olúwa ń béèrè lọ́wọ́ rẹ? Bí kò ṣe láti ṣe òtítọ́, kí o sì fẹ́ràn àánú, àti kí o rìn ní ìrẹ̀lẹ̀ pẹ̀lú Ọlọ́run rẹ̀.

  19. Mika 6:9nǹkan bí 710 ṣáájú Kristi

    Gbọ́! Ohùn Olúwa kígbe sí ìlú ńlá náà, láti jẹ ọlọ́gbọ́n ni láti bẹ̀rù orúkọ rẹ. “Ẹ kíyèsi ọ̀pá rẹ̀ gbọ́ ọ̀pá àti Ẹni náà tí ó yàn án.

  20. Mika 6:10nǹkan bí 710 ṣáájú Kristi

    Ǹjẹ́ ìṣúra ìwà búburú ha wà ní ilé ènìyàn búburú síbẹ̀, àti òsùwọ̀n àìkún tí ó jẹ́ ohun ìbínú?

  21. Mika 6:11nǹkan bí 710 ṣáájú Kristi

    Ǹjẹ́ èmi ha lè kà wọ́n sí mímọ́ pẹ̀lú òsùwọ̀n búburú, pẹ̀lú àpò òsùwọ̀n ẹ̀tàn?

  22. Mika 6:12nǹkan bí 710 ṣáájú Kristi

    Àwọn ọlọ́rọ̀ inú rẹ̀ kún fún ìwà ipá; àwọn tí ń gbé inú rẹ̀ ti ọ̀rọ̀ èké àti ahọ́n wọn ń sọ ẹ̀tàn?

  23. Mika 6:13nǹkan bí 710 ṣáájú Kristi

    Nítorí náà ni èmi yóò ṣe mú ọ ṣàìsàn ní lílù ọ́, láti sọ ọ́ dahoro nítorí ẹ̀ṣẹ̀ rẹ.

  24. Mika 6:14nǹkan bí 710 ṣáájú Kristi

    Ìwọ yóò jẹun ṣùgbọ́n kì yóò yó; ìyàn yóò wà láàrín rẹ. Ìwọ yóò kó pamọ́, ṣùgbọ́n ìwọ kì yóò lò láìléwu, nítorí ohun tí ìwọ kò pamọ́ ni èmi yóò fi fún idà.

  25. Mika 6:15nǹkan bí 710 ṣáájú Kristi

    Ìwọ yóò gbìn ṣùgbọ́n ìwọ kì yóò kórè ìwọ yóò tẹ olifi, ṣùgbọ́n ìwọ kì yóò fi òróró rẹ̀ kún ara rẹ; ìwọ yóò tẹ èso àjàrà, ṣùgbọ́n ìwọ kì yóò mu wáìnì.