- English
- King James KJV
- Complete Jewish CJB
- World English WEBM
- Berean Standard BSB
- American Standard ASV
- Geneva GNV
- Young's Literal YLT
- Douay-Rheims DRC
- International
- Shqip ALB
- العربية SVD
- বাংলা BN-IRV
- မြန်မာ Judson
- 简体文 CUV-S
- 繁體中文 CUV-T
- Čeština BKR
- Nederlands STVE
- Français LSG
- Deutsch SCH
- Ελληνικά Vamvas
- ગુજરાતી GU-IRV
- Hausa HCB
- עברית Hebrew
- हिन्दी HCV
- Magyar KAROLI
- Bahasa Indonesia INDO-TB
- Italiano Diodati
- 日本語 Kougo
- 한국어 Korean
- മലയാളം MAL
- मराठी MRCV
- Norsk DNB
- فارسی OPV
- Polski BG
- Português Almeida
- Română Cornilescu
- Русский Synodal
- Español RVG
- Kiswahili Neno
- Svenska SV1917
- Tagalog TAG-ADB
- தமிழ் TCV
- తెలుగు TSA
- ภาษาไทย THAI-KJV
- Українська Ohienko
- Tiếng Việt CADMAN
- Yorùbá YCB
circa 800–400 BC
The Hebrew Prophets
God speaks through Isaiah, Jeremiah, and the minor prophets—calling Israel to repentance and foretelling the coming Messiah.
Àwọn ẹsẹ láti sáà yìí
- Mika 1:10nǹkan bí 750 ṣáájú Kristi
Ẹ má ṣe sọ ní Gati ẹ má ṣe sọkún rárá. Ní ilẹ̀ Beti-Ofra mo yí ara mi nínú eruku.
- Mika 1:11nǹkan bí 750 ṣáájú Kristi
Ẹ kọjá lọ ni ìhòhò àti ni ìtìjú, ìwọ tí ó ń gbé ni Ṣafiri. Àwọn tí ó ń gbé ni Saanani kì yóò sì jáde wá. Beti-Eseli wà nínú ọ̀fọ̀; a ó sì gba ààbò rẹ̀ kúrò lọ́wọ́ yin.
- Mika 1:12nǹkan bí 750 ṣáájú Kristi
Nítorí àwọn tí ó ń gbé ni Marati ń retí ìre, ṣùgbọ́n ibi sọ̀kalẹ̀ ti ọ̀dọ̀ Olúwa wá sí ẹnu-bodè Jerusalẹmu.
- Mika 1:13nǹkan bí 750 ṣáájú Kristi
Ìwọ olùgbé Lakiṣi, dì kẹ̀kẹ́ mọ́ ẹranko tí ó yára. Òun sì ni ìbẹ̀rẹ̀ ẹ̀ṣẹ̀ sí àwọn ọmọbìnrin Sioni, nítorí a rí àìṣedéédéé Israẹli nínú rẹ̀.
- Mika 1:14nǹkan bí 750 ṣáájú Kristi
Nítorí náà ni ìwọ ó ṣe fi ìwé ìkọ̀sílẹ̀ fún Moreṣeti Gati. Àwọn ilé Aksibu yóò jẹ́ ẹlẹ́tàn sí àwọn ọba Israẹli.
- Mika 1:15nǹkan bí 750 ṣáájú Kristi
Èmi yóò sì mú àrólé kan wá sórí rẹ ìwọ olùgbé Meraṣa. Ẹni tí ó jẹ́ ògo Israẹli yóò sì wá sí Adullamu.
- Mika 1:16nǹkan bí 750 ṣáájú Kristi
Fá irun orí rẹ nínú ọ̀fọ̀ nítorí àwọn ọmọ rẹ aláìlágbára, sọ ra rẹ̀ di apárí bí ẹyẹ igún, nítorí wọn yóò kúrò lọ́dọ̀ rẹ lọ sí ìgbèkùn.
- Mika 2:1nǹkan bí 730 ṣáájú Kristi
Ègbé ni fún àwọn tí ń gbèrò àìṣedéédéé tí wọ́n sì ń ṣiṣẹ́ ibi lórí ibùsùn wọn! Nígbà tí ojúmọ́ bá mọ́, wọn yóò gbé e jáde nítorí ó wà ní agbára wọn láti ṣe é.
- Mika 2:2nǹkan bí 730 ṣáájú Kristi
Wọ́n sì ń ṣe ojúkòkòrò oko, wọ́n sì fi agbára wọn gbà wọ́n, àti àwọn ilé, wọ́n sì gbà wọ́n. Wọ́n sì ni ènìyàn àti ilẹ̀ rẹ̀ lára àní ènìyàn àti ohun ìní rẹ̀.
- Mika 2:3nǹkan bí 730 ṣáájú Kristi
Nítorí náà, Olúwa wí pé: “Èmi ń gbèrò ibi sí àwọn ìdílé wọ̀nyí, nínú èyí tí wọn kì yóò le è gba ara wọn là. Ìwọ kì yóò sì lè máa rìn ní ìgbéraga mọ́, nítorí yóò jẹ́ àkókò ibi.
- Mika 2:4nǹkan bí 730 ṣáájú Kristi
Ní ọjọ́ náà ni ẹnìkan yóò pa òwe kan sí yín; wọn yóò sì pohùnréré ẹkún kíkorò pé: ‘Ní kíkó a ti kó wọn tán; Olúwa ti pín ohun ìní àwọn ènìyàn mi; Ó ti mú un kúrò lọ́dọ̀ mi! Ó fi oko wa lé àwọn ọlọ̀tẹ̀ lọ́wọ́.’ ”
- Mika 2:5nǹkan bí 730 ṣáájú Kristi
Nítorí náà, ìwọ kò ní ní ẹnìkankan tí yóò ta okùn nínú ìjọ Olúwa, tí yóò pín ilẹ̀ nípa ìbò.
