Fò sí àkóónú

circa 800–400 BC

The Hebrew Prophets

God speaks through Isaiah, Jeremiah, and the minor prophets—calling Israel to repentance and foretelling the coming Messiah.

3,706 ẹsẹ · 14 ìwé tí a bo

Àwọn ẹsẹ láti sáà yìí

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Amosi 8:8nǹkan bí 787 ṣáájú Kristi

    “Ǹjẹ́ ilẹ̀ náà kì yóò ha wárìrì fún èyí? Àwọn tí ń gbé inú rẹ̀ kì yóò ha ṣọ̀fọ̀? Gbogbo ilẹ̀ yóò ru sókè bí omi Naili, yóò sì ru ú sókè pátápátá bí ìkún omi a ó sì tì í jáde, a ó sì tẹ̀ ẹ́ rì gẹ́gẹ́ bí odò Ejibiti.

  2. Amosi 8:9nǹkan bí 787 ṣáájú Kristi

    “Yóò sì ṣe ní ọjọ́ náà,” ni Olúwa Olódùmarè wí, “Èmi yóò mú oòrùn wọ̀ ní ọ̀sán, Èmi yóò mú kí ayé ṣókùnkùn ní ọ̀sán gangan.

  3. Amosi 8:10nǹkan bí 787 ṣáájú Kristi

    Èmí yóò yí àsè ẹ̀sìn yín padà sí ọ̀fọ̀, gbogbo orin yín ni èmi yóò sọ di ẹkún. Èmi yóò mú kí gbogbo yín wọ aṣọ ọ̀fọ̀, kí a sì fá orí yín. Èmi yóò mú kí ìgbà náà rí bí ìṣọ̀fọ̀ fún ọmọkùnrin kan ṣoṣo tí a bí àti òpin rẹ̀ bí ọjọ́ kíkorò.

  4. Amosi 8:11nǹkan bí 787 ṣáájú Kristi

    “Ọjọ́ ń bọ̀,” ni Olúwa Olódùmarè wí, “nígbà tí èmi yóò rán ìyàn sí ilẹ̀ náà, kì í ṣe ìyàn oúnjẹ tàbí òǹgbẹ fún omi. Ṣùgbọ́n ìyàn gbígbọ́ ọ̀rọ̀ Olúwa.

  5. Amosi 8:12nǹkan bí 787 ṣáájú Kristi

    Àwọn ènìyàn yóò rìn kiri láti Òkun dé Òkun wọn yóò sì máa rìn ká láti gúúsù sí àríwá, wọn yóò máa wá ọ̀rọ̀ Olúwa ṣùgbọ́n wọn kì yóò rí i.

  6. Amosi 8:13nǹkan bí 787 ṣáájú Kristi

    “Ní ọjọ́ náà “àwọn arẹwà wúńdíá àti àwọn alágbára ọ̀dọ́mọkùnrin yóò dákú fún òǹgbẹ omi.

  7. Amosi 8:14nǹkan bí 787 ṣáájú Kristi

    Àwọn tí ó fi ẹ̀ṣẹ̀ Samaria búra, tí wọ́n sì wí pé, ‘Bí ó ti dájú pé ọlọ́run rẹ ń bẹ láààyè, ìwọ Dani,’ bí ó ti dájú pè ọlọ́run rẹ ń bẹ láààyè, ìwọ Beerṣeba, wọ́n yóò ṣubú, wọn kì yóò si tún dìde mọ.”

  8. Amosi 9:1nǹkan bí 787 ṣáájú Kristi

    Mo rí Olúwa, ó dúró ní ẹ̀bá pẹpẹ, ó sì wí pé: “Lu orí àwọn àtẹ́rígbà ìlẹ̀kùn kí àwọn òpó kí ó lè mì fọ́ wọn sí orí àwọn gbogbo ènìyàn àwọn tí ó ṣẹ́kù ni èmi yóò fi idà pa, ẹni tí ó sálọ nínú wọn kí yóò sá gbé, ẹni ti ó sá àsálà nínú wọn kí yóò gbàlà.

  9. Amosi 9:2nǹkan bí 787 ṣáájú Kristi

    Bí wọ́n tilẹ̀ wa ilẹ̀ lọ sí ipò òkú, láti ibẹ̀ ni ọwọ́ mi yóò ti tẹ̀ wọ́n. Bí wọ́n tilẹ̀ gun òkè ọ̀run lọ, láti ibẹ̀ ni èmi yóò ti mú wọn sọ̀kalẹ̀.

  10. Amosi 9:3nǹkan bí 787 ṣáájú Kristi

    Bí wọ́n tilẹ̀ fi ara wọn pamọ́ ni orí òkè Karmeli, èmi yóò wá wọn rí, Èmi yóò si mú wọn kúrò níbẹ̀. Bí wọ́n tilẹ̀ fi ara pamọ́ fún mi sí ìsàlẹ̀ Òkun, láti ibẹ̀ ni Èmi yóò ti pàṣẹ fún ejò kí ó bù wọ́n ṣán.

  11. Amosi 9:4nǹkan bí 787 ṣáájú Kristi

    Bí wọ́n tilẹ̀ lọ sí ìgbèkùn ní iwájú àwọn ọ̀tá wọn láti ibẹ̀ ni èmi yóò ti pàṣẹ fún idà kí ó ṣá wọn pa. “Èmi yóò sì tẹ ojú mi mọ́ wọn fún ìbí, kì í sì í ṣe fún rere.”

