Fò sí àkóónú

circa 1900–1700 BC

Jacob, Joseph & Egypt

Jacob wrestles with God and becomes Israel; Joseph is sold into slavery yet rises to save the world from famine.

840 ẹsẹ · 1 ìwé tí a bo

Àwọn ẹsẹ láti sáà yìí

  1. Gẹnẹsisi 38:24nǹkan bí 1722 ṣáájú Kristi

    Lẹ́yìn nǹkan bí oṣù mẹ́ta, wọn sọ fún Juda pé, “Tamari aya ọmọ rẹ̀ ṣe àgbèrè, ó sì ti lóyún.” Juda sì wí pé, “Ẹ mú un jáde, kí ẹ sì dá iná sun ún.”

  2. Gẹnẹsisi 38:25nǹkan bí 1722 ṣáájú Kristi

    Bí wọ́n sì ti ń mú un jáde, ó ránṣẹ́ sí baba ọkọ rẹ̀ pé, “Ọkùnrin tí ó ni àwọn nǹkan wọ̀nyí ni ó fún mi lóyún. Wò ó, bóyá o lè mọ ẹni tí ó ni èdìdì ìdámọ̀, okùn àti ọ̀pá ìtìlẹ̀ wọ̀nyí.”

  3. Gẹnẹsisi 38:26nǹkan bí 1722 ṣáájú Kristi

    Juda sì dá wọn mọ̀, ó sì wí pé, “O ṣe olódodo jù mí lọ, níwọ̀n ìgbà tí n kò fi fún Ṣela ọmọ mi.” Kò sì bá a lòpọ̀ mọ́ láti ọjọ́ náà.

  4. Gẹnẹsisi 38:27nǹkan bí 1722 ṣáájú Kristi

    Nígbà tí àsìkò ìbímọ rẹ̀ tó. Ìbejì ọkùnrin ni ó bí.

  5. Gẹnẹsisi 38:28nǹkan bí 1722 ṣáájú Kristi

    Bí ó sì ti ń bímọ, ọ̀kan nínú àwọn ọmọ náà na ọwọ́ jáde; agbẹ̀bí sì so okùn òdòdó mọ́ ọmọ náà ní ọrùn ọwọ́. Ó sì wí pé, “Èyí ni o kọ́kọ́ jáde.”

  6. Gẹnẹsisi 38:29nǹkan bí 1721 ṣáájú Kristi

    Ṣùgbọ́n nígbà tí ó fa ọwọ́ rẹ̀ padà, èkejì rẹ̀ jáde. Tamari sì wí pé, “Níbo ni ìwọ ti wá?” Ó sì pe orúkọ rẹ̀ ní Peresi.

  7. Gẹnẹsisi 38:30nǹkan bí 1721 ṣáájú Kristi

    Nígbà náà ni èkejì tí a ti so okùn olódòdó mọ́ lọ́rùn ọwọ́ jáde, wọ́n sì pe orúkọ rẹ̀ ni Sera.

  8. Gẹnẹsisi 39:1nǹkan bí 1728 ṣáájú Kristi

    Nígbà tí wọ́n mú Josẹfu dé Ejibiti, Potifari, ará Ejibiti tí i ṣe ọ̀kan nínú àwọn ìjòyè Farao. Òun ni olórí àwọn ọmọ-ogun Farao. Ó ra Josẹfu lọ́wọ́ àwọn ará Iṣmaeli tí wọ́n mú un lọ síbẹ̀.

  9. Gẹnẹsisi 39:2nǹkan bí 1728 ṣáájú Kristi

    Olúwa sì wà pẹ̀lú Josẹfu, ó sì bùkún un, ó sì ń gbé ní ilé ọ̀gá rẹ̀ ará Ejibiti.

  10. Gẹnẹsisi 39:3nǹkan bí 1728 ṣáájú Kristi

    Nígbà tí ọ̀gá rẹ̀ rí i pé Olúwa wà pẹ̀lú rẹ̀, àti pé Olúwa jẹ́ kí ó máa ṣe àṣeyọrí nínú ohun gbogbo tí ó dáwọ́ rẹ̀ lé.

  11. Gẹnẹsisi 39:4nǹkan bí 1728 ṣáájú Kristi

    Josẹfu sì rí ojúrere Potifari, ó sì di aṣojú rẹ̀, Potifari fi Josẹfu ṣe olórí ilé rẹ̀ àti ohun gbogbo tí ó ní.

  12. Gẹnẹsisi 39:5nǹkan bí 1728 ṣáájú Kristi

    Láti ìgbà tí ó ti fi Josẹfu jẹ olórí ilé rẹ̀ àti ohun ìní rẹ̀ gbogbo, ni Ọlọ́run ti bẹ̀rẹ̀ sí ní bùkún àwọn ará Ejibiti nítorí Josẹfu. Ìbùkún Olúwa wà lórí gbogbo ohun tí Potifari ní, nílé àti lóko.

