- English
- King James KJV
- Complete Jewish CJB
- World English WEBM
- Berean Standard BSB
- American Standard ASV
- Geneva GNV
- Young's Literal YLT
- Douay-Rheims DRC
- International
- Shqip ALB
- العربية SVD
- বাংলা BN-IRV
- မြန်မာ Judson
- 简体文 CUV-S
- 繁體中文 CUV-T
- Čeština BKR
- Nederlands STVE
- Français LSG
- Deutsch SCH
- Ελληνικά Vamvas
- ગુજરાતી GU-IRV
- Hausa HCB
- עברית Hebrew
- हिन्दी HCV
- Magyar KAROLI
- Bahasa Indonesia INDO-TB
- Italiano Diodati
- 日本語 Kougo
- 한국어 Korean
- മലയാളം MAL
- मराठी MRCV
- Norsk DNB
- فارسی OPV
- Polski BG
- Português Almeida
- Română Cornilescu
- Русский Synodal
- Español RVG
- Kiswahili Neno
- Svenska SV1917
- Tagalog TAG-ADB
- தமிழ் TCV
- తెలుగు TSA
- ภาษาไทย THAI-KJV
- Українська Ohienko
- Tiếng Việt CADMAN
- Yorùbá YCB
circa 800–400 BC
The Hebrew Prophets
God speaks through Isaiah, Jeremiah, and the minor prophets—calling Israel to repentance and foretelling the coming Messiah.
Àwọn ẹsẹ láti sáà yìí
- Amosi 5:16nǹkan bí 787 ṣáájú Kristi
Nítorí èyí ni ohun tí Olúwa, Olúwa Ọlọ́run àwọn ọmọ-ogun wí: “Ẹkún yóò wà ní àwọn òpópónà igbe ìnira yóò sì wà ní àwọn gbàgede ìlú. A ó kó àwọn àgbẹ̀ jọ láti sọkún àti àwọn tí ń ṣọ̀fọ̀ láti pohùnréré ẹkún.
- Amosi 5:17nǹkan bí 787 ṣáájú Kristi
Ìpohùnréré ẹkún yóò wà ní gbogbo ọgbà àjàrà, nítorí èmi yóò la àárín yín kọjá,” ni Olúwa wí.
- Amosi 5:18nǹkan bí 787 ṣáájú Kristi
Ègbé ni fún ìwọ tí ó pẹ́ nítorí ọjọ́ Olúwa kí ni ìwọ fi pẹ́ fún ọjọ́ Olúwa? Ìmọ́lẹ̀ yóò di òkùnkùn ní ojú ọjọ́.
- Amosi 5:19nǹkan bí 787 ṣáájú Kristi
Gẹ́gẹ́ bí ènìyàn tí ó sá fún kìnnìún, tí ó padà wá bọ́ sí ẹnu àmọ̀tẹ́kùn. Yóò dàbí ẹni tí ó wọ ilé rẹ̀ lọ tí ó sinmi lé ògiri ilé rẹ̀ tí ejò sì bù ú ṣán.
- Amosi 5:20nǹkan bí 787 ṣáájú Kristi
Ǹjẹ́ ọjọ́ Olúwa kò ha ní ṣókùnkùn dípò kí ó ní ìmọ́lẹ̀? Tí yóò sì ṣókùnkùn dúdú láìsí ìmọ́lẹ̀ kankan níbẹ̀.
- Amosi 5:21nǹkan bí 787 ṣáájú Kristi
“Mo kórìíra, mo kẹ́gàn àwọn àsè ẹ̀sìn in yín, Èmi kò sì ní inú dídùn sí àpéjọ yín.
- Amosi 5:22nǹkan bí 787 ṣáájú Kristi
Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹ mú ẹbọ sísun àti ọrẹ ọkà wá. Èmi kò ní tẹ́wọ́ gbà wọ́n. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹ mú àṣàyàn ọrẹ àlàáfíà wá. Èmi kò ní náání wọn.
- Amosi 5:23nǹkan bí 787 ṣáájú Kristi
Ẹ gbé ariwo orin yín sẹ́yìn! Èmi kò ní fetísí ohun èlò orin yín.
- Amosi 5:24nǹkan bí 787 ṣáájú Kristi
Jẹ́ kí òtítọ́ sàn bí odò àti òdodo bí ìsun tí kò lé è gbẹ!
- Amosi 5:25nǹkan bí 787 ṣáájú Kristi
“Àbí ẹ̀yin mú ẹbọ àti ọrẹ tọ̀ mí wá ní ogójì ọdún ní aginjù ìwọ ilé Israẹli?
- Amosi 5:26nǹkan bí 787 ṣáájú Kristi
Ẹ̀yin ti gbé ibi ìrúbọ àwọn ọba yín sókè, ibùgbé àwọn òrìṣà yín, àní, ti àwọn òrìṣà yín tí ó níyì jùlọ, èyí tí ẹ̀yin fi ọwọ́ ara yín ṣe.
