Fò sí àkóónú

circa AD 48–96

Letters to the Churches

Paul and other apostles write to strengthen, correct, and encourage the scattered churches across the Roman world.

2,767 ẹsẹ · 21 ìwé tí a bo

Àwọn ẹsẹ láti sáà yìí

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Romu 16:20nǹkan bí 60 lẹ́yìn Kristi

    Ọlọ́run àlàáfíà yóò sì tẹ Satani mọ́lẹ̀ ní àtẹ́lẹsẹ̀ yín ní lọ́ọ́lọ́ọ́ yìí. Oore-ọ̀fẹ́ Jesu Kristi Olúwa wa kí ó wà pẹ̀lú yín.

  2. Romu 16:21nǹkan bí 60 lẹ́yìn Kristi

    Timotiu alábáṣiṣẹ́ mi, àti Lukiu, àti Jasoni, àti Sosipateru, àwọn ìbátan mi, kí yín.

  3. Romu 16:22nǹkan bí 60 lẹ́yìn Kristi

    Èmi Tertiu tí ń kọ lẹ́tà yìí, kí yín nínú Olúwa.

  4. Romu 16:23nǹkan bí 60 lẹ́yìn Kristi

    Gaiusi, ẹni tí èmi àti gbogbo ìjọ gbádùn ìtọ́jú wa tí ó ṣe náà fi ìkíni ránṣẹ́. Erastu, ẹni tí ó jẹ́ olùtọ́jú ìṣúra ìlú, àti arákùnrin wa Kuartu fi ìkíni wọn ránṣẹ́.

  5. Romu 16:24nǹkan bí 60 lẹ́yìn Kristi

    The grace of our Lord Jesus Christ be with you all. Amen.

  6. Romu 16:25nǹkan bí 60 lẹ́yìn Kristi

    Ǹjẹ́ fún ẹni tí ó ní agbára láti fi ẹsẹ̀ yín múlẹ̀ nípa ìyìnrere mi àti ìpolongo Jesu Kristi, gẹ́gẹ́ bí ìṣípayá ohun ìjìnlẹ̀ tí a ti pamọ́ láti ìgbà ayérayé,

  7. Romu 16:26nǹkan bí 60 lẹ́yìn Kristi

    ṣùgbọ́n, nísinsin yìí, a ti fihàn nípa ìwé mímọ́ àwọn wòlíì, àti gẹ́gẹ́ bí àṣẹ tí Ọlọ́run ayérayé pa, kí gbogbo orílẹ̀-èdè le ní ìgbọ́ràn tí ó wá láti inú ìgbàgbọ́;

  8. Romu 16:27nǹkan bí 60 lẹ́yìn Kristi

    kí ògo wà fún Ọlọ́run, ẹnìkan ṣoṣo tí ọgbọ́n í ṣe tirẹ̀ nípa Jesu Kristi títí láé! Àmín.

  9. 1 Kọrinti 1:1nǹkan bí 59 lẹ́yìn Kristi

    Paulu, ẹni ti a pé láti jẹ́ aposteli Kristi Jesu nípa ìfẹ́ Ọlọ́run àti Sostene arákùnrin wa,

  10. 1 Kọrinti 1:2nǹkan bí 59 lẹ́yìn Kristi

    Sí ìjọ ènìyàn Ọlọ́run ni Kọrinti, sí àwọn ti a sọ di mímọ́ nínú Kristi Jesu àti àwọn ti a pè láti jẹ́ mímọ́ pẹ̀lú gbogbo ènìyàn ni ibikíbi ti ń pe orúkọ Olúwa wa Jesu Kristi ẹni ti ń ṣe Olúwa tiwọn àti ti àwa náà:

  11. 1 Kọrinti 1:3nǹkan bí 59 lẹ́yìn Kristi

    Oore-ọ̀fẹ́ àti àlàáfíà fún yín láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run Baba wa àti Olúwa wa tí í ṣe Jesu Kristi.

  12. 1 Kọrinti 1:4nǹkan bí 59 lẹ́yìn Kristi

    Nígbà gbogbo ni mo ń dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run fún oore-ọ̀fẹ́ rẹ̀ tó fi fún un yín nínú Kristi Jesu.

