Fò sí àkóónú

circa 1900–1700 BC

Jacob, Joseph & Egypt

Jacob wrestles with God and becomes Israel; Joseph is sold into slavery yet rises to save the world from famine.

840 ẹsẹ · 1 ìwé tí a bo

Àwọn ẹsẹ láti sáà yìí

  1. Gẹnẹsisi 41:23nǹkan bí 1715 ṣáájú Kristi

    Lẹ́yìn wọn, àwọn méje mìíràn yọ jáde, tí kò yó ọmọ bẹ́ẹ̀ ni afẹ́fẹ́ ìlà-oòrùn ti rẹ̀ ẹ́ dànù tán.

  2. Gẹnẹsisi 41:24nǹkan bí 1715 ṣáájú Kristi

    Àwọn síírí ọkà méje tí kò yómọ sì gbé àwọn méje tí ó dára wọ̀nyí mì. Mo sọ àlá yìí fún àwọn onídán mi, ṣùgbọ́n kò sí ẹni tí ó le túmọ̀ rẹ̀ fún mi.”

  3. Gẹnẹsisi 41:25nǹkan bí 1715 ṣáájú Kristi

    Nígbà náà ni Josẹfu wí fún Farao, “Ìtumọ̀ kan náà ni àwọn àlá méjèèjì ní. Ọlọ́run fi ohun tí ó fẹ́ ṣe hàn fún Farao.

  4. Gẹnẹsisi 41:26nǹkan bí 1715 ṣáájú Kristi

    Àwọn màlúù méje ti ó dára jẹ́ ọdún méje, síírí ọkà méje tí ó dára náà sì jẹ́ ọdún méje: ọ̀kan ṣoṣo ni wọn, àlá kan náà ni.

  5. Gẹnẹsisi 41:27nǹkan bí 1715 ṣáájú Kristi

    Àwọn màlúù méje tí kò sanra, tí kò sì rẹwà tí ó jáde gbẹ̀yìn jẹ́ ọdún méje, bẹ́ẹ̀ náà ni síírí ọkà méje tí kò dára, tí afẹ́fẹ́ ìlà-oòrùn ti rẹ̀ dànù tan, wọn jẹ́ ọdún méje tí ìyàn yóò fi mú.

  6. Gẹnẹsisi 41:28nǹkan bí 1715 ṣáájú Kristi

    “Bí mo ti wí fún Farao ní ìṣáájú náà ni: Ọlọ́run fi ohun tí yóò ṣẹlẹ̀ han Farao.

  7. Gẹnẹsisi 41:29nǹkan bí 1715 ṣáájú Kristi

    Ọdún méje tí oúnjẹ yóò pọ̀ yanturu ń bọ̀ wà ní Ejibiti.

  8. Gẹnẹsisi 41:30nǹkan bí 1715 ṣáájú Kristi

    Ṣùgbọ́n ọdún méje mìíràn tí ìyàn yóò mú ń bọ̀, nígbà náà ni a ó tilẹ̀ gbàgbé gbogbo ọ̀pọ̀ ní ilẹ̀ Ejibiti, ìyàn yóò sì run gbogbo ilẹ̀ náà.

  9. Gẹnẹsisi 41:31nǹkan bí 1715 ṣáájú Kristi

    A kò ní rántí àsìkò ọ̀pọ̀ oúnjẹ yanturu náà mọ́ nítorí pé ìyàn tí yóò tẹ̀lé e yóò pọ̀ púpọ̀.

  10. Gẹnẹsisi 41:32nǹkan bí 1715 ṣáájú Kristi

    Ìdí tí Ọlọ́run fi fi àlá náà han fún Farao ní ọ̀nà méjì ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni pé, Ọlọ́run ti pinnu pé yóò ṣẹlẹ̀ bẹ́ẹ̀ dandan, àti pé kò ni pẹ́ tí Ọlọ́run yóò fi ṣe é.

  11. Gẹnẹsisi 41:33nǹkan bí 1715 ṣáájú Kristi

    “Ìmọ̀ràn mi ni wí pé, jẹ́ kí Farao wá ọlọ́gbọ́n ènìyàn kan ní ilẹ̀ Ejibiti, kí ó sì fi ṣe alákòóso iṣẹ́ àgbẹ̀ ilẹ̀ Ejibiti.

  12. Gẹnẹsisi 41:34nǹkan bí 1715 ṣáájú Kristi

    Kí Farao sì yan àwọn alábojútó láti máa gba ìdámárùn-ún ìkórè oko ilẹ̀ Ejibiti ní àsìkò ọdún méje ọ̀pọ̀.