- Mika 2:6nǹkan bí 730 ṣáájú Kristi
“Ẹ má ṣe sọtẹ́lẹ̀,” ni àwọn wòlíì wọn wí. “Ẹ má ṣe sọtẹ́lẹ̀ nípa nǹkan wọ̀nyí; kí ìtìjú má ṣe le bá wa.”
- Mika 2:7nǹkan bí 730 ṣáájú Kristi
Ṣé kí á sọ ọ́, ìwọ ilé Jakọbu: “Ǹjẹ́ ẹ̀mí Olúwa ha ń bínú bí? Ǹjẹ́ iṣẹ́ rẹ ha nìwọ̀nyí?” “Ǹjẹ́ ọ̀rọ̀ mi kò ha ń ṣe rere fún ẹni tí ń rìn déédé bí?
- Mika 2:8nǹkan bí 730 ṣáájú Kristi
Láìpẹ́ àwọn ènìyàn mi dìde bí ọ̀tá sí mi. Ìwọ bọ́ aṣọ ọlọ́rọ̀ kúrò lára àwọn tí ń kọjá lọ ní àìléwu, bí àwọn ẹni tí ó padà bọ̀ láti ojú ogun.
- Mika 2:9nǹkan bí 730 ṣáájú Kristi
Ẹ̀yin sì lé obìnrin àwọn ènìyàn mi kúrò nínú ilé ayọ̀ wọn, ẹ̀yin sì ti gba ògo mi, kúrò lọ́wọ́ àwọn ọmọ wọn láéláé.
- Mika 2:10nǹkan bí 730 ṣáájú Kristi
Ẹ dìde, kí ẹ sì máa lọ! Nítorí èyí kì í ṣe ibi ìsinmi yín, nítorí tí a ti sọ ọ́ di àìmọ́ yóò pa yín run, àní ìparun kíkorò.
- Mika 2:11nǹkan bí 730 ṣáájú Kristi
Tí òpùrọ́ àti ẹlẹ́tàn bá wà tí wọ́n sì wí pé, ‘Èmi yóò sọtẹ́lẹ̀ fún ọ nípa ọ̀pọ̀lọpọ̀ wáìnì àti ọtí líle,’ òun ni yóò tilẹ̀ ṣe wòlíì àwọn ènìyàn wọ̀nyí!
- Mika 2:12nǹkan bí 730 ṣáájú Kristi
“Èmi yóò kó gbogbo yín jọ, ìwọ Jakọbu; Èmi yóò gbá ìyókù Israẹli jọ. Èmi yóò kó wọn jọ pọ̀ gẹ́gẹ́ bí àgùntàn nínú agbo ẹran, gẹ́gẹ́ bí ọ̀wọ́ ẹran nínú agbo wọn, ibẹ̀ yóò sì pariwo nítorí ọ̀pọ̀ ènìyàn.
- Mika 2:13nǹkan bí 730 ṣáájú Kristi
Ẹni tí ó ń fọ ọ̀nà yóò lọ sókè níwájú wọn; wọn yóò fọ láti ẹnu ibodè, wọn yóò sì jáde lọ. Àwọn ọba wọn yóò sì kọjá lọ níwájú wọn, Olúwa ni yóò sì ṣe olórí wọn.”
- Mika 3:1nǹkan bí 710 ṣáájú Kristi
Nígbà náà, ni mo wí pé, “Ẹ gbọ́, ẹ̀yin olórí Jakọbu, ẹ̀yin alákòóso ilé Israẹli. Ǹjẹ́ ẹ̀yin kò ha ni í gba òdodo bí.
- Mika 3:2nǹkan bí 710 ṣáájú Kristi
Ẹ̀yin tí ó kórìíra ìre, tí ẹ sì fẹ́ràn ibi; ẹ̀yin tí ẹ fa awọ ẹran-ara àwọn ènìyàn mi ya kúrò lára wọn àti ẹran-ara wọn kúrò ní egungun wọn;
- Mika 3:3nǹkan bí 710 ṣáájú Kristi
àwọn tí ó jẹ ẹran-ara àwọn ènìyàn mi, wọn sì bọ́ awọ ara wọn kúrò lára wọn. Wọ́n sì fọ́ egungun wọn sí wẹ́wẹ́; wọn sì gé e sí wẹ́wẹ́ bí ẹran inú ìkòkò, bí ẹran inú agbada?”
- Mika 3:4nǹkan bí 710 ṣáájú Kristi
Nígbà náà ni wọn yóò kígbe sí Olúwa, ṣùgbọ́n òun kì yóò dá wọn lóhùn. Ní àkókò náà ni òun yóò fi ojú rẹ̀ pamọ́ kúrò lọ́dọ̀ wọn, nítorí ibi tí wọ́n ti ṣe.
- Mika 3:5nǹkan bí 710 ṣáájú Kristi
Báyìí ni Olúwa wí, “Ní ti àwọn Wòlíì tí ń ṣi àwọn ènìyàn mi lọ́nà, tí ẹnìkan bá fún wọn ní oúnjẹ, wọn yóò kéde àlàáfíà; ṣùgbọ́n tí kò bá fi nǹkan sí wọn ní ẹnu, wọn yóò múra ogun sí i.