- English
- King James KJV
- Complete Jewish CJB
- World English WEBM
- Berean Standard BSB
- American Standard ASV
- Geneva GNV
- Young's Literal YLT
- Douay-Rheims DRC
- International
- Shqip ALB
- العربية SVD
- বাংলা BN-IRV
- မြန်မာ Judson
- 简体文 CUV-S
- 繁體中文 CUV-T
- Čeština BKR
- Nederlands STVE
- Français LSG
- Deutsch SCH
- Ελληνικά Vamvas
- ગુજરાતી GU-IRV
- Hausa HCB
- עברית Hebrew
- हिन्दी HCV
- Magyar KAROLI
- Bahasa Indonesia INDO-TB
- Italiano Diodati
- 日本語 Kougo
- 한국어 Korean
- മലയാളം MAL
- मराठी MRCV
- Norsk DNB
- فارسی OPV
- Polski BG
- Português Almeida
- Română Cornilescu
- Русский Synodal
- Español RVG
- Kiswahili Neno
- Svenska SV1917
- Tagalog TAG-ADB
- தமிழ் TCV
- తెలుగు TSA
- ภาษาไทย THAI-KJV
- Українська Ohienko
- Tiếng Việt CADMAN
- Yorùbá YCB
circa 2100–1900 BC
Abraham: The Covenant
God calls Abram from Ur, establishes an everlasting covenant, and promises a son through whom all nations will be blessed.
Àwọn ẹsẹ láti sáà yìí
- Gẹnẹsisi 15:14nǹkan bí 1911 ṣáájú Kristi
Ṣùgbọ́n orílẹ̀-èdè náà tí wọn yóò máa sìn, ni èmi ó dá lẹ́jọ́, lẹ́yìn náà ni wọn ó sì jáde pẹ̀lú ọrọ̀ púpọ̀.
- Gẹnẹsisi 15:15nǹkan bí 1911 ṣáájú Kristi
Ṣùgbọ́n ìwọ yóò tọ àwọn baba rẹ lọ ni àlàáfíà, bẹ́ẹ̀ ni ìwọ yóò sì di arúgbó kí a tó gbé ọ sin.
- Gẹnẹsisi 15:16nǹkan bí 1911 ṣáájú Kristi
Ní ìran kẹrin àwọn ìran rẹ yóò padà wá sí ibi. Nítorí ẹ̀ṣẹ̀ àwọn ará Amori kò ì tí ì kún òsùwọ̀n.”
- Gẹnẹsisi 15:17nǹkan bí 1911 ṣáájú Kristi
Nígbà tí oòrùn wọ̀ tí ilẹ̀ sì ṣú, ìkòkò iná tí ń ṣèéfín àti ọwọ́ iná sì ń kọjá láàrín ẹ̀là ẹran náà.
- Gẹnẹsisi 15:18nǹkan bí 1911 ṣáájú Kristi
Ní ọjọ́ náà gan an ni Olúwa dá májẹ̀mú pẹ̀lú Abramu, ó sì wí pé, “Àwọn ìran rẹ ni èmi yóò fi ilẹ̀ yìí fún, láti odò Ejibiti dé odò ńlá Eufurate:
- Gẹnẹsisi 15:19nǹkan bí 1911 ṣáájú Kristi
ilẹ̀ àwọn ará Keni, àti ti ará Kenissiti, àti ará Kadmoni,
- Gẹnẹsisi 15:20nǹkan bí 1911 ṣáájú Kristi
àti ti ará Hiti, àti ti ará Peresi, àti ti ará Refaimu.
- Gẹnẹsisi 15:21nǹkan bí 1911 ṣáájú Kristi
Àti ti ará Amori, àti ti ará Kenaani, àti ti ará Girgaṣi àti ti ará Jebusi.”
- Gẹnẹsisi 16:1nǹkan bí 1912 ṣáájú Kristi
Sarai, aya Abramu kò bímọ fún un, ṣùgbọ́n ó ní ọmọ ọ̀dọ̀ obìnrin ará Ejibiti kan tí ń jẹ́ Hagari.
- Gẹnẹsisi 16:2nǹkan bí 1912 ṣáájú Kristi
Nítorí náà, Sarai wí fún Abramu pé, “Kíyèsi i Olúwa ti sé mi ní inú, èmi kò sì bímọ, wọlé tọ ọmọ ọ̀dọ̀ mi lọ, bóyá èmi yóò le ti ipasẹ̀ rẹ̀ ní ọmọ.” Abramu sì gba ohun tí Sarai sọ.
- Gẹnẹsisi 16:3nǹkan bí 1911 ṣáájú Kristi
Lẹ́yìn ọdún mẹ́wàá tí Abramu ti ń gbé ni Kenaani ni Sarai mú ọmọbìnrin, ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ Hagari, tí í ṣe ará Ejibiti fún Abramu ọkọ rẹ̀ láti fi ṣe aya.
