- English
- King James KJV
- Complete Jewish CJB
- World English WEBM
- Berean Standard BSB
- American Standard ASV
- Geneva GNV
- Young's Literal YLT
- Douay-Rheims DRC
- International
- Shqip ALB
- العربية SVD
- বাংলা BN-IRV
- မြန်မာ Judson
- 简体文 CUV-S
- 繁體中文 CUV-T
- Čeština BKR
- Nederlands STVE
- Français LSG
- Deutsch SCH
- Ελληνικά Vamvas
- ગુજરાતી GU-IRV
- Hausa HCB
- עברית Hebrew
- हिन्दी HCV
- Magyar KAROLI
- Bahasa Indonesia INDO-TB
- Italiano Diodati
- 日本語 Kougo
- 한국어 Korean
- മലയാളം MAL
- मराठी MRCV
- Norsk DNB
- فارسی OPV
- Polski BG
- Português Almeida
- Română Cornilescu
- Русский Synodal
- Español RVG
- Kiswahili Neno
- Svenska SV1917
- Tagalog TAG-ADB
- தமிழ் TCV
- తెలుగు TSA
- ภาษาไทย THAI-KJV
- Українська Ohienko
- Tiếng Việt CADMAN
- Yorùbá YCB
circa 800–400 BC
The Hebrew Prophets
God speaks through Isaiah, Jeremiah, and the minor prophets—calling Israel to repentance and foretelling the coming Messiah.
Àwọn ẹsẹ láti sáà yìí
- Mika 6:16nǹkan bí 710 ṣáájú Kristi
Nítorí tí ìwọ ti pa òfin Omri mọ́, àti gbogbo iṣẹ́ ilé Ahabu, tí ó sì ti tẹ̀lé ìmọ̀ràn wọn, nítorí náà ni èmi yóò ṣe mú ọ fún ìparun àti àwọn ènìyàn rẹ fún ìfiṣe ẹlẹ́yà; ìwọ yóò sì ru ẹ̀gàn àwọn ènìyàn mi.”
- Mika 7:1nǹkan bí 710 ṣáájú Kristi
Ègbé ni fún mi! Nítorí èmi sì dàbí ẹni tí ń kó èso ẹ̀ẹ̀rùn jọ, ìpèsè ọgbà àjàrà; kò sì ṣí odidi àjàrà kankan láti jẹ, kò sì ṣí àkọ́so ọ̀pọ̀tọ́ nítorí tí ebi ń pa mí.
- Mika 7:2nǹkan bí 710 ṣáájú Kristi
Àwọn olódodo sì ti kúrò ní ilẹ̀ náà, kò sì ṣí ẹnìkan tí ó ṣẹ́kù tí ó jọ olóòtítọ́; gbogbo wọn sì ń purọ́ ní dídúró nítorí ìtàjẹ̀ sílẹ̀, olúkúlùkù wọ́n sì ń fi àwọ̀n de arákùnrin rẹ̀.
- Mika 7:3nǹkan bí 710 ṣáájú Kristi
Ọwọ́ wọn méjèèjì ti múra tán láti ṣe búburú; àwọn alákòóso ń béèrè fún ẹ̀bùn, àwọn onídàájọ́ sì ń gba owó àbẹ̀tẹ́lẹ̀ alágbára sì ń pàṣẹ ohun tí wọ́n fẹ́, gbogbo wọn sì jùmọ̀ ń dìtẹ̀.
- Mika 7:4nǹkan bí 710 ṣáájú Kristi
Ẹni tí ó sàn jùlọ nínú wọn sì dàbí ẹ̀gún, ẹni tí ó jẹ́ olódodo jùlọ burú ju ẹ̀gún ọgbà lọ. Ọjọ́ àwọn olùṣọ́ rẹ̀ ti dé, àti ọjọ́ tí Ọlọ́run bẹ̀ ọ́ wò. Nísinsin yìí ní àkókò ìdààmú wọn.
- Mika 7:5nǹkan bí 710 ṣáájú Kristi
Ẹ má ṣe gba ọ̀rẹ́ kan gbọ́; ẹ má sì ṣe gbẹ́kẹ̀lé amọ̀nà kankan. Pa ìlẹ̀kùn ẹnu rẹ fún ẹni tí ó sùn ní oókan àyà rẹ.
- Mika 7:6nǹkan bí 710 ṣáájú Kristi
Nítorí tí ọmọkùnrin kò bọ̀wọ̀ fún baba rẹ̀, ọmọbìnrin sì dìde sí ìyá rẹ̀, aya ọmọ sí ìyá ọkọ rẹ̀, ọ̀tá olúkúlùkù ni àwọn ará ilé rẹ̀.
- Mika 7:7nǹkan bí 710 ṣáájú Kristi
Ṣùgbọ́n ní tèmi, èmi ní ìwòye ní ìrètí sí Olúwa, èmi dúró de Ọlọ́run olùgbàlà mi; Ọlọ́run mi yóò sì tẹ́tí sí mi.
- Mika 7:8nǹkan bí 710 ṣáájú Kristi
Má ṣe yọ̀ mí, ìwọ ọ̀tá mi. Bí mó bá ṣubú, èmi yóò dìde. Nígbà tí mo bá jókòó sínú òkùnkùn Olúwa yóò jẹ́ ìmọ́lẹ̀ fún mi.
