- English
- King James KJV
- Complete Jewish CJB
- World English WEBM
- Berean Standard BSB
- American Standard ASV
- Geneva GNV
- Young's Literal YLT
- Douay-Rheims DRC
- International
- Shqip ALB
- العربية SVD
- বাংলা BN-IRV
- မြန်မာ Judson
- 简体文 CUV-S
- 繁體中文 CUV-T
- Čeština BKR
- Nederlands STVE
- Français LSG
- Deutsch SCH
- Ελληνικά Vamvas
- ગુજરાતી GU-IRV
- Hausa HCB
- עברית Hebrew
- हिन्दी HCV
- Magyar KAROLI
- Bahasa Indonesia INDO-TB
- Italiano Diodati
- 日本語 Kougo
- 한국어 Korean
- മലയാളം MAL
- मराठी MRCV
- Norsk DNB
- فارسی OPV
- Polski BG
- Português Almeida
- Română Cornilescu
- Русский Synodal
- Español RVG
- Kiswahili Neno
- Svenska SV1917
- Tagalog TAG-ADB
- தமிழ் TCV
- తెలుగు TSA
- ภาษาไทย THAI-KJV
- Українська Ohienko
- Tiếng Việt CADMAN
- Yorùbá YCB
circa 1446 BC
Sinai & The Law
God meets Israel at Mount Sinai, reveals the Ten Commandments, and establishes the Tabernacle and the priestly covenant.
Àwọn ẹsẹ láti sáà yìí
- Eksodu 18:24nǹkan bí 1491 ṣáájú Kristi
Mose fetísílẹ̀ sí àna rẹ̀, ó sì ṣe ohun gbogbo tí ó wí fún un.
- Eksodu 18:25nǹkan bí 1491 ṣáájú Kristi
Mose sì yan àwọn ènìyàn tí wọ́n kún ojú òsùwọ̀n nínú gbogbo Israẹli; ó sì fi wọ́n jẹ olórí àwọn ènìyàn, olórí ẹgbẹẹ̀rún, olórí ọ̀rọ̀ọ̀rún, olórí àràádọ́ta, àti olórí mẹ́wàá mẹ́wàá.
- Eksodu 18:26nǹkan bí 1491 ṣáájú Kristi
Wọ́n sì ń ṣe ìdájọ́ àwọn ènìyàn ní ìgbà gbogbo. Wọ́n sì ń mú ẹjọ́ tó le tọ Mose wá; ṣùgbọ́n wọ́n ń dá ẹjọ́ tí kò le fúnra wọn.
- Eksodu 18:27nǹkan bí 1491 ṣáájú Kristi
Mose sì jẹ́ kí àna rẹ̀ lọ ní ọ̀nà rẹ̀, Jetro sì padà sí ilẹ̀ ẹ rẹ̀.
- Eksodu 19:1nǹkan bí 1491 ṣáájú Kristi
Ní oṣù kẹta tí àwọn Israẹli jáde kúrò ni ilẹ̀ Ejibiti, ni ọjọ́ náà gan an ni wọ́n dé aginjù Sinai.
- Eksodu 19:2nǹkan bí 1491 ṣáájú Kristi
Lẹ́yìn ìgbà tí wọ́n gbéra kúrò ní Refidimu, wọ́n wọ ijù Sinai, wọ́n sì tẹ̀dó síbẹ̀, níbẹ̀ ni Israẹli sì dó sí ní iwájú òkè ńlá.
- Eksodu 19:3nǹkan bí 1491 ṣáájú Kristi
Mose sì gòkè tọ Ọlọ́run lọ. Olúwa sì ké pè é láti orí òkè náà wá pé, “Èyí ni ìwọ yóò sọ fún ilé Jakọbu àti ohun tí ìwọ yóò sọ fún àwọn ọmọ Israẹli:
- Eksodu 19:4nǹkan bí 1491 ṣáájú Kristi
‘Ẹ̀yin ti rí ohun tí mo ti ṣe sí àwọn ará Ejibiti, àti bí mo ti gbé e yín ní apá ìyẹ́ idì.
- Eksodu 19:5nǹkan bí 1491 ṣáájú Kristi
Nísinsin yìí, bí ẹ̀yin bá ṣe ìgbọ́ràn sí mi dé ojú àmì, tí ẹ sì pa májẹ̀mú mi mọ́, nígbà náà ni ẹ̀yin ó jẹ́ ìṣúra fún mi ju gbogbo orílẹ̀-èdè yòókù lọ. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé gbogbo ayé ni tèmi.
- Eksodu 19:6nǹkan bí 1491 ṣáájú Kristi
Ẹ̀yin yóò sì máa jẹ́ ilẹ̀ ọba àwọn àlùfáà fún mi, orílẹ̀-èdè mímọ́.’ Ìwọ̀nyí ni ọ̀rọ̀ ti ìwọ yóò sọ fún àwọn ọmọ Israẹli.”
- Eksodu 19:7nǹkan bí 1491 ṣáájú Kristi
Mose sì tọ àwọn ènìyàn wá, ó sí pe àwọn àgbàgbà láàrín àwọn ènìyàn jọ. Ó sì gbé gbogbo ọ̀rọ̀ ti Olúwa pàṣẹ fún un láti sọ ní iwájú wọn.
