Fò sí àkóónú

circa 1446 BC

Sinai & The Law

God meets Israel at Mount Sinai, reveals the Ten Commandments, and establishes the Tabernacle and the priestly covenant.

1,657 ẹsẹ · 2 ìwé tí a bo

Àwọn ẹsẹ láti sáà yìí

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Eksodu 19:22nǹkan bí 1491 ṣáájú Kristi

    Kódà àwọn àlùfáà tí ó ń wá síwájú Olúwa gbọdọ̀ ya ara wọn sí mímọ́ bí bẹ́ẹ̀ kọ́. Olúwa yóò kọlù wọ́n.”

  2. Eksodu 19:23nǹkan bí 1491 ṣáájú Kristi

    Mose wí fún Olúwa pé, “Àwọn ènìyàn kì yóò lè wá sí orí òkè Sinai, nítorí ìwọ fúnra rẹ̀ ti kìlọ̀ fún wa pé, ‘Ṣe ààlà yí òkè ká, kí o sì yà á sí mímọ́.’ ”

  3. Eksodu 19:24nǹkan bí 1491 ṣáájú Kristi

    Olúwa sì wí fún Mose pé, “Sọ̀kalẹ̀ lọ, mú Aaroni gòkè wá pẹ̀lú rẹ. Ṣùgbọ́n kí àwọn àlùfáà àti àwọn ènìyàn má ṣe fi tipátipá gòkè tọ Olúwa. Bí bẹ́ẹ̀ kọ́ yóò kọlù wọ́n.”

  4. Eksodu 19:25nǹkan bí 1491 ṣáájú Kristi

    Mose sọ̀kalẹ̀ tọ àwọn ènìyàn lọ. Ó sì sọ ohun tí Olúwa wí fún wọn.

  5. Eksodu 20:1nǹkan bí 1491 ṣáájú Kristi

    Ọlọ́run sì sọ gbogbo ọ̀rọ̀ yìí pé,

  6. Eksodu 20:2nǹkan bí 1491 ṣáájú Kristi

    “Èmi ni Olúwa Ọlọ́run yín, tí ó mú un yín jáde láti ilẹ̀ Ejibiti, láti oko ẹrú jáde wá.

  7. Eksodu 20:3nǹkan bí 1491 ṣáájú Kristi

    “Ìwọ kò gbọdọ̀ ní ọlọ́run mìíràn pẹ̀lú mi.

  8. Eksodu 20:4nǹkan bí 1491 ṣáájú Kristi

    Ìwọ kò gbọdọ̀ ṣe ère fún ara yín, tàbí àwòrán ohun kan tí ń bẹ ní òkè ọ̀run, tàbí ti ohun kan tí ń bẹ ní ìsàlẹ̀ ilẹ̀, tàbí ti ohun kan tí ń bẹ nínú omi ní ìsàlẹ̀ ilẹ̀.

  9. Eksodu 20:5nǹkan bí 1491 ṣáájú Kristi

    Ìwọ kò gbọdọ̀ tẹ orí ara rẹ ba fún wọn, bẹ́ẹ̀ ni ìwọ kò gbọdọ̀ sìn wọ́n; nítorí Èmi Olúwa Ọlọ́run rẹ, Ọlọ́run owú ni mí, tí ń bẹ ẹ̀ṣẹ̀ àwọn baba wò lára àwọn ọmọ, láti ìran kẹta títí dé ẹ̀kẹrin nínú àwọn tí ó kórìíra mi.

  10. Eksodu 20:6nǹkan bí 1491 ṣáájú Kristi

    Èmi a sì máa fi àánú hàn sí ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn tí ó fẹ́ mi, tí wọ́n sì ń pa òfin mi mọ́.

  11. Eksodu 20:7nǹkan bí 1491 ṣáájú Kristi

    Ẹ má ṣe ṣi orúkọ Olúwa Ọlọ́run yín lò, torí pé ẹnikẹ́ni tí o bá ṣi orúkọ rẹ̀ lò kì yóò lọ láìjẹ̀bi.

  12. Eksodu 20:8nǹkan bí 1491 ṣáájú Kristi

    Rántí ọjọ́ ìsinmi láti yà á sí mímọ́.

