- English
- King James KJV
- Complete Jewish CJB
- World English WEBM
- Berean Standard BSB
- American Standard ASV
- Geneva GNV
- Young's Literal YLT
- Douay-Rheims DRC
- International
- Shqip ALB
- العربية SVD
- বাংলা BN-IRV
- မြန်မာ Judson
- 简体文 CUV-S
- 繁體中文 CUV-T
- Čeština BKR
- Nederlands STVE
- Français LSG
- Deutsch SCH
- Ελληνικά Vamvas
- ગુજરાતી GU-IRV
- Hausa HCB
- עברית Hebrew
- हिन्दी HCV
- Magyar KAROLI
- Bahasa Indonesia INDO-TB
- Italiano Diodati
- 日本語 Kougo
- 한국어 Korean
- മലയാളം MAL
- मराठी MRCV
- Norsk DNB
- فارسی OPV
- Polski BG
- Português Almeida
- Română Cornilescu
- Русский Synodal
- Español RVG
- Kiswahili Neno
- Svenska SV1917
- Tagalog TAG-ADB
- தமிழ் TCV
- తెలుగు TSA
- ภาษาไทย THAI-KJV
- Українська Ohienko
- Tiếng Việt CADMAN
- Yorùbá YCB
circa 2100–1900 BC
Abraham: The Covenant
God calls Abram from Ur, establishes an everlasting covenant, and promises a son through whom all nations will be blessed.
Àwọn ẹsẹ láti sáà yìí
- Gẹnẹsisi 20:4nǹkan bí 1897 ṣáájú Kristi
Ṣùgbọ́n Abimeleki kò tí ìbá obìnrin náà lòpọ̀, nítorí náà ó wí pé, “Olúwa ìwọ yóò run orílẹ̀-èdè aláìlẹ́bi bí?
- Gẹnẹsisi 20:5nǹkan bí 1897 ṣáájú Kristi
Ǹjẹ́ òun kò sọ fún mi pé, ‘Arábìnrin mi ni,’ obìnrin náà pẹ̀lú sì sọ pé, ‘Arákùnrin mí ni’? Ní òtítọ́ pẹ̀lú ọkàn mímọ́ àti ọwọ́ mímọ́, ni mo ṣe èyí.”
- Gẹnẹsisi 20:6nǹkan bí 1897 ṣáájú Kristi
Nígbà náà ni Ọlọ́run wí fún un nínú àlá náà pé, “Bẹ́ẹ̀ ni, mo mọ̀ pé pẹ̀lú òtítọ́ inú ni ìwọ ṣe èyí, èyí ni mo fi pa ọ́ mọ́ tí ń kò jẹ́ kí o ṣẹ̀ sí mi. Ìdí nìyí tí n kò fi jẹ́ kí o ní ìbálòpọ̀ pẹ̀lú obìnrin náà.
- Gẹnẹsisi 20:7nǹkan bí 1897 ṣáájú Kristi
Nísinsin yìí, dá aya ọkùnrin náà padà, nítorí pé wòlíì ni, yóò sì gbàdúrà fún ọ, ìwọ yóò sì yè. Ṣùgbọ́n bí ìwọ kò bá dá a padà, mọ̀ dájú pé ìwọ àti gbogbo ẹni tí í ṣe tìrẹ yóò kú.”
- Gẹnẹsisi 20:8nǹkan bí 1897 ṣáájú Kristi
Ní òwúrọ̀ kùtùkùtù ọjọ́ kejì, Abimeleki pe gbogbo àwọn ìjòyè rẹ̀. Nígbà tí ó sì sọ gbogbo ohun tí ó ṣẹlẹ̀ fún wọn, ