- English
- King James KJV
- Complete Jewish CJB
- World English WEBM
- Berean Standard BSB
- American Standard ASV
- Geneva GNV
- Young's Literal YLT
- Douay-Rheims DRC
- International
- Shqip ALB
- العربية SVD
- বাংলা BN-IRV
- မြန်မာ Judson
- 简体文 CUV-S
- 繁體中文 CUV-T
- Čeština BKR
- Nederlands STVE
- Français LSG
- Deutsch SCH
- Ελληνικά Vamvas
- ગુજરાતી GU-IRV
- Hausa HCB
- עברית Hebrew
- हिन्दी HCV
- Magyar KAROLI
- Bahasa Indonesia INDO-TB
- Italiano Diodati
- 日本語 Kougo
- 한국어 Korean
- മലയാളം MAL
- मराठी MRCV
- Norsk DNB
- فارسی OPV
- Polski BG
- Português Almeida
- Română Cornilescu
- Русский Synodal
- Español RVG
- Kiswahili Neno
- Svenska SV1917
- Tagalog TAG-ADB
- தமிழ் TCV
- తెలుగు TSA
- ภาษาไทย THAI-KJV
- Українська Ohienko
- Tiếng Việt CADMAN
- Yorùbá YCB
circa 800–400 BC
The Hebrew Prophets
God speaks through Isaiah, Jeremiah, and the minor prophets—calling Israel to repentance and foretelling the coming Messiah.
Àwọn ẹsẹ láti sáà yìí
- Jona 3:6nǹkan bí 862 ṣáájú Kristi
Ọ̀rọ̀ náà sì dé ọ̀dọ̀ ọba Ninefe, ó sì dìde kúrò lórí ìtẹ́ rẹ̀, ó sì bọ́ aṣọ ìgúnwà rẹ̀ kúrò lára rẹ̀, ó sì da aṣọ ọ̀fọ̀ bora, ó sì jókòó nínú eérú.
- Jona 3:7nǹkan bí 862 ṣáájú Kristi
Nígbà náà ní ó kéde rẹ̀ ni Ninefe pé, “Kí a la Ninefe já nípa àṣẹ ọba, àti àwọn àgbàgbà rẹ̀ pé: “Má ṣe jẹ́ kí ènìyàn, tàbí ẹranko, ọ̀wọ́ ẹran tàbí agbo ẹran, tọ́ ohunkóhun wò, má jẹ́ kí wọn jẹ tàbí mu omi.
- Jona 3:8nǹkan bí 862 ṣáájú Kristi
Ṣùgbọ́n jẹ́ kí ènìyàn àti ẹranko da aṣọ ọ̀fọ̀ bo ara, kí wọn sì kígbe kíkan sí Ọlọ́run, sì jẹ́ kí wọn yípadà, olúkúlùkù kúrò ní ọ̀nà ibi rẹ̀ àti kúrò ní ìwà ìpa tí ó wà lọ́wọ́ wọn.
- Jona 3:9nǹkan bí 862 ṣáájú Kristi
Ta ni ó lè mọ̀ bí Ọlọ́run yóò yípadà kí ó sì ronúpìwàdà, kí ó sì yípadà kúrò ní ìbínú gbígbóná rẹ̀, kí àwa má ṣègbé?”
- Jona 3:10nǹkan bí 862 ṣáájú Kristi
Ọlọ́run sì rí ìṣe wọn pé wọ́n yípadà kúrò ní ọ̀nà ibi wọn, Ọlọ́run sì ronúpìwàdà ibi tí òun ti wí pé òun yóò ṣe sí wọn, òun kò sì ṣe e mọ́.
- Jona 4:1nǹkan bí 862 ṣáájú Kristi
Ṣùgbọ́n ó ba Jona nínú jẹ́ gidigidi, ó sì bínú púpọ̀.
