Fò sí àkóónú

circa 1446 BC

Sinai & The Law

God meets Israel at Mount Sinai, reveals the Ten Commandments, and establishes the Tabernacle and the priestly covenant.

1,657 ẹsẹ · 2 ìwé tí a bo

Àwọn ẹsẹ láti sáà yìí

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Eksodu 22:10nǹkan bí 1491 ṣáájú Kristi

    “Bí ẹnikẹ́ni bá fún aládùúgbò rẹ̀ ní kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́, akọ màlúù, àgùntàn tàbí ẹranko mìíràn láti bá òun tọ́jú rẹ̀, tí ó sì kú, tàbí tí ó fi ara pa, tàbí tí a jí gbé, níbi tí kò ti sí ẹni tí o ṣe àkíyèsí.

  2. Eksodu 22:11nǹkan bí 1491 ṣáájú Kristi

    Wọn yóò búra sí ọ̀rọ̀ náà láàrín ara wọn ni iwájú Olúwa láti fihàn pé òun kò ní ọwọ́ nínú sísọnù ohun ọ̀sìn náà, olóhun gbọdọ̀ gba bẹ́ẹ̀, a kò sì ní san ohunkóhun fún un.

  3. Eksodu 22:12nǹkan bí 1491 ṣáájú Kristi

    Ṣùgbọ́n ti wọ́n bá jí ẹranko náà gbé ni ọ̀dọ̀ aládùúgbò rẹ̀, yóò san ẹ̀san padà fún olúwa rẹ̀.

  4. Eksodu 22:13nǹkan bí 1491 ṣáájú Kristi

    Bí ẹranko búburú bá fà á ya, ó ní láti mú àyakù ẹran náà wá gẹ́gẹ́ bí ẹ̀rí, kò sì ní san ẹran náà padà.

  5. Eksodu 22:14nǹkan bí 1491 ṣáájú Kristi

    “Bí ẹnìkan bá sì yá ẹranko lọ́dọ̀ aládùúgbò rẹ̀, tí ẹranko náà sì fi ara pa, tàbí kí ó kú nígbà tí ẹni tí ó ni í kò sí nítòsí. O gbọdọ̀ san án padà.

  6. Eksodu 22:15nǹkan bí 1491 ṣáájú Kristi

    Ṣùgbọ́n ti ó bá jẹ́ wí pé olóhun bá wà pẹ̀lú ẹranko náà, ẹni tí ó ya lò kò ní san ẹ̀san padà. Bí a bá yá ẹranko náà lò, owó tí ó fi yá a lò ni yóò fi tan àdánù ẹranko tí ó kú.

  7. Eksodu 22:16nǹkan bí 1491 ṣáájú Kristi

    “Bí ọkùnrin kan bá fi àrékérekè mú wúńdíá kan, ẹni tí kò pinnu láti fẹ́, tí ó sì bá a lòpọ̀, yóò san owó orí rẹ̀, yóò sì fi ṣe aya rẹ̀.

  8. Eksodu 22:17nǹkan bí 1491 ṣáájú Kristi

    Bí baba ọmọbìnrin náà bá kọ̀ jálẹ̀ láti fi fún un ní aya, ó ni láti san owó tó tó owó orí rẹ̀ fún fífẹ́ ẹ ní wúńdíá.

  9. Eksodu 22:18nǹkan bí 1491 ṣáájú Kristi

    “Má ṣe jẹ́ kí àjẹ́ kí ó wà láààyè.

  10. Eksodu 22:19nǹkan bí 1491 ṣáájú Kristi

    “Ẹnikẹ́ni ti ó bá bá ẹranko lòpọ̀ ní a ó pa.

  11. Eksodu 22:20nǹkan bí 1491 ṣáájú Kristi

    “Ẹnikẹ́ni ti ó bá rú ẹbọ sí òrìṣà yàtọ̀ sí Olúwa nìkan, ni a ó yà sọ́tọ̀ fún ìparun.

  12. Eksodu 22:21nǹkan bí 1491 ṣáájú Kristi

    “Ẹ má ṣe fi ìyà jẹ àlejò tàbí ni wọ́n lára, nítorí ìwọ pẹ̀lú ti jẹ́ àjèjì ni ilẹ̀ Ejibiti rí.

