- English
- King James KJV
- Complete Jewish CJB
- World English WEBM
- Berean Standard BSB
- American Standard ASV
- Geneva GNV
- Young's Literal YLT
- Douay-Rheims DRC
- International
- Shqip ALB
- العربية SVD
- বাংলা BN-IRV
- မြန်မာ Judson
- 简体文 CUV-S
- 繁體中文 CUV-T
- Čeština BKR
- Nederlands STVE
- Français LSG
- Deutsch SCH
- Ελληνικά Vamvas
- ગુજરાતી GU-IRV
- Hausa HCB
- עברית Hebrew
- हिन्दी HCV
- Magyar KAROLI
- Bahasa Indonesia INDO-TB
- Italiano Diodati
- 日本語 Kougo
- 한국어 Korean
- മലയാളം MAL
- मराठी MRCV
- Norsk DNB
- فارسی OPV
- Polski BG
- Português Almeida
- Română Cornilescu
- Русский Synodal
- Español RVG
- Kiswahili Neno
- Svenska SV1917
- Tagalog TAG-ADB
- தமிழ் TCV
- తెలుగు TSA
- ภาษาไทย THAI-KJV
- Українська Ohienko
- Tiếng Việt CADMAN
- Yorùbá YCB
circa 1900–1700 BC
Jacob, Joseph & Egypt
Jacob wrestles with God and becomes Israel; Joseph is sold into slavery yet rises to save the world from famine.
Àwọn ẹsẹ láti sáà yìí
- Gẹnẹsisi 26:26nǹkan bí 1804 ṣáájú Kristi
Nígbà náà ni Abimeleki tọ̀ ọ́ wá láti Gerari, àti Ahussati, olùdámọ̀ràn rẹ̀ àti Fikoli, olórí ogun rẹ̀.
- Gẹnẹsisi 26:27nǹkan bí 1804 ṣáájú Kristi
Isaaki sì bi wọ́n léèrè pé, “Èéṣe tí ẹ̀yin tọ̀ mí wá, níwọ̀n ìgbà tí ẹ̀yin kórìíra mi tí ẹ sì lé mi jáde kúrò lọ́dọ̀ yín?”
- Gẹnẹsisi 26:28nǹkan bí 1804 ṣáájú Kristi
Wọ́n dáhùn pé, “A rí i dájú pé Olúwa wà pẹ̀lú rẹ, nítorí náà ni a fi rò ó wí pé, ó yẹ kí májẹ̀mú kí o wà láàrín àwa àti ìwọ. Jẹ́ kí a ṣe àdéhùn
- Gẹnẹsisi 26:29nǹkan bí 1804 ṣáájú Kristi
pé ìwọ kì yóò ṣe wá ní ibi, bí àwa pẹ̀lú kò ti ṣe ọ́ ní aburú, tí a sì ń ṣe ọ́ dáradára, tí a sì rán ọ jáde ní àlàáfíà láìṣe ọ́ ní ibi, kíyèsi Olúwa sì ti bùkún fún ọ.”
- Gẹnẹsisi 26:30nǹkan bí 1804 ṣáájú Kristi
Isaaki sì ṣe àsè fún wọn, wọn sì jẹ, wọ́n sì mu.
- Gẹnẹsisi 26:31nǹkan bí 1804 ṣáájú Kristi
Ní òwúrọ̀ ọjọ́ kejì wọn búra fún ara wọn. Isaaki sì rán wọn lọ, wọ́n sì lọ ní àlàáfíà.
- Gẹnẹsisi 26:32nǹkan bí 1804 ṣáájú Kristi
Ní ọjọ́ náà gan an ni àwọn ìránṣẹ́ Isaaki wá sọ fún un pé àwọn ti kan omi ní kànga kan tí àwọn gbẹ́.
- Gẹnẹsisi 26:33nǹkan bí 1804 ṣáájú Kristi
Ó sì pe orúkọ kànga náà ní Ṣiba, títí di òní olónìí, orúkọ ìlú náà ni Beerṣeba.
- Gẹnẹsisi 26:34nǹkan bí 1796 ṣáájú Kristi
Nígbà tí Esau pé ọmọ ogójì ọdún ó fẹ́ ọmọbìnrin kan tí a ń pè ní Juditi, ọmọ Beeri, ará Hiti, ó sì tún fẹ́ Basemati, ọmọ Eloni ará Hiti.
- Gẹnẹsisi 26:35nǹkan bí 1796 ṣáájú Kristi
Fífẹ́ tí a fẹ́ àwọn obìnrin wọ̀nyí jẹ́ ìbànújẹ́ fún Isaaki àti Rebeka.