- Amosi 5:27nǹkan bí 787 ṣáájú Kristi
Nítorí náà èmi yóò rán an yín lọ sí ìgbèkùn ní ìkọjá Damasku,” ni Olúwa wí, ẹni tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Ọlọ́run alágbára.
- Amosi 6:1nǹkan bí 787 ṣáájú Kristi
Ègbé ni fún ẹ̀yin tí ará rọ̀ ní Sioni àti ẹ̀yin tí ẹ wà ní abẹ́ ààbò ní òkè Samaria àti ẹ̀yin olókìkí orílẹ̀-èdè tí ẹ̀yin ènìyàn Israẹli máa ń tọ̀ ọ́ wá.
- Amosi 6:2nǹkan bí 787 ṣáájú Kristi
Ẹ lọ Kalne kí ẹ lọ wò ó kí ẹ sí tí ibẹ̀ lọ sí Hamati ìlú ńlá a nì. Kí ẹ sì tún sọ̀kalẹ̀ lọ Gati ní ilẹ̀ Filistini. Ǹjẹ́ wọ́n ha dára ju ìpínlẹ̀ yín méjèèjì lọ? Ǹjẹ́ a ha rí ilẹ̀ tó tóbi ju tiyín lọ bí?
- Amosi 6:3nǹkan bí 787 ṣáájú Kristi
Ẹ̀yin sún ọjọ́ ibi síwájú, ẹ sì mú ìjọba òǹrorò súnmọ́ tòsí.
- Amosi 6:4nǹkan bí 787 ṣáájú Kristi
Ẹ̀yin sùn lé ibùsùn tí a fi eyín erin ṣe ẹ sì tẹ́ ara sílẹ̀ ni orí àwọn ibùsùn ẹyin pa èyí tí o dára nínú àwọn ọ̀dọ́-àgùntàn yín jẹ ẹ sì ń pa àwọn ọ̀dọ́ màlúù láàrín agbo wọn jẹ.
- Amosi 6:5nǹkan bí 787 ṣáájú Kristi
Ẹ̀yin ń lo ohun èlò orin bí i Dafidi ẹ sì ń ṣe àwọn àpilẹ̀rọ àwọn ohun èlò orin.
- Amosi 6:6nǹkan bí 787 ṣáájú Kristi
Ẹ̀yin mu wáìnì ẹ̀kún ọpọ́n kan àti ìkunra tí o dára jùlọ ṣùgbọ́n ẹ̀yin kò káàánú ilé Josẹfu tí ó di ahoro.
- Amosi 6:7nǹkan bí 787 ṣáájú Kristi
Nítorí náà, àwọn ni yóò lọ sí ìgbèkùn pẹ̀lú àwọn tí ó ti kó lọ sí ìgbèkùn àsè àwọn tí ń ṣe àṣelékè ni a ó mú kúrò.
- Amosi 6:8nǹkan bí 787 ṣáájú Kristi
Olúwa Olódùmarè ti búra fúnra rẹ̀, Olúwa Ọlọ́run àwọn ọmọ-ogun sì ti wí pé: “Mo kórìíra ìgbéraga Jakọbu n kò sì ní inú dídùn sí odi alágbára rẹ̀, Èmi yóò sì fa ìlú náà lé wọn lọ́wọ́ àti ohun gbogbo tí ó wà nínú rẹ̀.”
- Amosi 6:9nǹkan bí 787 ṣáájú Kristi
Bí ọkùnrin mẹ́wàá bá ṣẹ́kù nínú ilé kan, àwọn náà yóò kú.
- Amosi 6:10nǹkan bí 787 ṣáájú Kristi
Bí ẹbí tí ó yẹ kí ó gbé òkú wọn jáde fún sínsin bá wọlé, bí o ba sì béèrè pé ǹjẹ́ ẹnìkan wa tí ó fi ara pamọ́ níbẹ̀, “Ǹjẹ́ ẹnìkankan wà lọ́dọ̀ yín?” tí ó bá sì dáhùn wí pé, “Rárá,” nígbà náà ni yóò wí pé, “Pa ẹnu rẹ mọ́ àwa kò gbọdọ̀ dárúkọ Olúwa.”
- Amosi 6:11nǹkan bí 787 ṣáájú Kristi
Nítorí Olúwa tí pa àṣẹ náà, Òun yóò sì wó ilé ńlá náà lulẹ̀ túútúú, àti àwọn ilé kéékèèké sí wẹ́wẹ́.
- Amosi 6:12nǹkan bí 787 ṣáájú Kristi
Ǹjẹ́ ẹṣin a máa sáré lórí àpáta bí? Ǹjẹ́ ènìyàn a máa fi akọ màlúù kọ ilẹ̀ níbẹ̀? Ṣùgbọ́n ẹ̀yin ti yí òtítọ́ padà sí májèlé ẹ sì ti sọ èso òdodo di ìkorò.
- Amosi 6:13nǹkan bí 787 ṣáájú Kristi
Ẹ̀yin yọ̀ torí ìṣẹ́gun lórí Lo-Debari, ẹ̀yin sì wí pé, “Ṣé kì í ṣe agbára wa ni àwa fi gba Karnaimu?”