Fò sí àkóónú

circa 1900–1700 BC

Jacob, Joseph & Egypt

Jacob wrestles with God and becomes Israel; Joseph is sold into slavery yet rises to save the world from famine.

840 ẹsẹ · 1 ìwé tí a bo

Àwọn ẹsẹ láti sáà yìí

  1. Gẹnẹsisi 37:10nǹkan bí 1728 ṣáájú Kristi

    Nígbà tí ó sọ fún baba rẹ̀ àti àwọn arákùnrin rẹ̀ pẹ̀lú, baba rẹ̀ bá a wí pé, “Irú àlá wo ni ìwọ lá yìí? Ṣé ìyá rẹ, pẹ̀lú èmi àti àwọn ẹ̀gbọ́n rẹ yóò wá foríbalẹ̀ níwájú rẹ ni?”

  2. Gẹnẹsisi 37:11nǹkan bí 1728 ṣáájú Kristi

    Àwọn arákùnrin rẹ̀ sì ń ṣe ìlara rẹ̀ ṣùgbọ́n baba rẹ̀ pa ọ̀rọ̀ náà mọ́ lọ́kàn rẹ̀.

  3. Gẹnẹsisi 37:12nǹkan bí 1728 ṣáájú Kristi

    Àwọn arákùnrin rẹ̀ sì da ẹran baba wọn lọ sí Ṣekemu.

  4. Gẹnẹsisi 37:13nǹkan bí 1728 ṣáájú Kristi

    Israẹli sì wí fún Josẹfu pé, “Ṣé o mọ̀ pé, àwọn arákùnrin rẹ ń da ẹran ní Ṣekemu, wá, jẹ́ kí n rán ọ sí wọn.” Josẹfu sì dáhùn pé, “Èmi nìyí.”

  5. Gẹnẹsisi 37:14nǹkan bí 1728 ṣáájú Kristi

    O sì wí fún un pé, “Lọ wò bí àwọn arákùnrin rẹ àti àwọn agbo ẹran bá wà ní àlàáfíà, kí o sì wá jíṣẹ́ fún mi.” Ó sì rán Josẹfu lọ láti àfonífojì Hebroni. Nígbà tí Josẹfu dé Ṣekemu,

  6. Gẹnẹsisi 37:15nǹkan bí 1728 ṣáájú Kristi

    ọkùnrin kan sì rí i tí ó ń rìn kiri inú pápá, ó sì bi í pé, “Kín ni ò ń wá?”

  7. Gẹnẹsisi 37:16nǹkan bí 1728 ṣáájú Kristi

    Ó sì dáhùn pé, “Àwọn arákùnrin mi ni mò ń wá, ǹjẹ́ o mọ ibi tí wọ́n wà pẹ̀lú agbo ẹran?”

  8. Gẹnẹsisi 37:17nǹkan bí 1728 ṣáájú Kristi

    Ọkùnrin náà dáhùn pé, “Wọ́n ti kúrò ní ìhín, mo gbọ́ tí wọ́n ń wí pé, ‘Ẹ jẹ́ kí a lọ sí Dotani.’ ” Josẹfu sì wá àwọn arákùnrin rẹ̀ lọ, ó sì rí wọn ní tòsí Dotani.

  9. Gẹnẹsisi 37:18nǹkan bí 1728 ṣáájú Kristi

    Ṣùgbọ́n bí wọ́n sì ti rí i tí ń bọ̀ lókèèrè, kí ó sì tó dé ọ̀dọ̀ wọn, wọn gbìmọ̀ pọ̀ láti pa á.

  10. Gẹnẹsisi 37:19nǹkan bí 1728 ṣáájú Kristi

    “Alálàá ni ń bọ̀ yìí,” ni wọ́n ń wí fún ara wọn.

  11. Gẹnẹsisi 37:20nǹkan bí 1728 ṣáájú Kristi

    “Ẹ wá, ẹ jẹ́ kí a pa á. Kí a sì ju òkú rẹ̀ sínú kòtò, a ó sì wí pé, ẹranko búburú ni ó pa á, kí a máa wo ọ̀nà tí àlá rẹ̀ yóò gbà ṣẹ.”

  12. Gẹnẹsisi 37:21nǹkan bí 1728 ṣáájú Kristi

    Nígbà tí Reubeni gbọ́ èyí, ó gbìyànjú láti gbà á sílẹ̀ ní ọwọ́ wọn, ó sì wí pé, “Ẹ má ṣe jẹ́ kí a gba ẹ̀mí rẹ̀,

  13. Gẹnẹsisi 37:22nǹkan bí 1728 ṣáájú Kristi

    ẹ má ṣe jẹ́ kí a ta ẹ̀jẹ̀ sílẹ̀, ẹ má ṣe fọwọ́ kàn án, ẹ kúkú jù ú sínú kòtò láààyè nínú aginjù níbí.” Reubeni sọ èyí, kí ó ba à le gbà á kúrò lọ́wọ́ wọn, kí ó sì dá a padà lọ fún baba rẹ̀.