  13. 1 Kọrinti 1:5nǹkan bí 59 lẹ́yìn Kristi

    Nítorí nínú rẹ̀ ni a ti sọ yín di ọlọ́rọ̀ nínú ọ̀rọ̀ sísọ yín gbogbo àti nínú ìmọ̀ yín gbogbo.

  14. 1 Kọrinti 1:6nǹkan bí 59 lẹ́yìn Kristi

    Nítorí ẹ̀rí wa nínú Kristi ni a ti fi ìdí rẹ̀ múlẹ̀ nínú yín.

  15. 1 Kọrinti 1:7nǹkan bí 59 lẹ́yìn Kristi

    Nítorí náà ẹ̀yin kò ṣe aláìní nínú èyíkéyìí ẹ̀bùn ẹ̀mí, bí ẹ̀yin ṣe ń retí ìfarahàn Olúwa wa Jesu Kristi.

  16. 1 Kọrinti 1:8nǹkan bí 59 lẹ́yìn Kristi

    Òun yóò sì mú yín dúró títí dé òpin, kí ẹ̀yin kí ó lè jẹ́ aláìlábùkù ní ọjọ́ Olúwa wa Jesu Kristi.

  17. 1 Kọrinti 1:9nǹkan bí 59 lẹ́yìn Kristi

    Ọlọ́run, nípasẹ̀ ẹni ti a pè yín sínú ìdàpọ̀ pẹ̀lú Ọmọ rẹ̀ Jesu Kristi Olúwa wa, jẹ́ Olóòtítọ́.

  18. 1 Kọrinti 1:10nǹkan bí 59 lẹ́yìn Kristi

    Mo bẹ̀ yín ẹ̀yin ara, ní orúkọ Olúwa wa Jesu Kristi, pé kí gbogbo yín fohùn ṣọ̀kan kí ó máa ṣe sí ìyapa láàrín yín, àti pé kí a lè ṣe yín pé ní inú àti ìmọ̀ kan náà.

  19. 1 Kọrinti 1:11nǹkan bí 59 lẹ́yìn Kristi

    Ẹ̀yin ará mi, àwọn kan láti ilé Kloe sọ di mí mọ̀ fún mi pé ìjà ń bẹ́ láàrín yín.

  20. 1 Kọrinti 1:12nǹkan bí 59 lẹ́yìn Kristi

    Ohun tí mo ń sọ ní pé, olúkúlùkù yín ń wí pé, “Èmí tẹ̀lé Paulu”; “Èmi tẹ̀lé Apollo”; òmíràn wí pé, “Èmi tẹ̀lé Kefa, Peteru”; àti ẹlòmíràn wí pé, “Èmi tẹ̀lé Kristi.”

  21. 1 Kọrinti 1:13nǹkan bí 59 lẹ́yìn Kristi

    Ǹjẹ́ a ha pín Kristi bí? Ṣé a kan Paulu mọ́ àgbélébùú fún un yín bí? Ǹjẹ́ a tẹ̀ yín bọ omi ní orúkọ Paulu bí?

  22. 1 Kọrinti 1:14nǹkan bí 59 lẹ́yìn Kristi

    Inú mi dún púpọ̀ pé èmi kò tẹ ẹnikẹ́ni nínú yín bọ omi yàtọ̀ sí Krisipu àti Gaiusi.

  23. 1 Kọrinti 1:15nǹkan bí 59 lẹ́yìn Kristi

    Nítorí náà kò sí ẹni tí ó lè sọ pé òun ṣe ìtẹ̀bọmi ní orúkọ èmi fúnra ara mi.

  24. 1 Kọrinti 1:16nǹkan bí 59 lẹ́yìn Kristi

    (Bẹ́ẹ̀ ni, mo tún tẹ ìdílé Stefana bọ omi; lẹ́yìn èyí, èmí kò rántí pé mo tẹ ẹnikẹ́ni bọ omi mọ́ níbikíbi).

  25. 1 Kọrinti 1:17nǹkan bí 59 lẹ́yìn Kristi

    Nítorí Kristi kò rán mi láti máa ṣe ìtẹ̀bọmi, ṣùgbọ́n ó rán mi láti máa wàásù ìyìnrere: kì í ṣe nípa ọgbọ́n ènìyàn, kí a máa ṣe sọ àgbélébùú Kristi dí aláìlágbára.