- English
- King James KJV
- Complete Jewish CJB
- World English WEBM
- Berean Standard BSB
- American Standard ASV
- Geneva GNV
- Young's Literal YLT
- Douay-Rheims DRC
- International
- Shqip ALB
- العربية SVD
- বাংলা BN-IRV
- မြန်မာ Judson
- 简体文 CUV-S
- 繁體中文 CUV-T
- Čeština BKR
- Nederlands STVE
- Français LSG
- Deutsch SCH
- Ελληνικά Vamvas
- ગુજરાતી GU-IRV
- Hausa HCB
- עברית Hebrew
- हिन्दी HCV
- Magyar KAROLI
- Bahasa Indonesia INDO-TB
- Italiano Diodati
- 日本語 Kougo
- 한국어 Korean
- മലയാളം MAL
- मराठी MRCV
- Norsk DNB
- فارسی OPV
- Polski BG
- Português Almeida
- Română Cornilescu
- Русский Synodal
- Español RVG
- Kiswahili Neno
- Svenska SV1917
- Tagalog TAG-ADB
- தமிழ் TCV
- తెలుగు TSA
- ภาษาไทย THAI-KJV
- Українська Ohienko
- Tiếng Việt CADMAN
- Yorùbá YCB
circa 800–400 BC
The Hebrew Prophets
God speaks through Isaiah, Jeremiah, and the minor prophets—calling Israel to repentance and foretelling the coming Messiah.
Àwọn ẹsẹ láti sáà yìí
- Isaiah 2:20nǹkan bí 759 ṣáájú Kristi
Ní ọjọ́ náà ni àwọn ènìyàn yóò máa sọ àwọn ère fàdákà àti ère wúrà tí wọ́n ti yá fún bíbọ sí èkúté àti àwọn àdán.
- Isaiah 2:21nǹkan bí 759 ṣáájú Kristi
Wọn yóò sálọ sínú ihò ìsàlẹ̀ àpáta àti sínú ihò pàlàpálá àpáta kúrò lọ́wọ́ ìpayà Olúwa àti ògo ọláńlá rẹ̀, nígbà tí ó bá dìde láti mi ayé tìtì.
- Isaiah 2:22nǹkan bí 759 ṣáájú Kristi
Dẹ́kun à ń gba ènìyàn gbọ́, èémí ẹni tó wà ní ihò imú rẹ̀. Nítorí nínú kín ni a lè kà á sí?
- Isaiah 3:1nǹkan bí 759 ṣáájú Kristi
Kíyèsi i, Olúwa, Olúwa àwọn ọmọ-ogun, fẹ́ mú ìpèsè àti ìrànlọ́wọ́ kúrò ní Jerusalẹmu àti Juda gbogbo ìpèsè oúnjẹ àti ìpèsè omi.
- Isaiah 3:2nǹkan bí 759 ṣáájú Kristi
Àwọn akíkanjú àti jagunjagun, adájọ́ àti wòlíì, aláfọ̀ṣẹ àti alàgbà,
- Isaiah 3:3nǹkan bí 759 ṣáájú Kristi
balógun àádọ́ta àti àwọn ènìyàn, onípò gíga; olùdámọ̀ràn, oníṣọ̀nà tí ó dáńtọ́ àti ògbójú oníṣègùn.
- Isaiah 3:4nǹkan bí 759 ṣáájú Kristi
“Èmi ó sọ àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin di aláṣẹ wọn, ọ̀dọ́mọdé lásán làsàn ni yóò sì máa jẹ ọba lórí i wọn.”
- Isaiah 3:5nǹkan bí 759 ṣáájú Kristi
Àwọn ènìyàn yóò sì máa pọ́n ọmọnìkejì, wọn lójú ẹnìkan sí ẹnìkejì rẹ̀, aládùúgbò sí aládùúgbò rẹ̀. Àwọn ọ̀dọ́ yóò gbógun ti àwọn àgbàgbà, àwọn mẹ̀kúnnù yóò dìde sí ọlọ́lá.
- Isaiah 3:6nǹkan bí 759 ṣáájú Kristi
Ọkùnrin kan yóò di ọ̀kan nínú àwọn arákùnrin rẹ̀ mú, nínú ilé baba rẹ̀, yóò sì wí pé, “Ìwọ́ ní aṣọ, ìwọ máa ṣe olórí wa, sì mójútó àwọn ahoro wọ̀nyí!”
- Isaiah 3:7nǹkan bí 759 ṣáájú Kristi
Ṣùgbọ́n ní ọjọ́ náà ni yóò figbe bọnu pé, “Èmi kò ní àtúnṣe kan. Èmi kò ní oúnjẹ, bẹ́ẹ̀ ni n ó ní aṣọ nílé, ẹ má fi mí ṣe olórí àwọn ènìyàn náà.”
