- English
- King James KJV
- Complete Jewish CJB
- World English WEBM
- Berean Standard BSB
- American Standard ASV
- Geneva GNV
- Young's Literal YLT
- Douay-Rheims DRC
- International
- Shqip ALB
- العربية SVD
- বাংলা BN-IRV
- မြန်မာ Judson
- 简体文 CUV-S
- 繁體中文 CUV-T
- Čeština BKR
- Nederlands STVE
- Français LSG
- Deutsch SCH
- Ελληνικά Vamvas
- ગુજરાતી GU-IRV
- Hausa HCB
- עברית Hebrew
- हिन्दी HCV
- Magyar KAROLI
- Bahasa Indonesia INDO-TB
- Italiano Diodati
- 日本語 Kougo
- 한국어 Korean
- മലയാളം MAL
- मराठी MRCV
- Norsk DNB
- فارسی OPV
- Polski BG
- Português Almeida
- Română Cornilescu
- Русский Synodal
- Español RVG
- Kiswahili Neno
- Svenska SV1917
- Tagalog TAG-ADB
- தமிழ் TCV
- తెలుగు TSA
- ภาษาไทย THAI-KJV
- Українська Ohienko
- Tiếng Việt CADMAN
- Yorùbá YCB
Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa The Second Temple
Àwọn ẹsẹ Bíbélì pàtàkì
“Ṣùgbọ́n ní ọdún kìn-ín-ní ìjọba Kirusi ọba Babeli, ọba Kirusi pàṣẹ pé kí a tún ilé Ọlọ́run yìí kọ́.
Òun tilẹ̀ kò jáde láti inú tẹmpili ní Babeli fàdákà àti ohun èlò wúrà ilé Ọlọ́run, èyí tí Nebukadnessari kó láti inú tẹmpili ní Jerusalẹmu wá sí inú tẹmpili ní Babeli. Ọba Kirusi kó wọn fún ọkùnrin kan tí orúkọ rẹ̀ a máa jẹ́ Ṣeṣbassari, ẹni tí ó ti yàn gẹ́gẹ́ bí i baálẹ̀,
ó sì sọ fún un pé, ‘Kó àwọn ohun èlò yìí kí o lọ, kí o sì kó wọn sí inú ilé Olúwa ní Jerusalẹmu, kí ẹ sì tún ilé Ọlọ́run kọ́ sí ipò o rẹ̀.’
“Nígbà náà ni Ṣeṣbassari náà wá, ó sí fi ìpìlẹ̀ ilé Ọlọ́run tí ó wá ní Jerusalẹmu lélẹ̀, láti ìgbà náà àní títí di ìsinsin yìí ni o ti n bẹ ní kíkọ́ ṣùgbọ́n, kò sí tí ì parí tán.”
Nísinsin yìí tí ó bá tẹ́ ọba lọ́rùn, ẹ jẹ́ kí a ṣe ìwádìí nínú ìwé ìrántí ní ilé ìṣúra ọba ní Babeli láti rí bí ọba Kirusi fi àṣẹ lélẹ̀ lóòótọ́ láti tún ilé Ọlọ́run yìí kọ́ ní Jerusalẹmu. Nígbà náà jẹ́ kí ọba kó fi ìpinnu rẹ̀ lórí ọ̀rọ̀ yìí ránṣẹ́ sí wa.
Nígbà náà ni ọba Dariusi pàṣẹ, wọ́n sì wá inú ilé ìfí nǹkan pamọ́ sí ní ilé ìṣúra ní Babeli.
A rí ìwé kíká kan ní Ekbatana ibi kíkó ìwé sí ní ilé olódi agbègbè Media, wọ̀nyí ni ohun tí a kọ sínú rẹ̀. Ìwé ìrántí.
Ní ọdún kìn-ín-ní ìjọba ọba Kirusi, ọba pa àṣẹ kan nípa tẹmpili Ọlọ́run ní Jerusalẹmu. Jẹ́ kí a tún tẹmpili ibi tí a ti ń rú onírúurú ẹbọ kọ́, kí a fi ìpìlẹ̀ rẹ̀ lélẹ̀ ni gíga àti fífẹ̀ rẹ̀ jẹ́ àádọ́rùn-ún ẹsẹ̀ bàtà,
pẹ̀lú ipele òkúta ńlá ńlá mẹ́ta ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ àti ipele pákó kan, kí a san owó rẹ̀ láti inú ilé ìṣúra ọba.
Sì jẹ́ kí wúrà àti àwọn ohun èlò fàdákà ti ilé Ọlọ́run, tí Nebukadnessari kó láti ilé Olúwa ní Jerusalẹmu tí ó sì kó lọ sí Babeli, di dídápadà sí ààyè wọn nínú tẹmpili ní Jerusalẹmu; kí a kó wọn sí inú ilé Ọlọ́run.
Nítorí náà, kí ìwọ, Tatenai baálẹ̀ agbègbè Eufurate àti Ṣetar-bosnai àti àwọn ẹlẹgbẹ́ yín, àwọn ìjòyè ti agbègbè náà kúrò níbẹ̀.
Ẹ fi iṣẹ́ ilé Ọlọ́run yìí lọ́rùn sílẹ̀ láì dí i lọ́wọ́. Ẹ jẹ́ kí baálẹ̀ àwọn Júù àti àwọn àgbàgbà Júù tún ilé Ọlọ́run yín kọ́ sí ipò rẹ̀.