- Jona 4:2nǹkan bí 862 ṣáájú Kristi
Ó sì gbàdúrà sí Olúwa, ó sì wí pé, “Èmí bẹ̀ ọ́, Olúwa, ǹjẹ́ ọ̀rọ̀ ti mo sọ kọ́ ni èyí nígbà tí mo wà ní ilẹ̀ mi? Nítorí èyí ni mo ṣé sálọ sí Tarṣiṣi ní ìṣáájú: nítorí èmi mọ̀ pé, Ọlọ́run olóore-ọ̀fẹ́ ní ìwọ, àti aláàánú, O lọ́ra láti bínú, O sì ṣeun púpọ̀, O sì ronúpìwàdà ibi náà.
- Jona 4:3nǹkan bí 862 ṣáájú Kristi
Ǹjẹ́ báyìí, Olúwa, èmi bẹ̀ ọ, gba ẹ̀mí mi kúrò lọ́wọ́ mi nítorí ó sàn fún mi láti kú ju àti wà láààyè lọ.”
- Jona 4:4nǹkan bí 862 ṣáájú Kristi
Nígbà náà ni Olúwa wí pé, “Ìwọ́ ha ni ẹ̀tọ́ láti bínú bí?”
- Jona 4:5nǹkan bí 862 ṣáájú Kristi
Jona sì jáde kúrò ní ìlú náà, ó sì jókòó níhà ìlà-oòrùn ìlú náà. Ó sì pa àgọ́ kan níbẹ̀ fún ara rẹ̀, ó sì jókòó ni òjìji ní abẹ́ rẹ̀ títí yóò fi rí ohun tí yóò ṣẹlẹ̀ sí ìlú náà.
- Jona 4:6nǹkan bí 862 ṣáájú Kristi
Olúwa Ọlọ́run sì pèsè ìtàkùn kan, ó ṣe é kí ó gòkè wá sórí Jona; kí ó lè ṣe ìji bò ó lórí; láti gbà á kúrò nínú ìbànújẹ́ rẹ̀. Jona sì yọ ayọ̀ ńlá nítorí ìtàkùn náà.
- Jona 4:7nǹkan bí 862 ṣáájú Kristi
Ṣùgbọ́n Ọlọ́run pèsè kòkòrò kan nígbà tí ilẹ̀ mọ́ ní ọjọ́ kejì, ó sì jẹ ìtàkùn náà ó sì rọ.
- Jona 4:8nǹkan bí 862 ṣáájú Kristi
Ó sì ṣe, nígbà tí oòrùn yọ, Ọlọ́run pèsè ẹ̀fúùfù gbígbóná tí ìlà-oòrùn; oòrùn sì pa Jona lórí tó bẹ́ẹ̀ tí ó fi rẹ̀ ẹ́. Ó sì fẹ́ nínú ara rẹ̀ láti kú, ó sì wí pé, “Ó sàn fún mi láti kú ju àti wà láààyè lọ.”
- Jona 4:9nǹkan bí 862 ṣáájú Kristi
Ọlọ́run sì wí fún Jona pé, “O ha tọ́ fún ọ láti bínú nítorí ìtàkùn náà?” Òun sì wí pé, “Mo ni ẹ̀tọ́, o tọ́ fún mi láti bínú títí dé ikú.”
- Jona 4:10nǹkan bí 862 ṣáájú Kristi
Nígbà náà ni Olúwa wí pé, “Ìwọ kẹ́dùn ìtàkùn náà, nítorí èyí tí ìwọ kò ṣiṣẹ́ fun, tí ìwọ kò mu dàgbà; tí ó hù jáde ní òru kan tí ó sì kú ni òru kan.
- Jona 4:11nǹkan bí 862 ṣáájú Kristi
Ṣùgbọ́n Ninefe ní jù ọ̀kẹ́ mẹ́fà (120,000) ènìyàn nínú rẹ̀, tí wọn kò mọ ọwọ́ ọ̀tún wọn yàtọ̀ sí ti òsì, àti ọ̀pọ̀lọpọ̀ ohun ọ̀sìn pẹ̀lú. Ṣé èmí kò ha ní kẹ́dùn nípa ìlú ńlá náà?”
