Fò sí àkóónú

circa 1900–1700 BC

Jacob, Joseph & Egypt

Jacob wrestles with God and becomes Israel; Joseph is sold into slavery yet rises to save the world from famine.

840 ẹsẹ · 1 ìwé tí a bo

Àwọn ẹsẹ láti sáà yìí

  1. Gẹnẹsisi 27:41nǹkan bí 1760 ṣáájú Kristi

    Esau sì kórìíra Jakọbu nítorí ìre tí baba rẹ̀ sú fún un, ó sì wí fún ara rẹ̀ pé, “Baba mi sá à ti fẹ́rẹ kú, nígbà náà ni èmi ó pa Jakọbu, arákùnrin mi.”

  2. Gẹnẹsisi 27:42nǹkan bí 1760 ṣáájú Kristi

    Nígbà tí Rebeka sì gbọ́ ohun tí Esau àkọ́bí rẹ̀ wí, ó sì ránṣẹ́ sí Jakọbu, ó sì wí fun un pé, “Esau ẹ̀gbọ́n rẹ ń tu ara rẹ̀ nínú pẹ̀lú èrò à ti pa ọ́.

  3. Gẹnẹsisi 27:43nǹkan bí 1760 ṣáájú Kristi

    Nítorí náà ọmọ mi, ṣe ohun tí èmi yóò sọ fún ọ, sálọ sọ́dọ̀ Labani ẹ̀gbọ́n mi ní Harani.

  4. Gẹnẹsisi 27:44nǹkan bí 1760 ṣáájú Kristi

    Jókòó sí ibẹ̀ títí di ìgbà tí ìbínú ẹ̀gbọ́n rẹ yóò fi rọ̀.

  5. Gẹnẹsisi 27:45nǹkan bí 1760 ṣáájú Kristi

    Nígbà tí ẹ̀gbọ́n rẹ kò bá bínú sí ọ mọ́, tí ó sì ti gbàgbé ohun tí ìwọ ṣe sí i, èmí ó ránṣẹ́ sí ọ láti padà wá. Èéṣe tí èmi ó fi pàdánù ẹ̀yin méjèèjì ní ọjọ́ kan náà?”

  6. Gẹnẹsisi 27:46nǹkan bí 1760 ṣáájú Kristi

    Nígbà náà ni Rebeka wí fún Isaaki pé, “Ayé sì sú mi nítorí àwọn ọmọbìnrin Hiti wọ̀nyí. Bí Jakọbu bá fẹ́ ọ̀kan nínú àwọn ọmọbìnrin Hiti wọ̀nyí, ó kúkú sàn kí n má wà láààyè.”

  7. Gẹnẹsisi 28:1nǹkan bí 1760 ṣáájú Kristi

    Nítorí náà Isaaki pe Jakọbu, ó sì súre fún un, ó sì pàṣẹ fún un pé, “Ìwọ kò gbọdọ̀ fẹ́ aya láàrín àwọn ọmọbìnrin Kenaani.

  8. Gẹnẹsisi 28:2nǹkan bí 1760 ṣáájú Kristi

    Dípò bẹ́ẹ̀ lọ sí Padani-Aramu, sí ilé Betueli, baba ìyá rẹ, kí ìwọ kí ó sì fẹ́ aya fún ara rẹ nínú àwọn ọmọbìnrin Labani arákùnrin ìyá rẹ.

  9. Gẹnẹsisi 28:3nǹkan bí 1760 ṣáájú Kristi

    Kí Ọlọ́run Olódùmarè El-Ṣaddai kí ó bùkún fún ọ, kí ó sì mú ọ bí sí i, kí ó sì mú ọ pọ̀ sí i ní iye títí tí ìwọ yóò di àgbájọ àwọn ènìyàn.

  10. Gẹnẹsisi 28:4nǹkan bí 1760 ṣáájú Kristi

    Kí Ọlọ́run kí ó fún ìwọ àti irú-ọmọ rẹ ní ìre tí ó sú fún Abrahamu, kí ìwọ kí ó le gba ilẹ̀ níbi tí a ti ń ṣe àtìpó yìí, ilẹ̀ tí Ọlọ́run ti fi fún Abrahamu.”

  11. Gẹnẹsisi 28:5nǹkan bí 1760 ṣáájú Kristi

    Bẹ́ẹ̀ ni Isaaki sì rán Jakọbu lọ. Ó sì lọ sí Padani-Aramu, lọ́dọ̀ Labani ọmọ Betueli, ará Aramu, tí í ṣe arákùnrin Rebeka ìyá Jakọbu àti Esau.

