Fò sí àkóónú

circa 1900–1700 BC

Jacob, Joseph & Egypt

Jacob wrestles with God and becomes Israel; Joseph is sold into slavery yet rises to save the world from famine.

840 ẹsẹ · 1 ìwé tí a bo

Àwọn ẹsẹ láti sáà yìí

  1. Gẹnẹsisi 27:16nǹkan bí 1760 ṣáájú Kristi

    Ó sì fi awọ ewúrẹ́ wọ̀n-ọn-nì bo ọwọ́ àti ibi tí ọ̀bọ̀rọ́ ọrùn.

  2. Gẹnẹsisi 27:17nǹkan bí 1760 ṣáájú Kristi

    Nígbà náà ni ó gbé ẹran dídùn náà àti oúnjẹ tí ó ti sè lé Jakọbu ọmọ rẹ̀ lọ́wọ́.

  3. Gẹnẹsisi 27:18nǹkan bí 1760 ṣáájú Kristi

    Jakọbu wọlé lọ sí ọ̀dọ̀ baba rẹ̀ ó sì wí pé, “Baba mi.” Baba rẹ sì dáhùn pé, “Èmi nìyí, ìwọ ta ni, ọmọ mi?”

  4. Gẹnẹsisi 27:19nǹkan bí 1760 ṣáájú Kristi

    Jakọbu sì fèsì pé, “Èmi ni Esau àkọ́bí rẹ, èmi ti ṣe gẹ́gẹ́ bí ìwọ ti sọ fún mi, jọ̀wọ́ dìde jókòó, kí o sì jẹ nínú ẹran igbó mi tí mo ti sè, kí o ba à le súre fún mi pẹ̀lú gbogbo ọkàn rẹ.”

  5. Gẹnẹsisi 27:20nǹkan bí 1760 ṣáájú Kristi

    Isaaki tún béèrè pé, “Ọmọ mi, báwo ni ó ṣe tètè yá ọ bẹ́ẹ̀?” Jakọbu sì tún dáhùn pé, “Olúwa Ọlọ́run rẹ ló fún mi pa.”

  6. Gẹnẹsisi 27:21nǹkan bí 1760 ṣáájú Kristi

    Nígbà náà ni Isaaki wí fún Jakọbu pé, “Súnmọ́ mi, kí n le è fọwọ́ kàn ọ́, kí n lè mọ̀ bóyá Esau ọmọ mi ni nítòótọ́ tàbí òun kọ́.”

  7. Gẹnẹsisi 27:22nǹkan bí 1760 ṣáájú Kristi

    Jakọbu sì súnmọ́ Isaaki baba rẹ̀. Isaaki sì fọwọ́ kàn án, ó sì wí pé, “Ohùn ni ohùn Jakọbu; ṣùgbọ́n ọwọ́ ni ọwọ́ Esau.”

  8. Gẹnẹsisi 27:23nǹkan bí 1760 ṣáájú Kristi

    Kò sì dá Jakọbu mọ̀ nítorí ọwọ́ rẹ̀ ní irun bí i ti Esau arákùnrin rẹ, nítorí náà, ó súre fún un

  9. Gẹnẹsisi 27:24nǹkan bí 1760 ṣáájú Kristi

    ó sì bi í léèrè pé, “Ǹjẹ́ ìwọ ni Esau ọmọ mi ni tòótọ́?” Jakọbu sì dáhùn pé, “Èmi ni.”

  10. Gẹnẹsisi 27:25nǹkan bí 1760 ṣáájú Kristi

    Nígbà náà ni Isaaki wí pé, “Gbé ẹran igbó náà súnmọ́ ọ̀dọ̀ mi, kí èmi kí ó jẹ ẹ́, kí èmi sì súre fún ọ láti inú ọkàn mi wá.” Jakọbu sì gbé e wá ó sì jẹ ẹ́, ó sì tún fún un ní wáìnì, ó sì mú un pẹ̀lú.

  11. Gẹnẹsisi 27:26nǹkan bí 1760 ṣáájú Kristi

    Nígbà náà ni Isaaki baba rẹ̀ wí fun un pé, “Súnmọ́ mi, ọmọ mi, kí o sì fẹnukò mí ní ẹnu.”

  12. Gẹnẹsisi 27:27nǹkan bí 1760 ṣáájú Kristi

    Ó sì súnmọ́ ọn, ó sì fẹnukò ó ní ẹnu. Nígbà tí Isaaki gbọ́ òórùn aṣọ rẹ̀, ó súre fún un ó wí pé, “Wò ó òórùn ọmọ mi dàbí òórùn oko tí Olúwa ti bùkún.

  13. Gẹnẹsisi 27:28nǹkan bí 1760 ṣáájú Kristi

    Kí Ọlọ́run kí ó fún ọ nínú ìrì ọ̀run àti nínú ọ̀rá ilẹ̀ àti ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọkà àti wáìnì tuntun.