Síwájú sí i, mo pàṣẹ ohun tí ẹ gbọdọ̀ ṣe fún àwọn àgbàgbà Júù wọ̀nyí lórí kíkọ́ ilé Ọlọ́run yìí. Gbogbo ìnáwó àwọn ọkùnrin yìí ni kí ẹ san lẹ́kùnrẹ́rẹ́ lára ìṣúra ti ọba, láti ibi àkójọpọ̀ owó ìlú ti agbègbè Eufurate kí iṣẹ́ náà má bà dúró.
Ohunkóhun tí wọ́n bá fẹ́—àwọn ọ̀dọ́ akọ màlúù, àwọn àgbò, ọ̀dọ́-àgùntàn fún ẹbọ sísun sí Ọlọ́run ọ̀run, àti jéró, iyọ̀, wáìnì àti òróró, bí àwọn àlùfáà ní Jerusalẹmu ti béèrè ni ẹ gbọdọ̀ fún wọn lójoojúmọ́ láìyẹ̀.
Kí wọn lè rú àwọn ẹbọ tí ó tẹ́ Ọlọ́run ọ̀run lọ́rùn kí wọ́n sì gbàdúrà fún àlàáfíà ọba àti àwọn ọmọ rẹ̀.
Síwájú sí i, mo pàṣẹ pé tí ẹnikẹ́ni bá yí àṣẹ yìí padà, kí fa igi àjà ilé rẹ̀ yọ jáde, kí a sì gbe dúró, kí a sì fi òun náà kọ́ sí orí rẹ̀ kí ó wo ilé rẹ̀ palẹ̀ a ó sì sọ ọ́ di ààtàn.
Kí Ọlọ́run, tí ó ti jẹ́ kí orúkọ rẹ̀ máa gbé ibẹ̀, kí ó pa gbogbo ọba àti orílẹ̀-èdè rún tí ó bá gbé ọwọ́ sókè láti yí àṣẹ yìí padà tàbí láti wó tẹmpili yìí tí ó wà ní Jerusalẹmu run. Èmi Dariusi n pàṣẹ rẹ̀, jẹ́ kí ó di mímúṣẹ láìyí ohunkóhun padà.
A parí ilé Olúwa ní ọjọ́ kẹta, oṣù Addari tí í se oṣù kejì ní ọdún kẹfà ti ìjọba ọba Dariusi.
Nígbà náà ni àwọn ènìyàn Israẹli—àwọn àlùfáà, àwọn Lefi àti àwọn ìgbèkùn tí ó padà, ṣe ayẹyẹ yíya ilé Ọlọ́run sí mímọ́ pẹ̀lú ayọ̀.
Fún yíya ilé Ọlọ́run yìí sí mímọ́, wọ́n pa ọgọ́rùn-ún akọ màlúù, igba àgbò àti irinwó (400) akọ ọ̀dọ́-àgùntàn, àti gẹ́gẹ́ bí ọrẹ ẹ̀ṣẹ̀ fún gbogbo Israẹli, àgbò méjìlá, ọ̀kọ̀ọ̀kan fún olúkúlùkù àwọn ẹ̀yà Israẹli.
Wọ́n sì fi àwọn àlùfáà sí àwọn ìpín wọ́n àti àwọn Lefi sì ẹgbẹẹgbẹ́ wọn fún ìsin ti Ọlọ́run ní Jerusalẹmu, gẹ́gẹ́ bí ohun tí a kọ sínú ìwé Mose.
ta ni ó sọ nípa Kirusi pé, ‘Òun ni Olùṣọ́-àgùntàn mi àti pé òun yóò ṣe ohun gbogbo tí mo fẹ́; òun yóò sọ nípa Jerusalẹmu pé, “Jẹ́ kí a tún kọ́,” àti nípa tẹmpili, “Jẹ́ kí a fi ìpìlẹ̀ rẹ̀ lé ilẹ̀.” ’ ”
Yóò sì fi ìdí i májẹ̀mú kan múlẹ̀ pẹ̀lú ọ̀pọ̀lọpọ̀ fún ọ̀sẹ̀ kan. Ní àárín ọ̀sẹ̀ ni yóò mú òpin bá ẹbọ àti ọrẹ ẹbọ. Àti lórí apá kan ni yóò dà ìríra tí ó mú ìdahoro wá, títí tí òpin tí a ti pàṣẹ lórí asọnidahoro yóò fi padà fi dé bá a.”
“Agbára ọmọ-ogun rẹ̀ yóò dìde láti ba ohun mímọ́ ilé olódi tẹmpili jẹ́, yóò sì pa ẹbọ ojoojúmọ́ rẹ́. Nígbà náà ni wọn yóò gbé ìríra tí ó fa ìsọdahoro kalẹ̀.
Ní ọdún kejì ọba Dariusi ní ọjọ́ kìn-ín-ní oṣù kẹfà, ọ̀rọ̀ Olúwa wá nípasẹ̀ wòlíì Hagai sí Serubbabeli ọmọ Ṣealitieli, baálẹ̀ Juda, àti sọ́dọ̀ Joṣua ọmọ Josadaki, olórí àlùfáà.