- English
- King James KJV
- Complete Jewish CJB
- World English WEBM
- Berean Standard BSB
- American Standard ASV
- Geneva GNV
- Young's Literal YLT
- Douay-Rheims DRC
- International
- Shqip ALB
- العربية SVD
- বাংলা BN-IRV
- မြန်မာ Judson
- 简体文 CUV-S
- 繁體中文 CUV-T
- Čeština BKR
- Nederlands STVE
- Français LSG
- Deutsch SCH
- Ελληνικά Vamvas
- ગુજરાતી GU-IRV
- Hausa HCB
- עברית Hebrew
- हिन्दी HCV
- Magyar KAROLI
- Bahasa Indonesia INDO-TB
- Italiano Diodati
- 日本語 Kougo
- 한국어 Korean
- മലയാളം MAL
- मराठी MRCV
- Norsk DNB
- فارسی OPV
- Polski BG
- Português Almeida
- Română Cornilescu
- Русский Synodal
- Español RVG
- Kiswahili Neno
- Svenska SV1917
- Tagalog TAG-ADB
- தமிழ் TCV
- తెలుగు TSA
- ภาษาไทย THAI-KJV
- Українська Ohienko
- Tiếng Việt CADMAN
- Yorùbá YCB
circa AD 48–96
Letters to the Churches
Paul and other apostles write to strengthen, correct, and encourage the scattered churches across the Roman world.
Àwọn ẹsẹ láti sáà yìí
- 1 Kọrinti 11:6nǹkan bí 59 lẹ́yìn Kristi
Ṣùgbọ́n tí obìnrin bá kọ̀ láti bo orí rẹ̀, ẹ jẹ́ kí ó gé irun rẹ̀. Bí ó bá sì jẹ́ nǹkan ìtìjú fún un láti gé irun orí rẹ́, nígbà náà kí ó fi gèlè bo orí rẹ̀.
- 1 Kọrinti 11:7nǹkan bí 59 lẹ́yìn Kristi
Ṣùgbọ́n ọkùnrin kò ní láti fi nǹkan bo orí rẹ́ nígbà tí ó bá ń sìn, nítorí àwòrán àti ògo Ọlọ́run ni òun í ṣe, ṣùgbọ́n ògo ọkùnrin ni obìnrin í ṣe.
- 1 Kọrinti 11:8nǹkan bí 59 lẹ́yìn Kristi
Ọkùnrin kò ti inú obìnrin wá, ṣùgbọ́n a yọ obìnrin jáde lára ọkùnrin,
- 1 Kọrinti 11:9nǹkan bí 59 lẹ́yìn Kristi
bẹ́ẹ̀ ni a kò dá ọkùnrin fún àǹfààní obìnrin ṣùgbọ́n a da obìnrin fún ọkùnrin.
- 1 Kọrinti 11:10nǹkan bí 59 lẹ́yìn Kristi
Nítorí ìdí èyí àti nítorí àwọn angẹli, ni obìnrin ṣe gbọdọ̀ ní àmì àṣẹ rẹ̀ ní orí rẹ̀.
- 1 Kọrinti 11:11nǹkan bí 59 lẹ́yìn Kristi
Ẹ rántí pé, nínú ètò Ọlọ́run obìnrin kò lè wà láìsí ọkùnrin, bẹ́ẹ̀ ni ọkùnrin kò lè wà láàsí obìnrin.
- 1 Kọrinti 11:12nǹkan bí 59 lẹ́yìn Kristi
Lóòtítọ́ láti ara ọkùnrin ni a ti yọ obìnrin jáde bẹ́ẹ̀ sì ni ọkùnrin tipasẹ̀ obìnrin wa. Ṣùgbọ́n láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run ni ohun gbogbo ti wà.
- 1 Kọrinti 11:13nǹkan bí 59 lẹ́yìn Kristi
Kí ni ẹ̀yìn fúnra yín rò lórí ọ̀rọ̀ yìí? Ǹjẹ́ ó tọ̀nà fún obìnrin láti máa gbàdúrà Ọlọ́run ní gbangba láìbo orí rẹ̀ bí?
- 1 Kọrinti 11:14nǹkan bí 59 lẹ́yìn Kristi
Ǹjẹ́ ìwà abínibí yín kò ha kọ́ yín pé, bí ọkùnrin bá ní irun gígùn, àbùkù ni ó jẹ́ fún un.
- 1 Kọrinti 11:15nǹkan bí 59 lẹ́yìn Kristi
Ṣùgbọ́n bí obìnrin bá ní irun gígùn, ògo ni ó jẹ́ fún un nítorí irun gígùn tí a fi fún un jẹ́ ìbòrí fún un.
- 1 Kọrinti 11:16nǹkan bí 59 lẹ́yìn Kristi
Ṣùgbọ́n tí ẹnikẹ́ni bá fẹ́ jiyàn lórí ọ̀rọ̀ yìí, ohun kan tí mo lè sọ sí gbogbo rẹ̀ ni pé, a kò ní ìlànà tí ó yàtọ̀ sí èyí tí mo ti sọ, pé obìnrin gbọdọ̀ fi gèlè bo orí rẹ̀ nígbà tí ó bá ń sọtẹ́lẹ̀ tàbí tí ó bá ń gbàdúrà láàrín ìjọ Ọlọ́run.