- Mika 7:9nǹkan bí 710 ṣáájú Kristi
Nítorí èmi ti dẹ́ṣẹ̀ sí i, èmi yóò faradà ìbínú Olúwa, títí òun yóò ṣe gba ẹjọ́ mi rò, tí yóò sì ṣe ìdájọ́ mi. Òun yóò sì mú mi wá sínú ìmọ́lẹ̀; èmi yóò sì rí òdodo rẹ̀.
- Mika 7:10nǹkan bí 710 ṣáájú Kristi
Nígbà náà ni ọ̀tá mi yóò rí i ìtìjú yóò sì bo ẹni tí ó wí fún mi pé, “Níbo ni Olúwa Ọlọ́run rẹ wà?” Ojú mi yóò rí ìṣubú rẹ̀; nísinsin yìí ni yóò di ìtẹ̀mọ́lẹ̀ bí ẹrẹ̀ òpópó.
- Mika 7:11nǹkan bí 710 ṣáájú Kristi
Ọjọ́ tí a ó mọ odi rẹ yóò dé, ọjọ́ náà ni àṣẹ yóò jìnnà réré.
- Mika 7:12nǹkan bí 710 ṣáájú Kristi
Ní ọjọ́ náà àwọn ènìyàn yóò wá sọ́dọ̀ rẹ láti Asiria àti ìlú ńlá Ejibiti àní láti Ejibiti dé Eufurate láti Òkun dé Òkun àti láti òkè ńlá dé òkè ńlá.
- Mika 7:13nǹkan bí 710 ṣáájú Kristi
Ilẹ̀ náà yóò di ahoro fún àwọn olùgbé inú rẹ̀, nítorí èso ìwà wọn.
- Mika 7:14nǹkan bí 710 ṣáájú Kristi
Fi ọ̀pá rẹ bọ́ àwọn ènìyàn, agbo ẹran ìní rẹ, èyí tí ó ń dágbé nínú igbó ní àárín Karmeli. Jẹ́ kí wọn jẹun ní Baṣani àti Gileadi bí ọjọ́ ìgbàanì.
- Mika 7:15nǹkan bí 710 ṣáájú Kristi
“Bí i ọjọ́ tí ó jáde kúrò ní Ejibiti wá, ni èmi yóò fi ohun ìyanu hàn án.”
- Mika 7:16nǹkan bí 710 ṣáájú Kristi
Orílẹ̀-èdè yóò rí i, ojú yóò sì tì wọ́n, nínú gbogbo agbára wọn. Wọn yóò fi ọwọ́ lé ẹnu wọn, etí wọn yóò sì di.
- Mika 7:17nǹkan bí 710 ṣáájú Kristi
Wọn yóò lá erùpẹ̀ bí ejò, wọn yóò sì jáde kúrò nínú ihò wọn bí ekòló. Wọn yóò bẹ̀rù Olúwa Ọlọ́run wa, wọn yóò sì bẹ̀rù nítorí rẹ̀.
- Mika 7:18nǹkan bí 710 ṣáájú Kristi
Ta ni Ọlọ́run bí rẹ̀, ẹni tí ó dárí ẹ̀ṣẹ̀ jì, tí ó sì fojú fo ìrékọjá èyí tókù ìní rẹ̀? Kì í dúró nínú ìbínú rẹ̀ láéláé nítorí òun ní inú dídùn sí àánú.
- Mika 7:19nǹkan bí 710 ṣáájú Kristi
Òun yóò tún padà yọ́nú sí wa; òun yóò tẹ àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa mọ́lẹ̀, yóò sì fa gbogbo àìṣedéédéé wa sínú ibú Òkun.
- Mika 7:20nǹkan bí 710 ṣáájú Kristi
Ìwọ yóò fi òtítọ́ hàn sí Jakọbu ìwọ yóò sì fi àánú hàn sí Abrahamu, bí ìwọ ṣe búra fún àwọn baba wa láti ọjọ́ ìgbàanì.
- Nahumu 1:1nǹkan bí 713 ṣáájú Kristi
Ọ̀rọ̀-ìmọ̀ nípa Ninefe. Ìwé ìran Nahumu ará Elkoṣi.
- Nahumu 1:2nǹkan bí 713 ṣáájú Kristi
Ọlọ́run ń jẹ owú, ó sì ń gbẹ̀san, Olúwa ń gbẹ̀san, ó sì kún fún ìbínú. Olúwa ń gbẹ̀san lára àwọn ọ̀tá rẹ̀. Ìbínú rẹ̀ kò sì yí padà lórí àwọn ọ̀tá rẹ̀.
- Nahumu 1:3nǹkan bí 713 ṣáájú Kristi
Olúwa lọ́ra láti bínú, ó sì tóbi ní agbára; Olúwa kì yóò fi àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ sílẹ̀ láìjìyà. Ọ̀nà rẹ̀ wà nínú afẹ́fẹ́ àti nínú ìjì, ìkùùkuu sánmọ̀ sì ni eruku ẹsẹ̀ rẹ̀.
- Nahumu 1:4nǹkan bí 713 ṣáájú Kristi
Ó bá òkun wí, ó sì mú kí ó gbẹ; Ó sìsọ gbogbo odò di gbígbẹ. Baṣani àti Karmeli sì rọ. Ìtànná Lebanoni sì rẹ̀ sílẹ̀.