Fò sí àkóónú

circa 6 BC – AD 30

The Life of Jesus

The eternal Son of God enters history: born in Bethlehem, baptized in the Jordan, crucified at Golgotha, raised on the third day.

3,779 ẹsẹ · 4 ìwé tí a bo

Àwọn ẹsẹ láti sáà yìí

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Matiu 4:11nǹkan bí 26 lẹ́yìn Kristi

    Nígbà náà ni èṣù fi í sílẹ̀ lọ, àwọn angẹli sì tọ̀ ọ́ wá, wọ́n sì ṣe ìránṣẹ́ fún un.

  2. Matiu 4:12nǹkan bí 26 lẹ́yìn Kristi

    Nígbà tí Jesu gbọ́ wí pé a ti fi Johanu sínú túbú ó padà sí Galili.

  3. Matiu 4:13nǹkan bí 26 lẹ́yìn Kristi

    Ó kúrò ní Nasareti, ó sì lọ í gbé Kapernaumu, èyí tí ó wà létí Òkun Sebuluni àti Naftali.

  4. Matiu 4:14nǹkan bí 26 lẹ́yìn Kristi

    Kí èyí tí a ti sọtẹ́lẹ̀ láti ẹnu wòlíì Isaiah lè ṣẹ pé,

  5. Matiu 4:15nǹkan bí 26 lẹ́yìn Kristi

    “Ìwọ Sebuluni àti ilẹ̀ Naftali ọ̀nà tó lọ sí Òkun, ní ọ̀nà Jordani, Galili ti àwọn kèfèrí.

  6. Matiu 4:16nǹkan bí 26 lẹ́yìn Kristi

    Àwọn ènìyàn tí ń gbé ni òkùnkùn tí ri ìmọ́lẹ̀ ńlá, àti àwọn tó ń gbé nínú ilẹ̀ òjijì ikú ni ìmọ́lẹ̀ tan fún.”

  7. Matiu 4:17nǹkan bí 26 lẹ́yìn Kristi

    Láti ìgbà náà lọ ni Jesu ti bẹ̀rẹ̀ sí wàásù: “Ẹ ronúpìwàdà, nítorí tí ìjọba ọ̀run kù sí dẹ̀dẹ̀.”

  8. Matiu 4:18nǹkan bí 26 lẹ́yìn Kristi

    Bí Jesu ti ń rìn létí Òkun Galili, ó rí àwọn arákùnrin méjì, Simoni, ti à ń pè ní Peteru, àti Anderu arákùnrin rẹ̀. Wọ́n ń sọ àwọ̀n wọn sínú Òkun nítorí apẹja ni wọ́n.

  9. Matiu 4:19nǹkan bí 26 lẹ́yìn Kristi

    Jesu wí fún wọn pé, “Ẹ wá, ẹ máa tọ̀ mí lẹ́yìn èmi yóò sì sọ yín di apẹja ènìyàn.”

  10. Matiu 4:20nǹkan bí 26 lẹ́yìn Kristi

    Lójúkan náà, wọ́n fi àwọ̀n wọn sílẹ̀, wọ́n sì tọ̀ ọ́ lẹ́yìn.

  11. Matiu 4:21nǹkan bí 26 lẹ́yìn Kristi

    Bí ó sì ti kúrò ní ibẹ̀, ò rí àwọn arákùnrin méjì mìíràn, Jakọbu ọmọ Sebede àti Johanu, arákùnrin rẹ̀. Wọ́n wà nínú ọkọ̀ ojú omi pẹ̀lú Sebede baba wọn, wọ́n ń di àwọ̀n wọn, Jesu sì pè àwọn náà pẹ̀lú.

  12. Matiu 4:22nǹkan bí 26 lẹ́yìn Kristi

    Lójúkan náà, wọ́n fi ọkọ̀ ojú omi àti baba wọn sílẹ̀, wọ́n sì tọ̀ ọ́ lẹ́yìn.

  13. Matiu 4:23nǹkan bí 26 lẹ́yìn Kristi

    Jesu sì rin káàkiri gbogbo Galili, ó ń kọ́ni ní Sinagọgu, ó ń wàásù ìyìnrere ti ìjọba ọ̀run, ó sì ń ṣe ìwòsàn ààrùn gbogbo àti àìsàn láàrín gbogbo ènìyàn.

  14. Matiu 4:24nǹkan bí 26 lẹ́yìn Kristi

    Òkìkí rẹ̀ sì kàn yí gbogbo Siria ká; wọ́n sì gbé àwọn aláìsàn tí ó ní onírúurú ààrùn, àwọn tí ó ní ìnira ẹ̀mí èṣù, àti àwọn ti o ní wárápá àti àwọn tí ó ní ẹ̀gbà; ó sì wò wọ́n sàn.

  15. Matiu 4:25nǹkan bí 26 lẹ́yìn Kristi

    Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn láti Galili, Dekapoli, Jerusalẹmu, Judea, àti láti òkè odò Jordani sì tọ̀ ọ́ lẹ́yìn.

  16. Matiu 5:1nǹkan bí 31 lẹ́yìn Kristi

    Nígbà tí ó rí ọ̀pọ̀ ènìyàn, ó gun orí òkè lọ ó sì jókòó. Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ si tọ̀ ọ́ wá.

  17. Matiu 5:2nǹkan bí 31 lẹ́yìn Kristi

    Ó sì bẹ̀rẹ̀ sí kọ́ wọn. Ó wí pé,

  18. Matiu 5:3nǹkan bí 31 lẹ́yìn Kristi

    “Alábùkún fún ni àwọn òtòṣì ní ẹ̀mí, nítorí tiwọn ni ìjọba ọ̀run.

  19. Matiu 5:4nǹkan bí 31 lẹ́yìn Kristi

    Alábùkún fún ni àwọn tí ń ṣọ̀fọ̀, nítorí a ó tù wọ́n nínú.

  20. Matiu 5:5nǹkan bí 31 lẹ́yìn Kristi

    Alábùkún fún ni àwọn ọlọ́kàn tútù, nítorí wọn yóò jogún ayé.

  21. Matiu 5:6nǹkan bí 31 lẹ́yìn Kristi

    Alábùkún fún ni àwọn tí ebi ń pa tí òǹgbẹ ń gbẹ́ nítorí òdodo, nítorí wọn yóò yó.

  22. Matiu 5:7nǹkan bí 31 lẹ́yìn Kristi

    Alábùkún fún ni àwọn aláàánú, nítorí wọn yóò rí àánú gbà.

  23. Matiu 5:8nǹkan bí 31 lẹ́yìn Kristi

    Alábùkún fún ni àwọn ọlọ́kàn mímọ́, nítorí wọn yóò rí Ọlọ́run.

  24. Matiu 5:9nǹkan bí 31 lẹ́yìn Kristi

    Alábùkún fún ni àwọn onílàjà, nítorí ọmọ Ọlọ́run ni a ó máa pè wọ́n.

  25. Matiu 5:10nǹkan bí 31 lẹ́yìn Kristi

    Alábùkún fún ni àwọn ẹni tí a ṣe inúnibíni sí, nítorí tí wọ́n jẹ́ olódodo nítorí tiwọn ní ìjọba ọ̀run.