- 1 Kọrinti 11:17nǹkan bí 59 lẹ́yìn Kristi
Nínú àwọn àlàkalẹ̀ èmi ko ni yìn yín nítorí pé bí ẹ bá péjọ kì í ṣe fún rere bí ko ṣe fún búburú.
- 1 Kọrinti 11:18nǹkan bí 59 lẹ́yìn Kristi
Lọ́nà kìn-ín-ní, mo gbọ́ pe ìyapa máa ń wà láàrín yín ní ìgbà tí ẹ bá péjọpọ̀ gẹ́gẹ́ bí ìjọ, mo sì gba èyí gbọ́ dé ààyè ibìkan.
- 1 Kọrinti 11:19nǹkan bí 59 lẹ́yìn Kristi
Kò sí àní àní, ìyàtọ̀ gbọdọ̀ wa láàrín yín, kí àwọn tí ó ṣe ìtẹ́wọ́gbà lọ́dọ̀ Ọlọ́run láàrín yín le farahàn kedere.
- 1 Kọrinti 11:20nǹkan bí 59 lẹ́yìn Kristi
Nígbà tí ẹ bá pàdé láti jẹun, kì í ṣe oúnjẹ alẹ́ Olúwa ni ẹ máa ń jẹ.
- 1 Kọrinti 11:21nǹkan bí 59 lẹ́yìn Kristi
Ṣùgbọ́n tí ara yín, nígbà tí ẹ bá fẹ́ jẹun, olúkúlùkù yín a máa sáré jẹ oúnjẹ rẹ̀ láìdúró de ẹnìkejì rẹ̀. Ebi a sì máa pa wọ́n, ẹlòmíràn wọ́n sì ń mu àmuyó àti àmupara.
- 1 Kọrinti 11:22nǹkan bí 59 lẹ́yìn Kristi
Ṣé ẹ̀yin kò ní ilé tí ẹ ti lè jẹ, tí ẹ sì ti lè mu ni? Tàbí ẹ̀yin ń gan ìjọ Ọlọ́run ni? Ẹ̀yin sì ń dójútì àwọn aláìní? Kín ni kí èmi ó wí fún un yín? Èmi yóò ha yìn yín nítorí èyí? A! Rárá o. Èmi kọ́, n kò ní yìn yín.
- 1 Kọrinti 11:23nǹkan bí 59 lẹ́yìn Kristi
Nítorí èyí tí èmi gbà lọ́wọ́ Olúwa ni mo ti fi fún un yin. Ní alẹ́ ọjọ́ tí Judasi fihàn, Olúwa Jesu Kristi mú àkàrà.
- 1 Kọrinti 11:24nǹkan bí 59 lẹ́yìn Kristi
Lẹ́yìn ìgbà tí ó ti dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run fún àkàrà náà tan, ó bù ú, ó fi fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀, ó sì wí pé, “Ẹ gbà kí ẹ sì jẹ, èyí ní ara mi tí a fi fún un yín. Ẹ máa ṣe eléyìí ni rántí mi.”
- 1 Kọrinti 11:25nǹkan bí 59 lẹ́yìn Kristi
Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ lẹ́yìn oúnjẹ alẹ́, ó sì mú ago wáìnì, ó sì wí pé, “Ago yìí ni májẹ̀mú tuntun nínú ẹ̀jẹ̀ mi, ẹ máa ṣe èyí, nígbàkígbà ti ẹ̀yìn bá ń mu ú, ní ìrántí mi.”
- 1 Kọrinti 11:26nǹkan bí 59 lẹ́yìn Kristi
Nítorí nígbàkígbà tí ẹ bá ń jẹ lára àkàrà yìí, tí ẹ sì ǹ mu nínú ago yìí, ni ẹ tún sọ nípa ikú Olúwa. Ẹ máa ṣe eléyìí títí yóò fi padà dé.
- 1 Kọrinti 11:27nǹkan bí 59 lẹ́yìn Kristi
Nítorí náà tí ẹnikẹ́ni bá jẹ lára àkàrà yìí, tí ẹ sì ń mu nínú ago Olúwa yìí, ní ọ̀nà tí kò bójúmu, yóò jẹ̀bi ẹ̀ṣẹ̀ sí ara àti ẹ̀jẹ̀ Olúwa.
- 1 Kọrinti 11:28nǹkan bí 59 lẹ́yìn Kristi
Ìdí nìyìí tí ó fi yẹ kí ènìyàn yẹ ara rẹ̀ wò dáradára kí ó tó jẹ lára àkàrà nà án àti kí ó tó mu nínú ago náà.
- 1 Kọrinti 11:29nǹkan bí 59 lẹ́yìn Kristi
Nítorí tí ẹ bá jẹ lára àkàrà, tí ẹ sì mu nínú ago láìyẹ, tí ẹ kò ronú ara Kristi àti nǹkan tí ó túmọ̀ sí, ẹ̀ ń jẹ, ẹ sì ń mú ẹ̀bi ìdájọ́ Ọlọ́run wá sórí ara yín.
- 1 Kọrinti 11:30nǹkan bí 59 lẹ́yìn Kristi
Ìdí nìyìí tí ọ̀pọ̀ yín fi di ẹni tí kò lágbára mọ́, tí ọ̀pọ̀ yín sì ń ṣàìsàn, àwọn mìíràn nínú yín tilẹ̀ ti sùn.