  12. Amosi 9:5nǹkan bí 787 ṣáájú Kristi

    Olúwa, Olúwa àwọn ọmọ-ogun, ẹni ti ó fi ọwọ́ kan ilẹ̀ náà tí ó sì yọ́, tí àwọn olùgbé inú rẹ̀ yóò sì ṣọ̀fọ̀; gbogbo orílẹ̀-èdè yóò si ru sókè bí ríru odò Naili tiwọn yóò sì tẹ̀rì bí odò Ejibiti.

  13. Amosi 9:6nǹkan bí 787 ṣáájú Kristi

    Òun ni ẹni tí ó kọ́ ìtẹ́ rẹ̀ nínú àwọn ọ̀run ti ó sì fi ìpìlẹ̀ rẹ̀ sọlẹ̀ ní ilé ayé, Ẹni ti ó pe àwọn omi Òkun ti ó sì tú wọn jáde si orí ilé ayé Olúwa ni orúkọ rẹ̀.

  14. Amosi 9:7nǹkan bí 787 ṣáájú Kristi

    “Àbá ẹ̀yin ọmọ Israẹli kò ha dàbí àwọn ọmọ Kuṣi sí mi?” ni Olúwa wí. “Èmi kò ha ti mú Israẹli gòkè láti ilẹ̀ Ejibiti jáde wá àti àwọn Filistini láti ilẹ̀ Kafitori àti àwọn ará Aramu láti Kiri?

  15. Amosi 9:8nǹkan bí 787 ṣáájú Kristi

    “Dájúdájú, ojú Olúwa Olódùmarè ń bẹ̀ lára ilẹ̀ ọba tó kún fún ẹ̀ṣẹ̀. Èmi yóò pa á run kúrò lórí ilẹ̀. Síbẹ̀, Èmi kò nípa ilé Jakọbu run pátápátá,” ni Olúwa wí.

  16. Amosi 9:9nǹkan bí 787 ṣáájú Kristi

    “Nítorí Èmi yóò pàṣẹ, Èmi yóò sì mi ilé Israẹli ní àárín àwọn orílẹ̀-èdè bí a ti ń jọ nǹkan nínú ajọ̀ tí hóró kín ń kín kì yóò bọ́ sórí ilẹ̀.

  17. Amosi 9:10nǹkan bí 787 ṣáájú Kristi

    Gbogbo àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ láàrín àwọn ènìyàn mi ni yóò ti ipa idà kú gbogbo àwọn ti ń wí pé, ‘Aburú kì yóò lé wa bá, bẹ́ẹ̀ ni kì yóò ká wa mọ́.’

  18. Amosi 9:11nǹkan bí 787 ṣáájú Kristi

    “Ní ọjọ́ náà ní Èmi yóò gbé àgọ́ Dafidi tí ó wó ró, Èmi yóò dí odi rẹ̀ tí ó ya, Èmi yóò sì gbé ahoro rẹ̀ sókè, Èmi yóò sì kọ bí ti ọjọ́ ìgbàanì,

  19. Amosi 9:12nǹkan bí 787 ṣáájú Kristi

    kí wọn le jogún ìyókù Edomu àti gbogbo àwọn kèfèrí, ti a ń pè nípa orúkọ mi,” ni Olúwa, ẹni tí yóò ṣe nǹkan wọ̀nyí wí.

  20. Amosi 9:13nǹkan bí 787 ṣáájú Kristi

    “Ọjọ́ náà ń bọ,” ni Olúwa wí, “tí ẹni tí ń tulẹ̀ yóò lé ẹni tí ń kórè bá. Tí ẹni tí ń fún èso àjàrà yóò lé ẹni tí ń gbìn bá. Àwọn òkè ńlá yóò sì kán ọtí wáìnì sílẹ̀, tí yóò sì sàn láti ara àwọn òkè kéékèèké.

  21. Amosi 9:14nǹkan bí 787 ṣáájú Kristi

    Èmi yóò si tún mú ìgbèkùn Israẹli ènìyàn mi padà bọ̀. “Wọn yóò sì kọ́ ahoro ìlú, wọn yóò sì máa gbé inú wọn. Wọn yóò sì gbin ọgbà àjàrà, wọn yóò sì mu ọtí wáìnì wọn wọn yóò sì ṣe ọgbà pẹ̀lú, wọn yóò sì jẹ èso inú wọn.

  22. Amosi 9:15nǹkan bí 787 ṣáájú Kristi

    Èmi yóò gbin Israẹli sí orí ilẹ̀ rẹ̀. A kì yóò sì fà wọn tu mọ́ láéláé kúrò ni orí ilẹ̀ ti mo fi fún wọn,” ni Olúwa Ọlọ́run rẹ wí.

  23. Obadiah 1:1nǹkan bí 587 ṣáájú Kristi

    Ìran ti Obadiah. Èyí ni Olúwa Olódùmarè wí nípa Edomu. Àwa ti gbọ́ ohùn kan láti ọ̀dọ̀ Olúwa wá, a sì ti rán ikọ̀ kan sí gbogbo kèfèrí láti sọ pé, “Ẹ dìde, ẹ jẹ́ kí a dìde ogun sí i.”

  24. Obadiah 1:2nǹkan bí 587 ṣáájú Kristi

    “Kíyèsi i, Èmi yóò sọ ọ́ di kékeré láàrín àwọn kèfèrí; ìwọ yóò sì di gígàn lọ́pọ̀lọ́pọ̀.

  25. Obadiah 1:3nǹkan bí 587 ṣáájú Kristi

    Ìgbéraga àyà rẹ ti tàn ọ́ jẹ, ìwọ tí ń gbé inú pálapàla àpáta, tí o sì kọ́ ibùgbé rẹ sí ibi gíga, ìwọ wí nínú ọkàn rẹ pé, ‘Ta ni yóò mú mi sọ̀kalẹ̀?’