  14. Gẹnẹsisi 27:29nǹkan bí 1760 ṣáájú Kristi

    Kí àwọn orílẹ̀-èdè kí ó máa sìn ọ́, kí àwọn ènìyàn sì máa tẹríba fún ọ, máa ṣe olórí àwọn arákùnrin rẹ, kí àwọn iyèkan rẹ sì máa wólẹ̀ fún ọ Fífibú ni àwọn ẹni tó fi ọ́ bú, ìbùkún ni fún àwọn ẹni tí ó súre fún ọ.”

  15. Gẹnẹsisi 27:30nǹkan bí 1760 ṣáájú Kristi

    Bí Isaaki ti súre tán tí Jakọbu ṣẹ̀ṣẹ̀ jáde kúrò ní ọ̀dọ̀ baba rẹ̀ ni Esau ti oko ọdẹ dé.

  16. Gẹnẹsisi 27:31nǹkan bí 1760 ṣáájú Kristi

    Òun pẹ̀lú ṣe ẹran dídùn, ó sì gbé e tọ baba rẹ̀ wá, ó sì wí fún un pé, “Baba mi, dìde jókòó, kí o sì jẹ nínú ẹran igbó tí mo ti ṣè, kí o sì súre fún mi.”

  17. Gẹnẹsisi 27:32nǹkan bí 1760 ṣáájú Kristi

    Isaaki baba rẹ̀ sì bi í wí pé, “Ìwọ ta ni?” Ó sì dáhùn pé, “Èmi Esau, àkọ́bí rẹ ni.”

  18. Gẹnẹsisi 27:33nǹkan bí 1760 ṣáájú Kristi

    Nígbà náà ni Isaaki wárìrì gidigidi, ó sì wí pé, “Ta ni ẹni náà, tí ó ti pa ẹran igbó tí ó sì ti gbe wá fún mi, tí mo sì ti jẹ ẹ́ kí ó tó dé? Mo sì ti súre fún un, sì wò ó dájúdájú a ó sì bùkún un!”

  19. Gẹnẹsisi 27:34nǹkan bí 1760 ṣáájú Kristi

    Nígbà tí Esau gbọ́ ọ̀rọ̀ baba rẹ̀, ó ké, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí ní sọkún kíkorò, ó sì wí fún baba rẹ̀ pé, “Baba mi súre fún èmi náà, àní fún èmi náà pẹ̀lú.”

  20. Gẹnẹsisi 27:35nǹkan bí 1760 ṣáájú Kristi

    Ṣùgbọ́n Isaaki wí pé, “Àbúrò rẹ ti fi ẹ̀tàn wá, ó sì ti gba ìbùkún rẹ lọ.”

  21. Gẹnẹsisi 27:36nǹkan bí 1760 ṣáájú Kristi

    Esau sì wí pé, “Lásán ni a pe orúkọ rẹ̀ ní Jakọbu bí? Ní ìgbà méjì yìí ni ó ti tàn mí jẹ: ní àkọ́kọ́, ó gba ogún ìbí mi, nísinsin yìí, ó tún gba ìbùkún mi!” O sì béèrè pé, “Ṣe o kò wá fi ìre kankan sílẹ̀ fun mi ni?”

  22. Gẹnẹsisi 27:37nǹkan bí 1760 ṣáájú Kristi

    Isaaki sì dá Esau lóhùn pé, “Mo ti fi ṣe olórí rẹ àti àwọn ìbátan rẹ ni mo fi ṣe ìránṣẹ́ fún un, àti ọkà àti wáìnì ni mo ti fi lé e lọ́wọ́ lọ́pọ̀lọ́pọ̀, kí ni ó tún kù tí ǹ bá tún fún ọ báyìí ọmọ mi?”

  23. Gẹnẹsisi 27:38nǹkan bí 1760 ṣáájú Kristi

    Esau sì wí fún baba rẹ̀ pé, “Ṣe ìre kan ṣoṣo ni ìwọ ní lẹ́nu ni baba mi? Súre fún èmi náà, baba mi.” Esau sì sọkún kíkankíkan.

  24. Gẹnẹsisi 27:39nǹkan bí 1760 ṣáájú Kristi

    Isaaki baba rẹ̀ sì dá a lóhùn pé, “Ibùjókòó rẹ yóò jìnnà sí ọ̀rá ilẹ̀, àti sí ibi ìrì ọ̀run láti òkè wá.

  25. Gẹnẹsisi 27:40nǹkan bí 1760 ṣáájú Kristi

    Nípa idà rẹ ni ìwọ yóò máa gbé, ìwọ yóò sì máa sin àbúrò rẹ, ṣùgbọ́n ní ìkẹyìn, nígbà tí ìwọ bá di alágbára ìwọ yóò já àjàgà rẹ̀ kúrò lọ́rùn rẹ.”