Skip to content

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa The Second Temple

134 ẹsẹ · 49 abala

Àwọn ẹsẹ Bíbélì pàtàkì

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Báyìí ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí: “Àwọn ènìyàn wọ̀nyí wí pé, ‘Kò tí ì tó àkókò láti kọ́ ilé Olúwa.’ ”

  2. Nígbà náà ni ọ̀rọ̀ Olúwa wá láti ọ̀dọ̀ wòlíì Hagai wí pé,

  3. “Ǹjẹ́ àkókò ni fún ẹ̀yin fúnra yín láti máa gbé ní ilé tí a ṣe ní ọ̀ṣọ́ nígbà tí ilé yìí wà ni ahoro?”

  4. Nísìnsinyìí, èyí ni ohun tí Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí: “Ẹ kíyèsi ọ̀nà yín.

  5. Ẹ̀yin ti gbìn ohun ti ó pọ̀. Ṣùgbọ́n ẹ̀yin kórè díẹ̀ níbẹ̀. Ẹ̀yin jẹun, ṣùgbọ́n ẹ̀yin kò yó. Ẹ̀yin mu ṣùgbọ́n kò tẹ́ ẹ yín lọ́run; ẹ̀yin wọ aṣọ, ṣùgbọ́n kò mú òtútù yin lọ; ẹyin gba owó iṣẹ́ ṣùgbọ́n ẹ ń gbà á sínú ajádìí àpò.”

  6. Ẹ gun orí àwọn òkè ńlá lọ, kí ẹ sì mú igi wá pẹ̀lú yín. Kí ẹ sì kọ́ ilé náà, kí inú mi bà le è dùn sí i, kí a sì yín mí lógo,” ni Olúwa wí.

  7. “Ẹyin ti ń retí ọ̀pọ̀, ṣùgbọ́n kíyèsi i, o yípadà sí díẹ̀. Ohun tí ẹ̀yin mú wa ilé, èmi sì fẹ́ ẹ dànù. Nítorí kí ni?” ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí. “Nítorí ilé mi tí ó dahoro; tí olúkúlùkù yín sì ń sáré fún ilé ara rẹ̀.

  8. Nítorí yín ni àwọn ọ̀run ṣe dá ìrì dúró tí ilẹ̀ sì kọ̀ láti mu èso jáde.

  9. Mo sì ti pe ọ̀dá sórí ilẹ̀ àti sórí àwọn òkè ńlá, sórí ọkà àti sórí wáìnì tuntun, sórí òróró àti sórí ohun ti ilẹ̀ ń mú jáde, sórí ènìyàn, sórí ẹran àti sórí gbogbo iṣẹ́ ọwọ́ yín.”

  10. ‘Ta ni nínú yín tí ó kù tí ó sì ti rí ilé yìí ní ògo rẹ̀ àkọ́kọ́? Báwo ni ó ṣe ri sí yín nísinsin yìí? Ǹjẹ́ kò dàbí asán lójú yín?

  11. Èmi yóò mi gbogbo orílẹ̀-èdè, ìfẹ́ gbogbo orílẹ̀-èdè yóò fà sí tẹmpili yìí, Èmi yóò sì kún ilé yìí pẹ̀lú ògo,’ ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí.

  12. ‘Tèmi ni fàdákà àti wúrà,’ ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí.

  13. ‘Ògo ìkẹyìn ilé yìí yóò pọ̀ ju ti ìṣáájú lọ,’ ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí, ‘Àti ní ìhín yìí ni Èmi ó sì fi àlàáfíà fún ni,’ ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí.”

  14. “ ‘Ǹjẹ́ nísinsin yìí, ẹ ro èyí dáradára láti òní yìí lọ, ẹ kíyèsi bí nǹkan ṣe rí tẹ́lẹ̀, a to òkúta kan lé orí èkejì ní tẹmpili Olúwa.

  15. Mo fi ìrẹ̀dànù, ìmúwòdù àti yìnyín bá gbogbo iṣẹ́ ọwọ́ yín jẹ; síbẹ̀ ẹ̀yin kò yípadà sí ọ̀dọ̀ mi,’ ni Olúwa wí.

  16. Ǹjẹ́ èso ha wà nínú abà bí? Títí di àkókò yìí, àjàrà àti igi ọ̀pọ̀tọ́ àti pomegiranate, àti igi olifi kò ì tí ì so èso kankan. “ ‘Láti òní lọ ni èmi yóò bùkún fún un yin.’ ”

  17. Mo sì dáhùn mo sì wí fún angẹli tí ó ń bá mi sọ̀rọ̀, pé, “Kín ni wọ̀nyí, olúwa mi?”

  18. Angẹli tí ó ń bá mi sọ̀rọ̀ dáhùn ó sì wí fún mi pé, “Ìwọ kò mọ ohun tí àwọn wọ̀nyí jásí?” Mo sì wí pé, “Èmi kò mọ̀ ọ́n, olúwa mi.”

  19. Ó sì dáhùn ó sì wí fún mi pé, “Èyí ni ọ̀rọ̀ Olúwa sí Serubbabeli tó wí pé: ‘Kì í ṣe nípa ipá, kì í ṣe nípa agbára, bí kò ṣe nípa Ẹ̀mí mi,’ ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí.

  20. “Ta ni ìwọ, ìwọ òkè ńlá? Ìwọ yóò di pẹ̀tẹ́lẹ̀ níwájú Serubbabeli: òun yóò sì fi ariwo mú òkúta téńté orí rẹ̀ wá, yóò máa kígbe wí pé, ‘Ọlọ́run bùkún fun! Ọlọ́run bùkún fun!’ ”

  21. Ọ̀rọ̀ Olúwa sì tọ̀ mí wá, wí pé:

  22. “Ọwọ́ Serubbabeli ni a ti ṣe ìpìlẹ̀ ilé yìí, ọwọ́ rẹ̀ ni yóò sì parí rẹ̀; ìwọ yóò sì mọ̀ pé, Olúwa àwọn ọmọ-ogun ni ó rán mi sí i yín.

  23. “Ṣùgbọ́n ta ni ha kẹ́gàn ọjọ́ ohun kékeré? Nítorí wọn ó yọ̀ nígbà ti wọ́n bá rí okùn ìwọ̀n nì lọ́wọ́ Serubbabeli. “(Àwọn méje wọ̀nyí ni àwọn ojú Olúwa, tí ó ń sáré síyìn-ín sọ́hùn-ún ní gbogbo ayé.)”

  24. Báyìí ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí pé, “Jẹ́ kí ọwọ́ yín le ẹ̀yin ti ń gbọ́ ọ̀rọ̀ wọ̀nyí ní ọjọ́ wọ̀nyí ni ẹnu àwọn wòlíì tí ó wà ni ọjọ́ tí a fi ìpìlẹ̀ ilé Olúwa àwọn ọmọ-ogun lélẹ̀, jẹ́ ki ọwọ́ rẹ̀ le kí a bá lè kọ́ tẹmpili.

  25. Nítorí pé, ṣáájú ọjọ́ wọ̀nyí, owó ọ̀yà ènìyàn kò tó nǹkan, bẹ́ẹ̀ ni ọ̀yà ẹran pẹ̀lú, bẹ́ẹ̀ ni kò sí àlàáfíà fún ẹni ń jáde lọ, tàbí ẹni ti ń wọlé bọ, nítorí ìpọ́njú náà: nítorí mo dojú gbogbo ènìyàn, olúkúlùkù kọ aládùúgbò rẹ̀.