- English
- King James KJV
- Complete Jewish CJB
- World English WEBM
- Berean Standard BSB
- American Standard ASV
- Geneva GNV
- Young's Literal YLT
- Douay-Rheims DRC
- International
- Shqip ALB
- العربية SVD
- বাংলা BN-IRV
- မြန်မာ Judson
- 简体文 CUV-S
- 繁體中文 CUV-T
- Čeština BKR
- Nederlands STVE
- Français LSG
- Deutsch SCH
- Ελληνικά Vamvas
- ગુજરાતી GU-IRV
- Hausa HCB
- עברית Hebrew
- हिन्दी HCV
- Magyar KAROLI
- Bahasa Indonesia INDO-TB
- Italiano Diodati
- 日本語 Kougo
- 한국어 Korean
- മലയാളം MAL
- मराठी MRCV
- Norsk DNB
- فارسی OPV
- Polski BG
- Português Almeida
- Română Cornilescu
- Русский Synodal
- Español RVG
- Kiswahili Neno
- Svenska SV1917
- Tagalog TAG-ADB
- தமிழ் TCV
- తెలుగు TSA
- ภาษาไทย THAI-KJV
- Українська Ohienko
- Tiếng Việt CADMAN
- Yorùbá YCB
circa 1446 BC
Sinai & The Law
God meets Israel at Mount Sinai, reveals the Ten Commandments, and establishes the Tabernacle and the priestly covenant.
Àwọn ẹsẹ láti sáà yìí
- Eksodu 21:21nǹkan bí 1491 ṣáájú Kristi
Ṣùgbọ́n a kò ní fi ìyà jẹ ẹ́, ti ẹrú náà bá yè, tí ó dìde lẹ́yìn ọjọ́ kan tàbí méjì, nítorí ẹrú náà jẹ́ dúkìá rẹ̀.
- Eksodu 21:22nǹkan bí 1491 ṣáájú Kristi
“Bí àwọn ènìyàn ti ń jà bá pa aboyún lára, tí aboyún náà bá bímọ láìpé ọjọ́, ṣùgbọ́n tí kò sí aburú mìíràn mọ́ lẹ́yìn rẹ̀, ẹni tí ó fa ìpalára yìí yóò san iyekíye tí ọkọ aboyún náà bá béèrè fún, bí ilé ẹjọ́ bá ṣe gbà láààyè gẹ́gẹ́ bí owó ìtánràn.
- Eksodu 21:23nǹkan bí 1491 ṣáájú Kristi
Ṣùgbọ́n bí ìpalára náà bá yọrí sí ikú aboyún náà, pípa ni a ó pa ẹni ti ó fa ikú aboyún náà.
- Eksodu 21:24nǹkan bí 1491 ṣáájú Kristi
Ojú fún ojú, eyín fún eyín, ọwọ́ fún ọwọ́, ẹsẹ̀ fún ẹsẹ̀,
- Eksodu 21:25nǹkan bí 1491 ṣáájú Kristi
ìjóná fún ìjóná, ọgbẹ́ fún ọgbẹ́, ìnà fún ìnà.
- Eksodu 21:26nǹkan bí 1491 ṣáájú Kristi
“Bí ọkùnrin kan bá lu ẹrúkùnrin tàbí ẹrúbìnrin rẹ̀ ní ojú, ti ojú náà sì fọ́, ó ni láti jẹ́ kí ẹrú náà lọ ní òmìnira fún ìtánràn ojú rẹ̀ ti ó fọ́.
- Eksodu 21:27nǹkan bí 1491 ṣáájú Kristi
Bí ó bá sì lu ẹrúkùnrin tàbí ẹrúbìnrin rẹ̀ ti eyín rẹ̀ fi ká, ó ni láti jẹ́ kí ó lọ ní òmìnira ni ìtánràn fún eyín rẹ̀ tí ó ká.
- Eksodu 21:28nǹkan bí 1491 ṣáájú Kristi
“Bí akọ màlúù bá kan ọkùnrin tàbí obìnrin kan pa, a ó sọ akọ màlúù náà ní òkúta pa, a kò sì gbọdọ̀ jẹ ẹran rẹ̀. Ṣùgbọ́n a kò ní dá ẹni tí ó ni akọ màlúù náà lẹ́bi, ọrùn oní akọ màlúù náà yóò sì mọ́.
- Eksodu 21:29nǹkan bí 1491 ṣáájú Kristi
Ṣùgbọ́n tí ó bá ti di ìgbà gbogbo ti akọ màlúù náà ti máa ń kan ènìyàn, tí a sì ti ń kìlọ̀ fún olówó rẹ̀, ti olówó rẹ̀ kò sì mú un so, tí ó bá kan ọkùnrin tàbí obìnrin pa, a ó sọ akọ màlúù náà ní òkúta pa, a ó sì pa olówó rẹ̀ pẹ̀lú.
- Eksodu 21:30nǹkan bí 1491 ṣáájú Kristi
Bí àwọn ará ilé ẹni tí ó kú bá béèrè fún owó ìtánràn, yóò san iye owó tí wọ́n bá ní kí ó san fún owó ìtánràn láti fi ra ẹ̀mí ara rẹ̀ padà.
- Eksodu 21:31nǹkan bí 1491 ṣáájú Kristi
Bí akọ màlúù bá kan ọmọkùnrin tàbí ọmọbìnrin pa, a ó ṣe gẹ́gẹ́ bí òfin yìí ti là á kalẹ̀.