- Gẹnẹsisi 27:1nǹkan bí 1760 ṣáájú Kristi
Nígbà ti Isaaki di arúgbó, ojú rẹ̀ sì ti di bàìbàì tó bẹ́ẹ̀ tí kò le ríran. Ó pe Esau àkọ́bí rẹ̀, ó sì wí fún un pé, “Ọmọ mi.” Esau sì dáhùn pé, “Èmi nìyí.”
- Gẹnẹsisi 27:2nǹkan bí 1760 ṣáájú Kristi
Isaaki sì wí pé, “Nísinsin yìí mo di arúgbó, èmi kò sì mọ ọjọ́ tí èmi yóò kú.
- Gẹnẹsisi 27:3nǹkan bí 1760 ṣáájú Kristi
Nítorí náà, mú ohun èlò ọdẹ rẹ, apó àti ọrún, nísinsin yìí kí o sì lọ pa ẹran wá fún mi nínú igbó.
- Gẹnẹsisi 27:4nǹkan bí 1760 ṣáájú Kristi
Kí o sì ṣe ẹran àdídùn fún mi, irú èyí tí mo fẹ́ràn, kí o gbe wá fún mi kí n jẹ, kí n sì súre fún ọ kí n tó kú.”
- Gẹnẹsisi 27:5nǹkan bí 1760 ṣáájú Kristi
Ṣùgbọ́n Rebeka ń fetí léko gbọ́ nígbà tí Isaaki ń bá Esau ọmọ rẹ̀ sọ̀rọ̀. Nítorí náà, nígbà ti Esau ti ṣe ọdẹ lọ sínú igbó,
- Gẹnẹsisi 27:6nǹkan bí 1760 ṣáájú Kristi
Rebeka sọ fún Jakọbu ọmọ rẹ̀ pé, “Wò ó, mo gbọ́ tí baba rẹ ń wí fún Esau ẹ̀gbọ́n rẹ pé,
- Gẹnẹsisi 27:7nǹkan bí 1760 ṣáájú Kristi
‘Pa ẹran fún mi wá, kí o sì ṣe oúnjẹ àdídùn fún mi láti jẹ, kí n ba à le súre fún ọ níwájú Olúwa kí èmi tó kú.’
- Gẹnẹsisi 27:8nǹkan bí 1760 ṣáájú Kristi
Nísinsin yìí ọmọ mi, gbọ́ tèmi, kí o sì ṣe ohun tí èmi yóò wí fún ọ.
- Gẹnẹsisi 27:9nǹkan bí 1760 ṣáájú Kristi
Lọ sínú agbo ẹran, kí o sì mú ọmọ ewúrẹ́ méjì, kí ó lè ṣe oúnjẹ àdídùn fún baba rẹ, irú èyí tí ó fẹ́ràn dáradára.
- Gẹnẹsisi 27:10nǹkan bí 1760 ṣáájú Kristi
Ìwọ yóò sì gbé e tọ baba rẹ lọ, kí òun ba à lè jẹ ẹ́, kí ó sì súre fún ọ, kí ó tó kú.”
- Gẹnẹsisi 27:11nǹkan bí 1760 ṣáájú Kristi
Jakọbu sì wí fún Rebeka ìyá rẹ̀ pé, “Ṣùgbọ́n Esau ẹ̀gbọ́n mi jẹ́ ènìyàn onírun lára, bẹ́ẹ̀ alára ọ̀bọ̀rọ́ sì ni èmi,
- Gẹnẹsisi 27:12nǹkan bí 1760 ṣáájú Kristi
bí baba mi bá fọwọ́ kàn mi ń kọ́? Èmi yóò jọ ẹlẹ́tàn lójú rẹ̀, dípò kí ó súre fún mi, èmi yóò sì mú ègún wá sórí ara mi.”
- Gẹnẹsisi 27:13nǹkan bí 1760 ṣáájú Kristi
Ìyá rẹ̀ wá wí fun un pé, “Ọmọ mi jẹ́ kí ègún náà wá sórí mi, sá à ṣe ohun tí mo wí, kí o sì mú wọn wá fún mi.”
- Gẹnẹsisi 27:14nǹkan bí 1760 ṣáájú Kristi
Jakọbu sì ṣe ohun gbogbo tí ìyá rẹ̀ wí fun un, Rebeka sì ṣe oúnjẹ àdídùn náà, irú èyí tí Isaaki fẹ́ràn.
- Gẹnẹsisi 27:15nǹkan bí 1760 ṣáájú Kristi
Nígbà náà ni Rebeka mú èyí tí ó dára jù nínú aṣọ Esau ọmọ rẹ̀ àgbà tí ó wà nínú ilé Rebeka, ó sì fi wọ Jakọbu ọmọ rẹ̀ àbúrò.