- English
- King James KJV
- Complete Jewish CJB
- World English WEBM
- Berean Standard BSB
- American Standard ASV
- Geneva GNV
- Young's Literal YLT
- Douay-Rheims DRC
- International
- Shqip ALB
- العربية SVD
- বাংলা BN-IRV
- မြန်မာ Judson
- 简体文 CUV-S
- 繁體中文 CUV-T
- Čeština BKR
- Nederlands STVE
- Français LSG
- Deutsch SCH
- Ελληνικά Vamvas
- ગુજરાતી GU-IRV
- Hausa HCB
- עברית Hebrew
- हिन्दी HCV
- Magyar KAROLI
- Bahasa Indonesia INDO-TB
- Italiano Diodati
- 日本語 Kougo
- 한국어 Korean
- മലയാളം MAL
- मराठी MRCV
- Norsk DNB
- فارسی OPV
- Polski BG
- Português Almeida
- Română Cornilescu
- Русский Synodal
- Español RVG
- Kiswahili Neno
- Svenska SV1917
- Tagalog TAG-ADB
- தமிழ் TCV
- తెలుగు TSA
- ภาษาไทย THAI-KJV
- Українська Ohienko
- Tiếng Việt CADMAN
- Yorùbá YCB
circa 1900–1700 BC
Jacob, Joseph & Egypt
Jacob wrestles with God and becomes Israel; Joseph is sold into slavery yet rises to save the world from famine.
Àwọn ẹsẹ láti sáà yìí
- Gẹnẹsisi 39:19nǹkan bí 1719 ṣáájú Kristi
Nígbà tí Potifari gbọ́ ọ̀rọ̀ aya rẹ̀ pé báyìí ni ẹrú rẹ̀ ṣe sí aya rẹ̀, ó bínú gidigidi.
- Gẹnẹsisi 39:20nǹkan bí 1719 ṣáájú Kristi
Ó sì ju Josẹfu sí ẹ̀wọ̀n, níbi tí a ń ju àwọn ẹlẹ́wọ̀n ọba sí. Ṣùgbọ́n, nígbà tí Josẹfu wà nínú ẹ̀wọ̀n níbẹ̀,
- Gẹnẹsisi 39:21nǹkan bí 1719 ṣáájú Kristi
Olúwa sì wà pẹ̀lú rẹ̀, ó sì ṣàánú fún un, ó sì mú kí ó rí ojúrere àwọn alábojútó ọgbà ẹ̀wọ̀n.
- Gẹnẹsisi 39:22nǹkan bí 1719 ṣáájú Kristi
Nítorí náà, alábojútó ọgbà ẹlẹ́wọ̀n fi Josẹfu ṣe alákòóso ohun gbogbo tí ó wà nínú ẹ̀wọ̀n, àti ohun tí wọn ń ṣe níbẹ̀.
- Gẹnẹsisi 39:23nǹkan bí 1719 ṣáájú Kristi
Wọ́dà náà kò sì mikàn nípa gbogbo ohun tí ó fi sí abẹ́ àkóso Josẹfu, nítorí pé Olúwa wà pẹ̀lú Josẹfu, ó sì ń jẹ́ kí ó ṣe àṣeyọrí nínú ohun gbogbo tí ó dáwọ́lé.
Kò pẹ́ lẹ́yìn èyí, ni agbọ́tí ọba àti alásè rẹ̀ ṣẹ̀ ọba Ejibiti, olúwa wọn.
Farao sì bínú sí méjì nínú àwọn ìjòyè rẹ̀, olórí agbọ́tí àti olórí alásè,
Ó sì fi wọ́n sí ìhámọ́ ní ilé olórí ẹ̀ṣọ́, ní inú ẹ̀wọ̀n ibi tí Josẹfu pẹ̀lú wà.
Olórí ẹ̀ṣọ́ sì yan Josẹfu láti máa ṣe ìránṣẹ́ wọn. Lẹ́yìn ìgbà tí wọ́n ti wà ní ìhámọ́ fún ìgbà díẹ̀.
- Gẹnẹsisi 40:5nǹkan bí 1717 ṣáájú Kristi
Ni ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn ọkùnrin méjèèjì náà—olórí agbọ́tí àti olórí alásè ọba Ejibiti, tí a dè sínú túbú, lá àlá ní òru kan náà, àlá kọ̀ọ̀kan sì ní ìtumọ̀ tirẹ̀.
- Gẹnẹsisi 40:6nǹkan bí 1717 ṣáájú Kristi
Nígbà tí Josẹfu dé ọ̀dọ̀ wọn ní òwúrọ̀ ọjọ́ kejì, ó ṣe àkíyèsí pé, inú wọn kò dùn.