- Gẹnẹsisi 16:4nǹkan bí 1911 ṣáájú Kristi
Abramu sì bá Hagari lòpọ̀, ó sì lóyún. Nígbà tí ó sì ti mọ̀ pé òun lóyún, ó bẹ̀rẹ̀ sì ní kẹ́gàn ọ̀gá rẹ̀.
- Gẹnẹsisi 16:5nǹkan bí 1911 ṣáájú Kristi
Nígbà náà ni Sarai wí fún Abramu pé, “Ìwọ ni ó jẹ́ kí ẹ̀gbin yìí máa jẹ mí, mo fa ọmọ ọ̀dọ̀ mi lé ọ lọ́wọ́, nígbà tí ó sì rí i pé òun lóyún, mo di ẹni ẹ̀gàn ní ojú rẹ̀. Kí Olúwa kí ó ṣe ìdájọ́ láàrín tèmi tìrẹ.”
- Gẹnẹsisi 16:6nǹkan bí 1911 ṣáájú Kristi
Abramu dáhùn pé, “Ìwọ ló ni ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ, ṣe ohunkóhun tí ó bá tọ́ ní ojú rẹ sí i.” Nígbà náà ni Sarai fi ìyà jẹ Hagari, ó sì sálọ.
- Gẹnẹsisi 16:7nǹkan bí 1911 ṣáájú Kristi
Angẹli Olúwa sì rí Hagari ní ẹ̀gbẹ́ ìsun omi ní ijù, ìsun omi tí ó wà ní ẹ̀gbẹ́ ọ̀nà tí ó lọ sí Ṣuri.
- Gẹnẹsisi 16:8nǹkan bí 1911 ṣáájú Kristi
Ó sì wí pé, “Hagari, ìránṣẹ́ Sarai, níbo ni o ti ń bọ̀, níbo sì ni ìwọ ń lọ?” Ó sì dáhùn pé, “Mo ń sálọ kúrò lọ́dọ̀ ọ̀gá mi Sarai ni.”
- Gẹnẹsisi 16:9nǹkan bí 1911 ṣáájú Kristi
Angẹli Olúwa sì wí fún un pé, “Padà lọ sí ọ̀dọ̀ ọ̀gá rẹ kí o sì tẹríba fún un.”
- Gẹnẹsisi 16:10nǹkan bí 1911 ṣáájú Kristi
Angẹli Olúwa náà sì fi kún fún un pé, “Èmi yóò sọ ọ́ di orílẹ̀-èdè ńlá, ìran rẹ kì yóò sì lóǹkà.”
- Gẹnẹsisi 16:11nǹkan bí 1911 ṣáájú Kristi
Angẹli Olúwa náà sì wí fún un pé, “Ìwọ ti lóyún, ìwọ yóò sì bí ọmọkùnrin kan. Ìwọ yóò sì pe orúkọ rẹ̀ ní Iṣmaeli, nítorí tí Olúwa ti rí ìpọ́njú rẹ.
- Gẹnẹsisi 16:12nǹkan bí 1911 ṣáájú Kristi
Òun yóò jẹ́ oníjàgídíjàgan ènìyàn ọwọ́ rẹ̀ yóò wà lára ènìyàn gbogbo, ọwọ́ ènìyàn gbogbo yóò sì wà lára rẹ̀, yóò sì máa gbé ní ìkanra pẹ̀lú àwọn arákùnrin rẹ̀.”
- Gẹnẹsisi 16:13nǹkan bí 1911 ṣáájú Kristi
Ó sì pe orúkọ Olúwa tí o bá sọ̀rọ̀ ní, “Ìwọ ni Ọlọ́run tí ó rí mi,” nítorí tí ó wí pé, “Mo ti ri ẹni tí ó rí mi báyìí.”
- Gẹnẹsisi 16:14nǹkan bí 1911 ṣáájú Kristi
Nítorí náà ni a ṣe ń pe kànga náà ní Beeri-Lahai-Roi; kànga ẹni alààyè tí ó rí mi. Ó wà ní agbede-méjì Kadeṣi àti Beredi.
- Gẹnẹsisi 16:15nǹkan bí 1910 ṣáájú Kristi
Hagari sì bí ọmọkùnrin kan fún Abramu, Abramu sì pe orúkọ rẹ̀ ní Iṣmaeli.
- Gẹnẹsisi 16:16nǹkan bí 1910 ṣáájú Kristi
Abramu jẹ́ ẹni ọdún mẹ́rìndínláàádọ́rùn-ún nígbà tí Hagari bí Iṣmaeli fún un.
- Gẹnẹsisi 17:1nǹkan bí 1897 ṣáájú Kristi
Ní ìgbà tí Abramu di ẹni ọ̀kàndínlọ́gọ́rùn-ún ọdún, Olúwa farahàn án, ó sì wí pé, “Èmi ni Ọlọ́run alágbára, máa rìn níwájú mi, kí o sì jẹ́ aláìlábùkù.