- Mika 1:1nǹkan bí 750 ṣáájú Kristi
Ọ̀rọ̀ Olúwa tí ó tọ Mika ará Moreṣeti wá ní àkókò ìjọba Jotamu, Ahasi, àti Hesekiah, àwọn ọba Juda nìwọ̀nyí, ìran tí ó rí nípa Samaria àti Jerusalẹmu.
- Mika 1:2nǹkan bí 750 ṣáájú Kristi
Ẹ gbọ́, gbogbo ẹ̀yin ènìyàn, fetísílẹ̀, ìwọ ayé àti gbogbo ohun tó wà níbẹ̀, kí Olúwa Olódùmarè lè ṣe ẹlẹ́rìí sí yín, Olúwa láti inú tẹmpili mímọ́ rẹ̀ wá.
- Mika 1:3nǹkan bí 750 ṣáájú Kristi
Wò ó! Olúwa ń bọ̀ wá láti ibùgbé rẹ̀; yóò sọ̀kalẹ̀, yóò sì tẹ ibi gíga ayé mọ́lẹ̀.
- Mika 1:4nǹkan bí 750 ṣáájú Kristi
Àwọn òkè ńlá yóò sí yọ́ lábẹ́ rẹ̀, àwọn àfonífojì yóò sì pínyà, bí idà níwájú iná, bí omi tí ó ń sàn lọ ni ibi gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́.
- Mika 1:5nǹkan bí 750 ṣáájú Kristi
Nítorí ìré-òfin-kọjá Jakọbu ni gbogbo èyí, àti nítorí ẹ̀ṣẹ̀ ilé Israẹli. Kí ni ìré-òfin-kọjá Jakọbu? Ǹjẹ́ Samaria ha kọ? Kí ni àwọn ibi gíga Juda? Ǹjẹ́ Jerusalẹmu ha kọ?
- Mika 1:6nǹkan bí 750 ṣáájú Kristi
“Nítorí náà, èmi yóò ṣe Samaria bí òkìtì lórí pápá, bí ibi ti à ń lò fún gbígbin ọgbà àjàrà. Èmi yóò gbá àwọn òkúta rẹ̀ dànù sínú àfonífojì. Èmi yóò sí tú ìpilẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ palẹ̀.
- Mika 1:7nǹkan bí 750 ṣáájú Kristi
Gbogbo àwọn ère fínfín rẹ̀ ni a ó fọ́ sí wẹ́wẹ́ gbogbo àwọn ẹ̀bùn tẹmpili rẹ̀ ni a ó fi iná sun, Èmi yóò sì pa gbogbo àwọn òrìṣà rẹ̀ run. Nítorí tí ó ti kó àwọn ẹ̀bùn rẹ̀ jọ láti inú owó èrè panṣágà, gẹ́gẹ́ bí owó èrè panṣágà, wọn yóò sì tún padà sí owó iṣẹ́ panṣágà.”
- Mika 1:8nǹkan bí 750 ṣáájú Kristi
Nítorí èyí, èmi yóò sì sọkún, èmi yóò sì pohùnréré ẹkún: èmi yóò máa lọ ní ẹsẹ̀ lásán àti ní ìhòhò. Èmi yóò ké bí akátá, èmi yóò sì máa dárò bí àwọn ọmọ ògòǹgò.
- Mika 1:9nǹkan bí 750 ṣáájú Kristi
Nítorí tí ọgbẹ́ rẹ̀ jẹ́ aláìlèwòtán; ó sì ti wá sí Juda. Ó sì ti dé ẹnu-bodè àwọn ènìyàn mi, àní sí Jerusalẹmu.