- Gẹnẹsisi 40:7nǹkan bí 1717 ṣáájú Kristi
Ó sì bi àwọn ìjòyè Farao tí ó wà pẹ̀lú rẹ̀ nínú ìhámọ́, nínú ilé olúwa rẹ̀ léèrè pé, “Èéṣe tí ojú yín fi fàro bẹ́ẹ̀ ní òní, tí inú yín kò sì dùn?”
- Gẹnẹsisi 40:8nǹkan bí 1717 ṣáájú Kristi
Wọ́n wí pé, “Àwa méjèèjì ni a lá àlá, kò sì sí ẹni tí yóò túmọ̀ rẹ̀.” Josẹfu sì wí fún wọn pé, “Ọlọ́run nìkan ni ó ni ìtumọ̀. Ẹ sọ àwọn àlá yín fún mi.”
- Gẹnẹsisi 40:9nǹkan bí 1717 ṣáájú Kristi
Olórí agbọ́tí sì ṣọ́ àlá rẹ̀ fún Josẹfu, wí pé, “Ní ojú àlá mi, mo rí àjàrà kan (tí wọn ń fi èso rẹ̀ ṣe wáìnì) níwájú mi,
- Gẹnẹsisi 40:10nǹkan bí 1717 ṣáájú Kristi
mo sì rí ẹ̀ka mẹ́ta lórí àjàrà náà, ó yọ ẹ̀ka tuntun, ó sì tanná, láìpẹ́, ó bẹ̀rẹ̀ sí ní í ní èso tí ó ti pọ́n.
- Gẹnẹsisi 40:11nǹkan bí 1717 ṣáájú Kristi
Ife Farao sì wà lọ́wọ́ mi, mo sì mú àwọn èso àjàrà náà, mo sì fún un sínú ife Farao, mo sì gbé ife náà fún Farao.”
- Gẹnẹsisi 40:12nǹkan bí 1717 ṣáájú Kristi
Josẹfu wí fún un pé, “Èyí ni ìtumọ̀ àlá rẹ. Ẹ̀ka mẹ́ta náà dúró fún ọjọ́ mẹ́ta.
- Gẹnẹsisi 40:13nǹkan bí 1717 ṣáájú Kristi
Láàrín ọjọ́ mẹ́ta Farao yóò mú ọ jáde nínú ẹ̀wọ̀n padà sí ipò rẹ, ìwọ yóò sì tún máa gbé ọtí fún un, gẹ́gẹ́ bí ìṣe rẹ àtẹ̀yìnwá.
- Gẹnẹsisi 40:14nǹkan bí 1717 ṣáájú Kristi
Ṣùgbọ́n nígbà tí ohun gbogbo bá dára fún ọ, rántí mi kí o sì fi àánú hàn sí mi. Dárúkọ mi fún Farao, kí o sì mú mi jáde kúrò ní ìhín.
- Gẹnẹsisi 40:15nǹkan bí 1717 ṣáájú Kristi
Nítorí á jí mi gbé tà kúrò ní ilẹ̀ àwọn Heberu ni, àti pé níhìn-ín èmi kò ṣe ohunkóhun tí ó fi yẹ kí èmi wà ní ìhámọ́ bí mo ti wà yìí.”
- Gẹnẹsisi 40:16nǹkan bí 1717 ṣáájú Kristi
Nígbà tí olórí alásè rí i wí pé ìtumọ̀ tí Josẹfu fún àlá náà dára, ó wí fún Josẹfu pé, “Èmi pẹ̀lú lá àlá, mo ru agbọ̀n oúnjẹ mẹ́ta lórí.
- Gẹnẹsisi 40:17nǹkan bí 1717 ṣáájú Kristi
Nínú agbọ̀n tí ó wà lókè, onírúurú oúnjẹ ló wà níbẹ̀ fún Farao, ṣùgbọ́n àwọn ẹyẹ sì ń ṣà wọ́n jẹ láti inú apẹ̀rẹ̀ náà tí ó wà lórí mi.”
- Gẹnẹsisi 40:18nǹkan bí 1717 ṣáájú Kristi
Josẹfu dáhùn, “Èyí ni ìtumọ̀ àlá rẹ. Agbọ̀n mẹ́ta náà túmọ̀ sí ọjọ́ mẹ́ta.
- Gẹnẹsisi 40:19nǹkan bí 1717 ṣáájú Kristi
Láàrín ọjọ́ mẹ́ta, Farao yóò tú ọ sílẹ̀, yóò sì bẹ́ orí rẹ, yóò sì gbé ara rẹ kọ́ sí orí igi. Àwọn ẹyẹ yóò sì jẹ ara rẹ.”
- Gẹnẹsisi 40:20nǹkan bí 1717 ṣáájú Kristi
Ọjọ́ kẹta sì jẹ́ ọjọ́ ìbí Farao, ó sì ṣe àsè fún gbogbo àwọn ìjòyè e rẹ̀. Ó sì mú olórí agbọ́tí àti olórí alásè jáde kúrò nínú ẹ̀wọ̀n.