  13. Eksodu 20:9nǹkan bí 1491 ṣáájú Kristi

    Ọjọ́ mẹ́fà ni ìwọ yóò fi ṣiṣẹ́, kí ìwọ kí ó ṣe gbogbo iṣẹ́ rẹ,

  14. Eksodu 20:10nǹkan bí 1491 ṣáájú Kristi

    ṣùgbọ́n ọjọ́ keje ni ọjọ́ ìsinmi Olúwa Ọlọ́run rẹ: nínú rẹ̀ ìwọ kò gbọdọ̀ ṣe iṣẹ́kíṣẹ́ kan: ìwọ, àti ọmọ rẹ ọkùnrin àti ọmọ rẹ obìnrin, ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ ọkùnrin àti ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ obìnrin, àti ẹran ọ̀sìn rẹ, àti àlejò rẹ, tí ń bẹ nínú ibodè rẹ.

  15. Eksodu 20:11nǹkan bí 1491 ṣáájú Kristi

    Nítorí ní ọjọ́ mẹ́fà ni Olúwa dá ọ̀run àti ayé, òkun àti ohun gbogbo tí ń bẹ nínú wọn, ó sì sinmi ní ọjọ́ keje: nítorí náà ni Olúwa ṣe bùkún ọjọ́ ìsinmi tí ó sì yà á sí mímọ́.

  16. Eksodu 20:12nǹkan bí 1491 ṣáájú Kristi

    Bọ̀wọ̀ fún baba òun ìyá rẹ, kí ọjọ́ rẹ kí ó lè pẹ́ ní orí ilẹ̀ tí Olúwa Ọlọ́run rẹ fi fún ọ.

  17. Eksodu 20:13nǹkan bí 1491 ṣáájú Kristi

    Ìwọ kò gbọdọ̀ pànìyàn.

  18. Eksodu 20:14nǹkan bí 1491 ṣáájú Kristi

    Ìwọ kò gbọdọ̀ ṣe panṣágà.

  19. Eksodu 20:15nǹkan bí 1491 ṣáájú Kristi

    Ìwọ kò gbọdọ̀ jalè.

  20. Eksodu 20:16nǹkan bí 1491 ṣáájú Kristi

    Ìwọ kò gbọdọ̀ jẹ́rìí èké sí ẹnìkejì rẹ.

  21. Eksodu 20:17nǹkan bí 1491 ṣáájú Kristi

    Ìwọ kò gbọdọ̀ ṣe ojúkòkòrò sí ilé ẹnìkéjì rẹ. Ìwọ kò gbọdọ̀ ṣe ojúkòkòrò sí aya ẹnìkéjì rẹ, ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ̀ ọkùnrin àti ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ̀ obìnrin, akọ màlúù rẹ̀ àti kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ rẹ̀ àti ohun gbogbo tí í ṣe ti ẹnìkéjì rẹ.”

  22. Eksodu 20:18nǹkan bí 1491 ṣáájú Kristi

    Nígbà tí àwọn ènìyàn náà rí mọ̀nàmọ́ná tí wọ́n sí gbọ́ ohùn ìpè àti èéfín tí ń rú láti orí òkè, tí wọ́n sì gbọ́ sísán àrá, dídún ìpè kíkankíkan; wọ́n dúró ní òkèrè wọ́n sì ń gbọ̀n ṣìgàṣìgà fún ìbẹ̀rù.

  23. Eksodu 20:19nǹkan bí 1491 ṣáájú Kristi

    Wọ́n wí fún Mose pé, “Ìwọ fúnra rẹ̀ máa bá wa sọ̀rọ̀, àwa yóò sì gbọ́. Má ṣe jẹ́ kí Ọlọ́run fúnra rẹ̀ kí ó bá wa sọ̀rọ̀, bí bẹ́ẹ̀ kọ́, àwa yóò kú.”

  24. Eksodu 20:20nǹkan bí 1491 ṣáájú Kristi

    Mose sì sọ fún àwọn ènìyàn náà pé, “Ẹ má bẹ̀rù. Ọlọ́run wá láti dán an yín wò, kí ẹ̀rù Ọlọ́run kí ó lè máa wà ní ara yín, kí ẹ̀yin kí ó má ṣe ṣẹ̀.”

  25. Eksodu 20:21nǹkan bí 1491 ṣáájú Kristi

    Àwọn ènìyàn sì dúró ní òkèèrè nígbà tí Mose súnmọ́ ibi òkùnkùn biribiri níbi tí Ọlọ́run wà.