- English
- King James KJV
- Complete Jewish CJB
- World English WEBM
- Berean Standard BSB
- American Standard ASV
- Geneva GNV
- Young's Literal YLT
- Douay-Rheims DRC
- International
- Shqip ALB
- العربية SVD
- বাংলা BN-IRV
- မြန်မာ Judson
- 简体文 CUV-S
- 繁體中文 CUV-T
- Čeština BKR
- Nederlands STVE
- Français LSG
- Deutsch SCH
- Ελληνικά Vamvas
- ગુજરાતી GU-IRV
- Hausa HCB
- עברית Hebrew
- हिन्दी HCV
- Magyar KAROLI
- Bahasa Indonesia INDO-TB
- Italiano Diodati
- 日本語 Kougo
- 한국어 Korean
- മലയാളം MAL
- मराठी MRCV
- Norsk DNB
- فارسی OPV
- Polski BG
- Português Almeida
- Română Cornilescu
- Русский Synodal
- Español RVG
- Kiswahili Neno
- Svenska SV1917
- Tagalog TAG-ADB
- தமிழ் TCV
- తెలుగు TSA
- ภาษาไทย THAI-KJV
- Українська Ohienko
- Tiếng Việt CADMAN
- Yorùbá YCB
circa 1446 BC
Sinai & The Law
God meets Israel at Mount Sinai, reveals the Ten Commandments, and establishes the Tabernacle and the priestly covenant.
Àwọn ẹsẹ láti sáà yìí
- Eksodu 20:22nǹkan bí 1491 ṣáájú Kristi
Olúwa sì sọ fún Mose pé, “Sọ àwọn nǹkan wọ̀nyí fún àwọn ará Israẹli, ‘Ẹ̀yin ti rí i fúnra yín bí èmi ti bá a yín sọ̀rọ̀ láti ọ̀run wá.
- Eksodu 20:23nǹkan bí 1491 ṣáájú Kristi
Ẹ̀yin kò gbọdọ̀ sin ọlọ́run mìíràn pẹ̀lú mi: ẹ̀yin kò gbọdọ̀ rọ ọlọ́run fàdákà tàbí ọlọ́run wúrà fún ara yín.
- Eksodu 20:24nǹkan bí 1491 ṣáájú Kristi
“ ‘Pẹpẹ erùpẹ̀ ni kí ìwọ mọ fún mi. Ní orí pẹpẹ yìí ni kí ìwọ ti máa rú ẹbọ sísun rẹ sí mi àti ẹbọ àlàáfíà rẹ, àgùntàn rẹ, ewúrẹ́ àti akọ màlúù rẹ. Ní ibi gbogbo tí mo gbé fi ìrántí orúkọ mi sí, èmi yóò sì máa tọ̀ ọ́ wá, èmi yóò sì máa bùkún ọ níbẹ̀.
- Eksodu 20:25nǹkan bí 1491 ṣáájú Kristi
Bí ìwọ bá ṣe pẹpẹ òkúta fún mi, má ṣe fi òkúta tí a ṣe lọ́ṣọ̀ọ́ kọ́ ọ, nítorí bí ìwọ bá lo ohun ọnà rẹ lórí rẹ̀, ìwọ sọ ọ di àìmọ́.
- Eksodu 20:26nǹkan bí 1491 ṣáájú Kristi
Ìwọ kò gbọdọ̀ gun àkàsọ̀ lọ sí ibi pẹpẹ mi, kí àwọn ènìyàn má ba à máa wo ìhòhò rẹ láti abẹ́ aṣọ tí ìwọ wọ̀ nígbà tí ìwọ bá ń gòkè lọ sí ibi pẹpẹ.’
- Eksodu 21:1nǹkan bí 1491 ṣáájú Kristi
“Wọ̀nyí ni àwọn òfin tí ìwọ yóò gbé sí iwájú wọn.
- Eksodu 21:2nǹkan bí 1491 ṣáájú Kristi
“Bí ìwọ bá yá ọkùnrin Heberu ní ìwẹ̀fà, òun yóò sìn ọ́ fún ọdún mẹ́fà. Ṣùgbọ́n ní ọdún keje, òun yóò lọ ni òmìnira láìsan ohunkóhun padà.
- Eksodu 21:3nǹkan bí 1491 ṣáájú Kristi
Bí ó bá wá ní òun nìkan, òun nìkan náà ni yóò padà lọ ní òmìnira; ṣùgbọ́n tí ó bá mú ìyàwó wá, ó ní láti mú ìyàwó rẹ̀ padà lọ.
- Eksodu 21:4nǹkan bí 1491 ṣáájú Kristi
Bí olówó rẹ̀ bá fún un ní aya, tí aya náà sì bímọ ọkùnrin àti obìnrin, aya àti àwọn ọmọ rẹ̀ yóò jẹ́ ti olówó rẹ̀, yóò sì lọ ní òmìnira ní òun nìkan.