- Eksodu 19:8nǹkan bí 1491 ṣáájú Kristi
Gbogbo àwọn ènìyàn náà sì pa ohùn wọn pọ̀ wọ́n sì dáhùn wí pé, “Àwa yóò ṣe ohun gbogbo ti Olúwa wí.” Mose sì mú ìdáhùn wọn padà tọ Olúwa lọ.
- Eksodu 19:9nǹkan bí 1491 ṣáájú Kristi
Olúwa sọ fún Mose pé, “Èmi yóò tọ̀ ọ́ wá nínú ìkùùkuu ṣíṣú dudu, kí àwọn ènìyàn lè gbọ́ ohùn mi nígbà ti mo bá ń bá ọ sọ̀rọ̀, kí wọn kí ó lè máa gbà ọ́ gbọ́.” Nígbà náà ni Mose sọ ohun tí àwọn ènìyàn wí fún Olúwa.
- Eksodu 19:10nǹkan bí 1491 ṣáájú Kristi
Olúwa sì wí fún Mose pé, “Tọ àwọn ènìyàn lọ kí o sì yà wọ́n sí mímọ́ ni òní àti ni ọ̀la. Jẹ́ kí wọn kí ó fọ aṣọ wọn.
- Eksodu 19:11nǹkan bí 1491 ṣáájú Kristi
Kí wọn kí ó sì múra di ọjọ́ kẹta, nítorí ni ọjọ́ náà ni Olúwa yóò sọ̀kalẹ̀ sí orí òkè Sinai ni ojú gbogbo àwọn ènìyàn.
- Eksodu 19:12nǹkan bí 1491 ṣáájú Kristi
Kí ìwọ kí ó ṣe ààlà fún àwọn ènìyàn, kí ìwọ kí ó sì wí fún wọn pé, ‘Ẹ kíyèsí ara yín, kí ẹ má ṣe gun orí òkè lọ, kí ẹ má tilẹ̀ fi ọwọ́ ba etí rẹ̀; ẹnikẹ́ni tí ó bá fi ọwọ́ kan òkè náà, ó dájú, pípa ni a ó pa á.
- Eksodu 19:13nǹkan bí 1491 ṣáájú Kristi
A ó sọ ọ́ ní òkúta tàbí kí a ta á ní ọfà, ọwọ́kọ́wọ́ kò gbọdọ̀ kàn án. Ìbá à ṣe ènìyàn tàbí ẹranko, òun kì yóò wà láààyè.’ Nígbà ti ìpè bá dún nìkan ni kí wọn ó gun òkè wá.”
- Eksodu 19:14nǹkan bí 1491 ṣáájú Kristi
Mose sì sọ̀kalẹ̀ láti orí òkè náà wá sí ọ̀dọ̀ àwọn ènìyàn, ó yà wọ́n sí mímọ́, wọ́n sì fọ aṣọ wọn.
- Eksodu 19:15nǹkan bí 1491 ṣáájú Kristi
Ó sì sọ fún àwọn ènìyàn pé, “Ẹ múra sílẹ̀ di ọjọ́ kẹta; ẹ má ṣe bá aya yín lòpọ̀.”
- Eksodu 19:16nǹkan bí 1491 ṣáájú Kristi
Ní òwúrọ̀ ọjọ́ kẹta, àrá àti mọ̀nàmọ́ná sì wà pẹ̀lú ìkùùkuu tí ó ṣú dudu ní orí òkè, ìpè ńlá sì dún kíkankíkan tó bẹ́ẹ̀ tí gbogbo àwọn tí ó wà ni ibùdó wárìrì.
- Eksodu 19:17nǹkan bí 1491 ṣáájú Kristi
Mose sì kó àwọn ènìyàn tí ó jáde láti ibùdó wá pàdé Ọlọ́run, wọ́n dúró nítòsí òkè.
- Eksodu 19:18nǹkan bí 1491 ṣáájú Kristi
Èéfín sì bo òkè Sinai nítorí Olúwa sọ̀kalẹ̀ sí orí rẹ̀ nínú iná. Èéfín náà sì ń ru sókè bí èéfín iná ìléru, gbogbo òkè náà sì mì tìtì.
- Eksodu 19:19nǹkan bí 1491 ṣáájú Kristi
Ohùn ìpè sì ń rinlẹ̀ dòdò. Mose sọ̀rọ̀, Ọlọ́run sì fi àrá dá a lóhùn.
- Eksodu 19:20nǹkan bí 1491 ṣáájú Kristi
Olúwa sọ̀kalẹ̀ sí orí òkè Sinai, o sì pe Mose wá sí orí òkè náà. Mose sì gun orí òkè.
- Eksodu 19:21nǹkan bí 1491 ṣáájú Kristi
Olúwa sọ fún Mose pé, “Sọ̀kalẹ̀, kí ó sì kìlọ̀ fún àwọn ènìyàn, kí wọn má ṣe fi tipátipá wá ọ̀nà láti wo Olúwa, bí wọn bá ṣe bẹ́ẹ̀, ọ̀pọ̀ wọn yóò ṣègbé.