- English
- King James KJV
- Complete Jewish CJB
- World English WEBM
- Berean Standard BSB
- American Standard ASV
- Geneva GNV
- Young's Literal YLT
- Douay-Rheims DRC
- International
- Shqip ALB
- العربية SVD
- বাংলা BN-IRV
- မြန်မာ Judson
- 简体文 CUV-S
- 繁體中文 CUV-T
- Čeština BKR
- Nederlands STVE
- Français LSG
- Deutsch SCH
- Ελληνικά Vamvas
- ગુજરાતી GU-IRV
- Hausa HCB
- עברית Hebrew
- हिन्दी HCV
- Magyar KAROLI
- Bahasa Indonesia INDO-TB
- Italiano Diodati
- 日本語 Kougo
- 한국어 Korean
- മലയാളം MAL
- मराठी MRCV
- Norsk DNB
- فارسی OPV
- Polski BG
- Português Almeida
- Română Cornilescu
- Русский Synodal
- Español RVG
- Kiswahili Neno
- Svenska SV1917
- Tagalog TAG-ADB
- தமிழ் TCV
- తెలుగు TSA
- ภาษาไทย THAI-KJV
- Українська Ohienko
- Tiếng Việt CADMAN
- Yorùbá YCB
circa 800–400 BC
The Hebrew Prophets
God speaks through Isaiah, Jeremiah, and the minor prophets—calling Israel to repentance and foretelling the coming Messiah.
Àwọn ẹsẹ láti sáà yìí
- Amosi 4:4nǹkan bí 787 ṣáájú Kristi
“Ẹ lọ sí Beteli láti dẹ́ṣẹ̀; ẹ lọ sí Gilgali kí ẹ sì dẹ́ṣẹ̀ sí i. Ẹ mú ẹbọ sísun yín láràárọ̀ wá, ìdámẹ́wàá yín ní ọdọọdún mẹ́ta.
- Amosi 4:5nǹkan bí 787 ṣáájú Kristi
Kí ẹ mú ọ̀rẹ́ ìdúpẹ́ ìyẹ̀fun ìwúkàrà ti a sun kí ẹ sì mú ọrẹ àtinúwá lọ fi wọ́n yangàn, ẹ̀yin ènìyàn Israẹli, nítorí èyí ni ẹ fẹ́ láti ṣe,” ni Olúwa Olódùmarè wí.
- Amosi 4:6nǹkan bí 787 ṣáájú Kristi
“Èmi fún un yín ní mímọ́ eyín ní gbogbo ìlú yín, àti àìní oúnjẹ ní gbogbo ibùgbé yín, síbẹ̀, ẹ̀yin kò yípadà sọ́dọ̀ mi,” ni Olúwa wí.
- Amosi 4:7nǹkan bí 787 ṣáájú Kristi
“Àti pẹ̀lú mo mú òjò dúró nígbà tí ìkórè ku oṣù mẹ́ta. Mo rán òjò sí ibùgbé kan ṣùgbọ́n kò rọ̀ sí ìlú mìíràn. Oko kan ní òjò; àwọn mìíràn kò ní ó sì gbẹ.
- Amosi 4:8nǹkan bí 787 ṣáájú Kristi
Àwọn ènìyàn ń rìn láti ìlú kan sí ìlú mìíràn fún omi wọn kò rí mu tẹ́ wọn lọ́rùn, síbẹ̀ ẹ̀yin kò padà sí ọ̀dọ̀ mi,” ni Olúwa wí.
- Amosi 4:9nǹkan bí 787 ṣáájú Kristi
“Lọ́pọ̀ ìgbà ni mo kọlu ọgbà àti ọgbà àjàrà yín mo fi ìrẹ̀dànù àti ìmúwòdù lù wọ́n. Eṣú sì jẹ igi ọ̀pọ̀tọ́ àti igi olifi yín, síbẹ̀ ẹ̀yin kò yípadà sí mi,” ni Olúwa wí.
- Amosi 4:10nǹkan bí 787 ṣáájú Kristi
“Mo rán àjàkálẹ̀-ààrùn sí i yín bí mo ti ṣe sí Ejibiti. Mo fi idà pa àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin yín. Pẹ̀lú àwọn ẹṣin tí a kó ní ìgbèkùn. Mo kún imú yín fún òórùn ibùdó yín, síbẹ̀ ẹ̀yin kò yípadà sí mi,” ni Olúwa wí.
- Amosi 4:11nǹkan bí 787 ṣáájú Kristi
“Mo ti bì ṣubú nínú yín, bí Ọlọ́run ti bi Sodomu àti Gomorra ṣubú ẹ̀yin sì dàbí ògúnná tí a fa yọ kúrò nínú iná, síbẹ̀ ẹ̀yin kò yípadà sí mi,” ni Olúwa wí.
- Amosi 4:12nǹkan bí 787 ṣáájú Kristi
“Nítorí náà, èyí ni ohun tí èmi yóò ṣe sí i yín, Israẹli, àti nítorí tí èmi ó ṣe èyí sí i yín, ẹ múra láti pàdé Ọlọ́run yín, ẹ̀yin Israẹli.”