- Eksodu 21:5nǹkan bí 1491 ṣáájú Kristi
“Bí ẹrú náà bá sì wí ní gbangba pé, mo fẹ́ràn olúwa mi, ìyàwó mi àti àwọn ọmọ, èmi kò sì fẹ́ ẹ́ gba òmìnira mọ́,
- Eksodu 21:6nǹkan bí 1491 ṣáájú Kristi
nígbà náà ni olúwa rẹ̀ yóò mu wá sí iwájú ìdájọ́. Òun yóò sì mú un lọ sí ẹnu-ọ̀nà tàbí lọ sí ibi ọ̀wọ̀n, yóò sì fi ìlu lu etí rẹ̀, òun yóò sì máa sin olówó rẹ̀ títí ayé.
- Eksodu 21:7nǹkan bí 1491 ṣáájú Kristi
“Bí ọkùnrin kan bá ta ọmọbìnrin rẹ̀ bí ìwẹ̀fà, ọmọbìnrin yìí kò ní gba òmìnira bí i ti ọmọkùnrin.
- Eksodu 21:8nǹkan bí 1491 ṣáájú Kristi
Bí òun kò bá sì tẹ́ olówó rẹ̀ lọ́rùn, ẹni tí ó fẹ́ ẹ fún ara rẹ̀, yóò jẹ́ kí wọn ó rà á padà, òun kò ní ẹ̀tọ́ láti tà á bí ẹrú fún àjèjì, nítorí pé òun ni kò ṣe ojúṣe rẹ̀ pẹ̀lú ìwẹ̀fà náà.
- Eksodu 21:9nǹkan bí 1491 ṣáájú Kristi
Bí ó bá fẹ́ ẹ fún ọmọkùnrin rẹ̀, kò ní máa lò ó bí ìwẹ̀fà mọ́, ṣùgbọ́n yóò máa ṣe sí i gẹ́gẹ́ bí ọmọ rẹ̀ obìnrin.
- Eksodu 21:10nǹkan bí 1491 ṣáájú Kristi
Bí ó bá fẹ́ obìnrin mìíràn, kò gbọdọ̀ kùnà ojúṣe rẹ̀ nípa fífún un ní oúnjẹ àti aṣọ, bẹ́ẹ̀ ni kò gbọdọ̀ kùnà ojúṣe rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọkọ sí aya.
- Eksodu 21:11nǹkan bí 1491 ṣáájú Kristi
Bí ó bá kùnà láti ṣe àwọn nǹkan mẹ́ta wọ̀nyí fún un, òun yóò lọ ní òmìnira láìsan owó kankan padà.
- Eksodu 21:12nǹkan bí 1491 ṣáájú Kristi
“Ẹnikẹ́ni tí ó bá lu arákùnrin rẹ̀ pa, pípa ni a ó pa á.
- Eksodu 21:13nǹkan bí 1491 ṣáájú Kristi
Ṣùgbọ́n bí kò bá mọ̀ ọ́n mọ̀ pa á, tí ó bá jẹ́ àmúwá Ọlọ́run ni, òun yóò lọ sí ibi tí èmi yóò yàn fún un.
- Eksodu 21:14nǹkan bí 1491 ṣáájú Kristi
Ṣùgbọ́n tí ó bá mú arákùnrin rẹ̀, tí ó sì fi ẹ̀tàn pa á. Ẹ mú un kúrò ní iwájú pẹpẹ mi kí ẹ sì pa á.
- Eksodu 21:15nǹkan bí 1491 ṣáájú Kristi
“Ẹnikẹ́ni tí ó bá pa baba tàbí ìyá rẹ̀, pípa ni a ó pa á.
- Eksodu 21:16nǹkan bí 1491 ṣáájú Kristi
“Ẹnikẹ́ni ti ó bá jí ènìyàn gbé, tí ó sì tà á tàbí tí ó fi pamọ́, pípa ni a ó pa á.
- Eksodu 21:17nǹkan bí 1491 ṣáájú Kristi
“Ẹnikẹ́ni tí ó bá ṣépè fún baba tàbí ìyá rẹ̀, pípa ni a ó pa á.
- Eksodu 21:18nǹkan bí 1491 ṣáájú Kristi
“Bí àwọn ọkùnrin méjì bá ń jà, ti ọ̀kan sọ òkúta tàbí fi ìkùùkuu lu ẹnìkejì rẹ̀, tí ó sì pa á lára, ti irú ìpalára bẹ́ẹ̀ mu kí ó wà lórí ìdùbúlẹ̀ àìsàn.
- Eksodu 21:19nǹkan bí 1491 ṣáájú Kristi
Ẹni tó lu ẹnìkejì rẹ̀ kò ní ní ẹ̀bi, níwọ̀n ìgbà ti ẹni tí a lù bá ti lè dìde, tí ó sì lé è fi ọ̀pá ìtìlẹ̀ ní ọwọ́ rẹ̀ rìn káàkiri. Ẹni náà ni láti san owó ti ó fi tọ́jú ara rẹ̀ padà fún un, lẹ́yìn ìgbà tí ara rẹ̀ bá ti yá tan pátápátá.
- Eksodu 21:20nǹkan bí 1491 ṣáájú Kristi
“Bí ọkùnrin kan bá fi ọ̀pá lu ẹrúkùnrin tàbí ẹrúbìnrin rẹ̀, ti ẹrú náà sì kú lójú ẹsẹ̀, a ó fi ìyà jẹ ẹ́.