- Eksodu 21:32nǹkan bí 1491 ṣáájú Kristi
Bí akọ màlúù bá kan ẹrúkùnrin tàbí ẹrúbìnrin pa, olówó rẹ̀ yóò san ọgbọ̀n ṣékélì fàdákà fún ẹni tó ni ẹrú, a ó sì sọ akọ màlúù náà ni òkúta pa.
- Eksodu 21:33nǹkan bí 1491 ṣáájú Kristi
“Bí ọkùnrin kan bá ṣí kòtò sílẹ̀ láìbò tàbí kí ó gbẹ́ kòtò sílẹ̀ láìbò, tí màlúù tàbí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ bá ṣe bẹ́ẹ̀ bọ́ sínú kòtò náà.
- Eksodu 21:34nǹkan bí 1491 ṣáájú Kristi
Ẹni tí ó ni kòtò yóò san owó àdánù yìí fún ẹni tí ó ni ẹran. Òkú ẹran náà yóò sì di tirẹ̀.
- Eksodu 21:35nǹkan bí 1491 ṣáájú Kristi
“Bí akọ màlúù ọkùnrin kan bá pa akọ màlúù ẹlòmíràn lára tí ó sì kú, wọn yóò ta akọ màlúù tó wà láààyè, wọn yóò sì pín owó èyí tiwọn tà àti ẹran èyí tí ó kú dọ́gbadọ́gba.
- Eksodu 21:36nǹkan bí 1491 ṣáájú Kristi
Ṣùgbọ́n tí ó bá ti di ìgbà gbogbo tí akọ màlúù náà máa ń kan òmíràn, tí olówó rẹ̀ kò sì mú un so, olówó rẹ̀ yóò san ẹran dípò ẹran. Ẹran tí ó kú yóò sì jẹ́ tirẹ̀.
- Eksodu 22:1nǹkan bí 1491 ṣáájú Kristi
“Bí ọkùnrin kan bá jí akọ màlúù tàbí àgùntàn, tí ó sì pa á tàbí tà á. Ó gbọdọ̀ san akọ màlúù márùn-ún padà fún ọ̀kan tí ó jí, àti àgùntàn mẹ́rin mìíràn fún ọ̀kan tí ó jí.
- Eksodu 22:2nǹkan bí 1491 ṣáájú Kristi
“Bí a bá mú olè níbi ti ó ti ń fọ́lé, ti a sì lù ú pa, ẹni tí ó lù ú pa náà kò ní ẹ̀bi ìtàjẹ̀ sílẹ̀.
- Eksodu 22:3nǹkan bí 1491 ṣáájú Kristi
Ṣùgbọ́n ti ó bá ṣẹlẹ̀ ni ojú ọ̀sán, a ó kà á si ìpànìyàn. Ọkùnrin ti ó lù ú pa náà yóò ni ẹ̀bi ìtàjẹ̀ sílẹ̀. “Olè gbọdọ̀ san ohun tí ó jí padà. Ṣùgbọ́n tí kò bá ni ohun ti ó lè fi san án padà, a ó tà á, a ó sì fi sanwó ohun tí ó jí gbé padà.
- Eksodu 22:4nǹkan bí 1491 ṣáájú Kristi
Bí a bá rí ẹran tí ó jí gbé náà ni ọwọ́ rẹ̀ ní ààyè: ìbá ṣe akọ màlúù, akọ kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ tàbí àgùntàn, yóò san án padà ní ìlọ́po méjì.
- Eksodu 22:5nǹkan bí 1491 ṣáájú Kristi
“Bí ọkùnrin kan bá ń bọ́ ẹran ọ̀sìn rẹ̀ lórí pápá tàbí nínú ọgbà àjàrà, tí ó sì jẹ́ kí ó lọ jẹ nínú oko ẹlòmíràn, a ó mú kí ó san ohun ti ẹran rẹ̀ jẹ padà pẹ̀lú èyí tí ó dára jù nínú oko tàbí nínú ọgbà rẹ̀ (ẹlòmíràn padà fún un).
- Eksodu 22:6nǹkan bí 1491 ṣáájú Kristi
“Bí iná bá ṣẹ́ tí ó kán lu igbó tí ó sì jó àká ọkà tàbí gbogbo oko náà, ẹni tí iná ṣẹ́ lọ́wọ́ rẹ̀ yóò san ohun tí iná ti ó ṣẹ́ jó padà.
- Eksodu 22:7nǹkan bí 1491 ṣáájú Kristi
“Bí ọkùnrin kan bá fún aládùúgbò rẹ̀ ní fàdákà tàbí ohun èlò fún ìtọ́jú, ti wọ́n sì jí gbé lọ́dọ̀ aládùúgbò rẹ̀, tí a bá mú irú olè bẹ́ẹ̀, yóò san án padà ní ìlọ́po méjì.
- Eksodu 22:8nǹkan bí 1491 ṣáájú Kristi
Ṣùgbọ́n ti a kò bá rí olè náà mú, baálé ilé náà yóò fi ara hàn níwájú ìdájọ́ láti jẹ́ kí a mọ̀ bí òun fúnra rẹ̀ ni ó gbé ohun ti ó sọnù náà.
- Eksodu 22:9nǹkan bí 1491 ṣáájú Kristi
Bí ẹnìkan bá ni akọ màlúù, kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́, àgùntàn, aṣọ tàbí ohun ìní mìíràn tí ó sọnù ní ọ̀nà ti kò bá òfin mu, tí a sì rí ẹni ti ó sọ pé òun ni ó ní ín, àwọn méjèèjì yóò mú ẹjọ́ wọn wá sí iwájú adájọ́. Ẹnikẹ́ni tí adájọ́ bá dá lẹ́bi yóò san án ni ìlọ́po méjì padà fún ẹnìkejì rẹ̀.