  13. Eksodu 22:22nǹkan bí 1491 ṣáájú Kristi

    “Má ṣe yan opó tàbí ọmọ òrukàn jẹ.

  14. Eksodu 22:23nǹkan bí 1491 ṣáájú Kristi

    Bí ìwọ bá ṣe bẹ́ẹ̀, bí wọn bá ké pè mi. Èmi yóò sì gbọ́ ohùn igbe wọn.

  15. Eksodu 22:24nǹkan bí 1491 ṣáájú Kristi

    Ìbínú mi yóò ru sókè. Èmi yóò sì fi idà pa ọ. Ìyàwó rẹ yóò di opó, àwọn ọmọ rẹ yóò sì di aláìní baba.

  16. Eksodu 22:25nǹkan bí 1491 ṣáájú Kristi

    “Bí ìwọ bá yá ọ̀kan nínú àwọn ènìyàn mi tí ìyà ń jẹ láàrín yín lówó, má ṣe dàbí ayánilówó, kí o má sì gba èlé.

  17. Eksodu 22:26nǹkan bí 1491 ṣáájú Kristi

    Bí ìwọ bá gba aṣọ aládùúgbò rẹ ni ẹ̀jẹ́, ìwọ gbọdọ̀ fún un padà kí oòrùn tó ó wọ̀,

  18. Eksodu 22:27nǹkan bí 1491 ṣáájú Kristi

    nítorí aṣọ yìí nìkan ní ó ní ti ó lè fi bo àṣírí ara. Kí ni ohun mìíràn ti yóò fi sùn? Nígbà ti ó bá gbé ohun rẹ̀ sókè sí mi, èmi yóò gbọ́ nítorí aláàánú ni èmi.

  19. Eksodu 22:28nǹkan bí 1491 ṣáájú Kristi

    “Ìwọ kò gbọdọ̀ sọ̀rọ̀-òdì sí Ọlọ́run tàbí gégùn lé orí ìjòyè àwọn ènìyàn rẹ.

  20. Eksodu 22:29nǹkan bí 1491 ṣáájú Kristi

    “Ìwọ kò gbọdọ̀ lọ́ra láti mú ọrẹ wá fún mi láti inú ìre oko rẹ àti láti inú wáìnì rẹ. “Àkọ́bí ọmọ rẹ ọkùnrin ni ìwọ yóò fi fún mi.

  21. Eksodu 22:30nǹkan bí 1491 ṣáájú Kristi

    Ṣe bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ pẹ̀lú agbo màlúù rẹ àti agbo àgùntàn rẹ. Jẹ́ kí wọn wà lọ́dọ̀ ìyá wọn fún ọjọ́ méje, kí ìwọ kí ó sì fi wọ́n fún mi ní ọjọ́ kẹjọ.

  22. Eksodu 22:31nǹkan bí 1491 ṣáájú Kristi

    “Ẹ̀yin yóò jẹ́ ènìyàn mímọ́ mi. Nítorí náà má ṣe jẹ ẹran ti ẹranko búburú fàya: ẹ fi fún ajá jẹ.

  23. Eksodu 23:1nǹkan bí 1491 ṣáájú Kristi

    “Ìwọ kò gbọdọ̀ tan ìròyìn èké kalẹ̀. Ìwọ kò gbọdọ̀ ran ènìyàn búburú lọ́wọ́ láti jẹ́rìí èké.

  24. Eksodu 23:2nǹkan bí 1491 ṣáájú Kristi

    “Ìwọ kò gbọdọ̀ tẹ̀lé ọ̀pọ̀ ènìyàn láti ṣe aburú. Nígbà tí ìwọ bá jẹ́rìí sí ẹjọ́, ìwọ kò gbọdọ̀ yí ìdájọ́ po nípa gbígbé lẹ́yìn ọ̀pọ̀ ènìyàn.

  25. Eksodu 23:3nǹkan bí 1491 ṣáájú Kristi

    Bẹ́ẹ̀ ni ìwọ kò gbọdọ̀ ṣe ojúsàájú sí tálákà nínú ẹjọ́ rẹ̀.