  13. Gẹnẹsisi 39:6nǹkan bí 1728 ṣáájú Kristi

    Ó sì fi Josẹfu ṣe àkóso gbogbo ohun tí ó ní. Kò sì ṣe ìyọnu lórí ohunkóhun mọ àyàfi nípa oúnjẹ tí ó ń jẹ láti ìgbà tí ó ti fi Josẹfu ṣe àkóso ilé e rẹ̀. Josẹfu sì jẹ́ arẹwà ọkùnrin ní ìdúró àti ìrísí rẹ̀,

  14. Gẹnẹsisi 39:7nǹkan bí 1719 ṣáájú Kristi

    lẹ́yìn ìgbà díẹ̀, aya rẹ̀ ṣe àkíyèsí Josẹfu, ó sì wí fún un pé, “Wá bá mi lòpọ̀!”

  15. Gẹnẹsisi 39:8nǹkan bí 1719 ṣáájú Kristi

    Ṣùgbọ́n Josẹfu kọ̀, ó sì wí fún aya ọ̀gá rẹ̀ pé, “Kíyèsi, Olúwa mi kò fi ohunkóhun dù mi nínú ilé yìí, gbogbo ohun ìní rẹ̀ ni ó fi lé mi lọ́wọ́.

  16. Gẹnẹsisi 39:9nǹkan bí 1719 ṣáájú Kristi

    Kò sí ẹni tí ó jù mi lọ nínú ilé yìí, ọ̀gá mi kò fi ohunkóhun dù mi àyàfi ìwọ, tí í ṣe aya rẹ̀. Báwo ni mo ṣe lè ṣe ohun búburú yìí, kí ń sì ṣẹ̀ sí Ọlọ́run?”

  17. Gẹnẹsisi 39:10nǹkan bí 1719 ṣáájú Kristi

    Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé gbogbo ìgbà ni ó ń tẹnumọ́ èyí fún Josẹfu, Josẹfu kọ̀ láti bá a lòpọ̀. Ó tilẹ̀ kọ̀ láti máa dúró ni ibi tí ó bá wà.

  18. Gẹnẹsisi 39:11nǹkan bí 1719 ṣáájú Kristi

    Ní ọjọ́ kan, Josẹfu lọ sínú ilé láti ṣe iṣẹ́, kò sì sí èyíkéyìí nínú àwọn ìránṣẹ́ ní tòsí.

  19. Gẹnẹsisi 39:12nǹkan bí 1719 ṣáájú Kristi

    Ó sì di aṣọ Josẹfu mú, ó sì wí pé, “Wá bá mi lòpọ̀!” Ṣùgbọ́n Josẹfu fi aṣọ rẹ̀ sílẹ̀ sí i lọ́wọ́, ó sì sá jáde.

  20. Gẹnẹsisi 39:13nǹkan bí 1719 ṣáájú Kristi

    Nígbà tí ó rí i pé ó ti fi aṣọ rẹ̀ sílẹ̀ sí òun lọ́wọ́, ó sì ti sá jáde,

  21. Gẹnẹsisi 39:14nǹkan bí 1719 ṣáájú Kristi

    ó pe àwọn ìránṣẹ́ ilé náà, ó sì wí fún wọn pé, “Ẹ wò ó, ọkọ ọ̀ mi mú Heberu kan wọlé tọ̀ wá wá láti fi wá ṣe ẹlẹ́yà. Ó wọlé tọ̀ mí wá, láti bá mi lòpọ̀, ṣùgbọ́n mo kígbe.

  22. Gẹnẹsisi 39:15nǹkan bí 1719 ṣáájú Kristi

    Nígbà tí ó gbọ́ pé mo gbé ohùn mi sókè, tí mo sì kígbe, ó jọ̀wọ́ aṣọ rẹ̀ sọ́dọ̀ mi, ó sì sá, ó bọ́ sóde.”

  23. Gẹnẹsisi 39:16nǹkan bí 1719 ṣáájú Kristi

    Ó sì fi aṣọ náà sọ́dọ̀ títí tí ọkọ rẹ̀ fi dé.

  24. Gẹnẹsisi 39:17nǹkan bí 1719 ṣáájú Kristi

    Ó rò fún un pé, “Ẹrú ará Heberu tí o rà wá ilé láti fi wá ṣẹlẹ́yà wá láti bá mi lòpọ̀.

  25. Gẹnẹsisi 39:18nǹkan bí 1719 ṣáájú Kristi

    Ṣùgbọ́n bí mo ti kígbe fún ìrànlọ́wọ́, ó sì sá kúrò nínú ilé.”