- Isaiah 3:8nǹkan bí 759 ṣáájú Kristi
Jerusalẹmu ń ta gbọ̀nọ́ngbọ̀nọ́n Juda ń ṣubú lọ, ọ̀rọ̀ àti ìṣe wọn lòdì sí Olúwa, láti mú ojú ògo rẹ̀ bínú.
- Isaiah 3:9nǹkan bí 759 ṣáájú Kristi
Ìwò ojú wọn ń jẹ́rìí lòdì sí wọn, wọ́n ń polongo ẹ̀ṣẹ̀ wọn bí i Sodomu; wọn ò fi pamọ́! Ègbé ni fún wọn! Wọ́n ti mú ìparun wá sórí ara wọn.
- Isaiah 3:10nǹkan bí 759 ṣáájú Kristi
Ẹ sọ fún olódodo pé yóò dára fún wọn, nítorí ní àjẹgbádùn ni wọn yóò jẹ èso iṣẹ́ ẹ wọn.
- Isaiah 3:11nǹkan bí 759 ṣáájú Kristi
Ègbé ni fún ènìyàn búburú! Ìparun wà lórí i wọn, a ó sì san èrè iṣẹ́ tí ọwọ́ wọn ti ṣe fún wọn.
- Isaiah 3:12nǹkan bí 759 ṣáájú Kristi
Àwọn ọ̀dọ́mọdé ni o ń pọ́n àwọn ènìyàn mi lójú àwọn obìnrin ń jẹ ọba lé wọn lórí. Háà! Ènìyàn mi àwọn afinimọ̀nà yín ti ṣì yín lọ́nà, wọn sì mú yín kúrò ní ipa ọ̀nà yín.
- Isaiah 3:13nǹkan bí 759 ṣáájú Kristi
Olúwa bọ sí ipò rẹ̀ ní ìtẹ́ ìdájọ́ Ó dìde láti dá àwọn ènìyàn lẹ́jọ́.
- Isaiah 3:14nǹkan bí 759 ṣáájú Kristi
Olúwa dojú ẹjọ́ kọ àwọn àgbàgbà àti àwọn olórí àwọn ènìyàn rẹ̀. “Ẹ̀yin ni ẹ ti run ọgbà àjàrà mi, ogún àwọn tálákà ń bẹ̀ nínú ilé yín.
- Isaiah 3:15nǹkan bí 759 ṣáájú Kristi
Kín ni èrò yín láti máa run àwọn ènìyàn mi túútúú tí ẹ sì fojú àwọn tálákà ni gbolẹ̀?” ni Olúwa wí, Olúwa àwọn ọmọ-ogun.
- Isaiah 3:16nǹkan bí 759 ṣáájú Kristi
Olúwa wí pé, “Àwọn obìnrin Sioni jẹ́ agbéraga, wọn ń rìn lọ pẹ̀lú ọrùn tí ó nà tàntàn, tí wọn ń fojú pe ọkùnrin, tí wọn ń sọ̀dí bí wọ́n ti ń yan lọ pẹ̀lú ohun ọ̀ṣọ́ tí ń mì wọnjanwọnjan lọ́rùn ẹsẹ̀ wọn.
- Isaiah 3:17nǹkan bí 759 ṣáájú Kristi
Nítorí náà Olúwa yóò mú egbò wá sórí àwọn obìnrin Sioni, Olúwa yóò sì pá wọn ní agbárí.”
- Isaiah 3:18nǹkan bí 759 ṣáájú Kristi
Ní ọjọ́ náà, Olúwa yóò já ọ̀ṣọ́ wọn gbà kúrò ti ọwọ́ àti gèlè àti ẹ̀gbà ọrùn tí ó dàbí òṣùpá
- Isaiah 3:19nǹkan bí 759 ṣáájú Kristi
gbogbo yẹtí, ẹ̀gbà ọwọ́ àti ìbòjú,
- Isaiah 3:20nǹkan bí 759 ṣáájú Kristi
gbogbo gèlè, ẹ̀gbà ọrùn, ẹsẹ̀ àti àyà, àwọn ìgò tùràrí àti òògùn,
- Isaiah 3:21nǹkan bí 759 ṣáájú Kristi
òrùka ọwọ́ àti ti imú,
- Isaiah 3:22nǹkan bí 759 ṣáájú Kristi
àwọn àtàtà aṣọ, àwọ̀lékè, agbádá àti àpamọ́wọ́,