  13. Gẹnẹsisi 41:35nǹkan bí 1715 ṣáájú Kristi

    Kí wọn kó gbogbo oúnjẹ ilẹ̀ náà ni àwọn ọdún méje ọ̀pọ̀ yìí, kí wọn sì kó àwọn ọkà tí wọn jẹ ṣẹ́kù pamọ́ lábẹ́ àṣẹ Farao. Kí a kó wọn pamọ́ ni àwọn ìlú fún jíjẹ.

  14. Gẹnẹsisi 41:36nǹkan bí 1715 ṣáájú Kristi

    Kí wọn kó oúnjẹ náà pamọ́ fún orílẹ̀-èdè yìí, kí a ba à le lò ó ni ọdún méje tí ìyàn yóò fi jà ní ilẹ̀ Ejibiti, kí ìyàn náà má ba à pa orílẹ̀-èdè yìí run.”

  15. Gẹnẹsisi 41:37nǹkan bí 1715 ṣáájú Kristi

    Èrò náà sì dára lójú Farao àti àwọn ìjòyè rẹ̀.

  16. Gẹnẹsisi 41:38nǹkan bí 1715 ṣáájú Kristi

    Farao sì bi wọ́n pé, “Ǹjẹ́ a le rí ẹnikẹ́ni bi ọkùnrin yìí, nínú ẹni tí ẹ̀mí Ọlọ́run ń gbé?”

  17. Gẹnẹsisi 41:39nǹkan bí 1715 ṣáájú Kristi

    Nígbà náà ni Farao wí fún Josẹfu, “Níwọ́n bí Ọlọ́run ti fi gbogbo èyí hàn ọ́, kò sí ẹni náà tí ó gbọ́n tí ó sì mọ̀ràn bí i tìrẹ ní ilẹ̀ Ejibiti yìí,

  18. Gẹnẹsisi 41:40nǹkan bí 1715 ṣáájú Kristi

    ìwọ yóò ṣe àkóso ààfin mi gbogbo àwọn ènìyàn gbọdọ̀ tẹríba fún àṣẹ ẹ̀ rẹ. Ìtẹ́ mi nìkan ni èmi yóò fi jù ọ́ lọ.”

  19. Gẹnẹsisi 41:41nǹkan bí 1715 ṣáájú Kristi

    Farao wí fún Josẹfu pé, “Mo fi ọ́ ṣe alábojútó gbogbo ilẹ̀ Ejibiti.”

  20. Gẹnẹsisi 41:42nǹkan bí 1715 ṣáájú Kristi

    Farao sì bọ́ òrùka èdìdì ọwọ́ rẹ̀, ó sì fi wọ Josẹfu ó wọ̀ ọ́ ní aṣọ ọ̀gbọ̀ dáradára, ó sì fi ẹ̀gbà tí ó dára sí i lọ́rùn.

  21. Gẹnẹsisi 41:43nǹkan bí 1715 ṣáájú Kristi

    Ó sì mú un kí ó gun kẹ̀kẹ́-ẹṣin bí igbákejì ara rẹ̀, àwọn ènìyàn sì ń pariwo níwájú rẹ̀ pé, “Ẹ yàgò lọ́nà.” Báyìí ni ó sì fi ṣe alábojútó gbogbo ilẹ̀ Ejibiti.

  22. Gẹnẹsisi 41:44nǹkan bí 1715 ṣáájú Kristi

    Nígbà náà ni Farao wí fún Josẹfu pé, “Èmi ni Farao. Ṣùgbọ́n láìsí àṣẹ rẹ, ẹnikẹ́ni kò gbọdọ̀ ṣe ohunkóhun ní ilẹ̀ Ejibiti.”

  23. Gẹnẹsisi 41:45nǹkan bí 1715 ṣáájú Kristi

    Farao sì sọ Josẹfu ní orúkọ yìí Safenati-Panea (èyí tí ó túmọ̀ sí ẹni tí ó ni agbára ikú àti ìyè ní ìkáwọ́ bí òrìṣà). Ó sì fun un ní Asenati ọmọ Potifẹra, alábojútó òrìṣà Oni, gẹ́gẹ́ bí aya. Josẹfu sì rin gbogbo ilẹ̀ Ejibiti já.

  24. Gẹnẹsisi 41:46nǹkan bí 1715 ṣáájú Kristi

    Ọmọ ọgbọ̀n ọdún ni Josẹfu nígbà tí ó wọ iṣẹ́ Farao ọba Ejibiti. Josẹfu sì jáde kúrò níwájú Farao, ó sì ṣe ìbẹ̀wò káàkiri gbogbo ilẹ̀ Ejibiti.

  25. Gẹnẹsisi 41:47nǹkan bí 1715 ṣáájú Kristi

    Ní ọdún méje ọ̀pọ̀, ilẹ̀ náà so èso lọ́pọ̀lọ́pọ̀.