- Amosi 4:13nǹkan bí 787 ṣáájú Kristi
Ẹni tí ó dá àwọn òkè tí ó dá afẹ́fẹ́ tí ó sì fi èrò rẹ̀ hàn sí ènìyàn, ẹni tí ó yípadà sí òkùnkùn tí ó sì tẹ ibi gíga ayé. Olúwa Ọlọ́run àwọn ọmọ-ogun ni orúkọ rẹ̀.
- Amosi 5:1nǹkan bí 787 ṣáájú Kristi
Gbọ́ ọ̀rọ̀ yìí, ìwọ ilé Israẹli, ìpohùnréré ẹkún tí mo ṣe nípa rẹ:
- Amosi 5:2nǹkan bí 787 ṣáájú Kristi
“Wúńdíá Israẹli ṣubú láì kò sì le padà dìde ó di ẹni ìkọ̀tì ní ilẹ̀ rẹ̀ kò sí ẹni tí yóò gbé e dìde.”
- Amosi 5:3nǹkan bí 787 ṣáájú Kristi
Èyí ni ohun tí Olúwa Olódùmarè wí: “Ìlú tí ẹgbẹ̀rún (1,000) alágbára ti jáde, yóò dín ku ọgọ́rùn-ún ní Israẹli. Ìlú tí ọgọ́rùn-ún alàgbà ti jáde yóò ṣẹ́kù ẹni mẹ́wàá.”
- Amosi 5:4nǹkan bí 787 ṣáájú Kristi
Èyí ni ohun tí Olúwa sọ fún ilé Israẹli: “Wá mi kí o sì yè;
- Amosi 5:5nǹkan bí 787 ṣáájú Kristi
ẹ má ṣe wá Beteli, ẹ má ṣe lọ sí Gilgali, ẹ má ṣe rìnrìn àjò lọ sí Beerṣeba. Nítorí dájúdájú a ó kó Gilgali ní ìgbèkùn, A ó sì sọ Beteli di asán.”
- Amosi 5:6nǹkan bí 787 ṣáájú Kristi
Ẹ wá Olúwa, ẹ̀yin yóò sì yè, kí ó má ba à gbilẹ̀ bí iná ní Josẹfu a sì jó o run Beteli kò sì ní rí ẹni tí yóò bu omi pa á.
- Amosi 5:7nǹkan bí 787 ṣáájú Kristi
Ẹ̀yin tí ẹ̀ sọ òdodo di ìkorò tí ẹ sì gbé olódodo ṣánlẹ̀.
- Amosi 5:8nǹkan bí 787 ṣáájú Kristi
Ẹni tí ó dá ìràwọ̀ Pleiadesi àti Orioni ẹni tí ó sọ òru dúdú di òwúrọ̀ tí ó sọ ọjọ́ dúdú di ìmọ́lẹ̀ ẹni tí ó wọ́ omi Òkun jọ pọ̀ tí ó sì rọ̀ wọ́n sí orí ilẹ̀ Olúwa ni orúkọ rẹ̀,
- Amosi 5:9nǹkan bí 787 ṣáájú Kristi
Ó fọ́n ìparun sí ìlú olódi tí ó sì sọ àwọn ibùgbé àwọn ọmọ-aládé di ahoro.
- Amosi 5:10nǹkan bí 787 ṣáájú Kristi
Ìwọ kórìíra ẹni tí ń bá ni wí ní ẹnu ibodè ó sì ń pẹ̀gàn ẹni tí ń sọ òtítọ́.
- Amosi 5:11nǹkan bí 787 ṣáájú Kristi
Ìwọ ń tẹ tálákà mọ́lẹ̀ o ń fi ipá gba ọkà lọ́wọ́ wọn. Nítorí náà, ìwọ ti fi òkúta tí a gbẹ́ kọ́lé ṣùgbọ́n ẹ kò sì ní gbé inú wọn, Nítòótọ́ ìwọ ti gbin ọgbà àjàrà tí ó lẹ́wà. Ìwọ kò ní mu wáìnì inú wọn.
- Amosi 5:12nǹkan bí 787 ṣáájú Kristi
Nítorí mo mọ iye àìṣedéédéé rẹ mo sì mọ bí ẹ̀ṣẹ̀ rẹ tí tóbi tó. Ìwọ ni olódodo lára, ìwọ sì ń gba àbẹ̀tẹ́lẹ̀ o sì ń fi òtítọ́ du tálákà ní ilé ẹjọ́.
- Amosi 5:13nǹkan bí 787 ṣáájú Kristi
Àwọn ọlọ́gbọ́n máa ń dákẹ́ jẹ́ẹ́ ní àkókò wọ̀nyí, nítorí búburú ni gbogbo ọjọ́.
- Amosi 5:14nǹkan bí 787 ṣáájú Kristi
Wá rere, má ṣe wá búburú kí ìwọ ba à le yè. Nígbà náà ni Olúwa Ọlọ́run àwọn ọmọ-ogun yóò wà pẹ̀lú rẹ. Òun yóò sì wà pẹ̀lú rẹ bí ìwọ ṣe wí.
- Amosi 5:15nǹkan bí 787 ṣáájú Kristi
Kórìíra búburú kí o sì fẹ́ rere dúró ní orí òtítọ́ ní ilé ẹjọ́ bóyá Olúwa Ọlọ́run alágbára yóò síjú àánú wo ọmọ Josẹfu tó ṣẹ́kù.