  14. Gẹnẹsisi 37:23nǹkan bí 1728 ṣáájú Kristi

    Nítorí náà, nígbà tí Josẹfu dé ọ̀dọ̀ àwọn arákùnrin rẹ̀, wọ́n bọ́ ẹ̀wù rẹ̀—Ẹ̀wù ọlọ́nà, aláràbarà tí ó wọ̀—

  15. Gẹnẹsisi 37:24nǹkan bí 1728 ṣáájú Kristi

    wọ́n mú un, wọ́n sì jù ú sínú kòtò. Kòtò náà sì ṣófo, kò sí omi nínú rẹ̀.

  16. Gẹnẹsisi 37:25nǹkan bí 1728 ṣáájú Kristi

    Bí wọ́n sì ti jókòó láti jẹun, wọ́n gbójú sókè, wọ́n sì rí àwọn oníṣòwò ará Iṣmaeli tí wọ́n ń wọ́ bọ̀ láti Gileadi. Ìbákasẹ wọn sì ru tùràrí, ìkunra àti òjìá, wọ́n ń lọ sí Ejibiti.

  17. Gẹnẹsisi 37:26nǹkan bí 1728 ṣáájú Kristi

    Juda wí fún àwọn arákùnrin rẹ̀ pé, “Èrè kí ni ó jẹ́ bí a bá pa arákùnrin wa tí a bo ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ mọ́lẹ̀ ti ọkàn wa sì ń dá wa lẹ́bi?

  18. Gẹnẹsisi 37:27nǹkan bí 1728 ṣáájú Kristi

    Ẹ wá, ẹ jẹ́ kí á tà á fún àwọn ará Iṣmaeli, kí àwa má sì pa á, ṣè bí àbúrò wa ni, ẹran-ara wa àti ẹ̀jẹ̀ wa ní i ṣe.” Àwọn arákùnrin rẹ̀ sì fi ara mọ́ ohun tí ó sọ.

  19. Gẹnẹsisi 37:28nǹkan bí 1728 ṣáájú Kristi

    Nítorí náà, nígbà tí àwọn oníṣòwò ara Midiani ń kọjá, àwọn arákùnrin Josẹfu fà á jáde láti inú kòtò, wọ́n sì tà á fún àwọn ará Iṣmaeli ní ogún owó wúrà, wọ́n sì mú Josẹfu lọ sí ilẹ̀ Ejibiti.

  20. Gẹnẹsisi 37:29nǹkan bí 1728 ṣáájú Kristi

    Nígbà tí Reubeni padà dé ibi kòtò tí ó sì ri pé Josẹfu kò sí níbẹ̀ mọ́, ó fa aṣọ rẹ̀ ya pẹ̀lú ìbànújẹ́.

  21. Gẹnẹsisi 37:30nǹkan bí 1728 ṣáájú Kristi

    Ó padà lọ sí ọ̀dọ̀ àwọn arákùnrin rẹ̀, ó sì wí pé, “Ọmọdékùnrin náà kò sí níbẹ̀ mọ́! Níbo ni ẹ fẹ́ kí n wọ̀ báyìí?”

  22. Gẹnẹsisi 37:31nǹkan bí 1728 ṣáájú Kristi

    Nígbà náà ni wọ́n mú aṣọ Josẹfu, wọ́n pa ewúrẹ́ kan, wọ́n sì tẹ aṣọ náà bọ inú ẹ̀jẹ̀ ewúrẹ́ náà.

  23. Gẹnẹsisi 37:32nǹkan bí 1728 ṣáájú Kristi

    Wọ́n sì mú aṣọ ọlọ́nà aláràbarà náà padà sí ọ̀dọ̀ baba wọn, wọ́n sì wí pé, “A rí èyí he nínú oko, yẹ̀ ẹ́ wò, kí o sì mọ̀ bóyá ti ọmọ rẹ ni.”

  24. Gẹnẹsisi 37:33nǹkan bí 1728 ṣáájú Kristi

    Ó sì dá a mọ̀, ó wí pé, “Háà! Aṣọ ọmọ mi ni, ẹranko búburú ti pa á jẹ, láìṣe àní àní, ó ti fa Josẹfu ya pẹ́rẹpẹ̀rẹ.”

  25. Gẹnẹsisi 37:34nǹkan bí 1728 ṣáájú Kristi

    Nígbà náà ni Jakọbu fa aṣọ rẹ̀ ya, ó sì wọ aṣọ ọ̀fọ̀, ó sì ṣọ̀fọ̀ ọmọ rẹ̀ fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọjọ́.