  12. Gẹnẹsisi 28:6nǹkan bí 1760 ṣáájú Kristi

    Nígbà tí Esau gbọ́ pé, Isaaki ti súre fún Jakọbu, ó sì ti rán Jakọbu lọ sí Padani-Aramu láti fẹ́ aya níbẹ̀ àti pé nígbà tí ó súre fún un, ó kìlọ̀ fun un pé, kò gbọdọ̀ fẹ́ nínú àwọn ọmọbìnrin Kenaani

  13. Gẹnẹsisi 28:7nǹkan bí 1760 ṣáájú Kristi

    àti pé, Jakọbu ti gbọ́rọ̀ sí ìyá àti baba rẹ̀ lẹ́nu, ó sì ti lọ sí Padani-Aramu.

  14. Gẹnẹsisi 28:8nǹkan bí 1760 ṣáájú Kristi

    Nígbà náà ni Esau mọ bí Isaaki baba rẹ ti kórìíra àwọn ọmọbìnrin Kenaani tó.

  15. Gẹnẹsisi 28:9nǹkan bí 1760 ṣáájú Kristi

    Nítorí náà Esau tọ Iṣmaeli lọ, ó sì fẹ́ Mahalati, arábìnrin Nebaioti, ọmọbìnrin Iṣmaeli tí í ṣe ọmọ Abrahamu. Ó fẹ́ ẹ, kún àwọn ìyàwó tí ó ti ní tẹ́lẹ̀.

  16. Gẹnẹsisi 28:10nǹkan bí 1760 ṣáájú Kristi

    Jakọbu kúrò ní Beerṣeba, ó sì kọrí sí ìlú Harani.

  17. Gẹnẹsisi 28:11nǹkan bí 1760 ṣáájú Kristi

    Nígbà tí ó dé ibìkan, ó dúró ní òru náà nítorí tí ilẹ̀ ti ń ṣú, ó sì gbé òkúta kan ó fi ṣe ìrọ̀rí, ó sì sùn.

  18. Gẹnẹsisi 28:12nǹkan bí 1760 ṣáájú Kristi

    Ó sì lá àlá pé, a gbé àkàsọ̀ kan dúró ti ó fi ìdí lélẹ̀, orí rẹ̀ sì kan ọ̀run, àwọn angẹli Ọlọ́run sì ń gòkè, wọ́n sì ń sọ̀kalẹ̀ lórí rẹ̀.

  19. Gẹnẹsisi 28:13nǹkan bí 1760 ṣáájú Kristi

    Olúwa sì dúró lókè rẹ̀, ó sì wí pé, “Èmi ni Olúwa, Ọlọ́run baba rẹ Abrahamu àti Ọlọ́run Isaaki, ìwọ àti ìran rẹ ni èmi yóò fi ilẹ̀ tí ìwọ dùbúlẹ̀ sórí rẹ̀ yìí fún.

  20. Gẹnẹsisi 28:14nǹkan bí 1760 ṣáájú Kristi

    Ìran rẹ yóò pọ̀ bí erùpẹ̀ ilẹ̀, ìwọ yóò sì tànkálẹ̀ dé ìlà-oòrùn àti ìwọ̀-oòrùn, àti dé gúúsù àti àríwá. A ó sì bùkún gbogbo orílẹ̀-èdè ayé nípasẹ̀ ìwọ àti àwọn ọmọ rẹ.

  21. Gẹnẹsisi 28:15nǹkan bí 1760 ṣáájú Kristi

    Èmi wà pẹ̀lú rẹ, èmi yóò sì pa ọ mọ́ ní ibikíbi tí ìwọ bá lọ, èmi yóò sì mú ọ padà wá sí ilẹ̀ yìí ní àlàáfíà. Èmi kì yóò fi ọ sílẹ̀ ní ìgbà kan, títí tí èmi yóò fi mú gbogbo ìlérí mi ṣẹ.”

  22. Gẹnẹsisi 28:16nǹkan bí 1760 ṣáájú Kristi

    Nígbà tí Jakọbu jí lójú oorun rẹ̀, ó rò nínú ara rẹ̀ pé, “Dájúdájú Olúwa ń bẹ ní ìhín yìí, èmi kò sì mọ̀.”

  23. Gẹnẹsisi 28:17nǹkan bí 1760 ṣáájú Kristi

    Ẹ̀rù sì bà á, ó sì wí pé, “Ìhín yìí ní ẹ̀rù gidigidi; ibí kì í ṣe ibòmíràn bí kò ṣe ilé Ọlọ́run, àní ẹnu ibodè ọ̀run nìyìí.”

  24. Gẹnẹsisi 28:18nǹkan bí 1760 ṣáájú Kristi

    Jakọbu sì dìde ní kùtùkùtù òwúrọ̀, ó sì gbé òkúta tí ó fi ṣe ìrọ̀rí lélẹ̀ bí ọ̀wọ́n, ó sì da òróró si lórí.

  25. Gẹnẹsisi 28:19nǹkan bí 1760 ṣáájú Kristi

    Ó sì pe orúkọ ibẹ̀ ní Beteli, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ìlú náà ń jẹ́ Lusi tẹ́lẹ̀ rí.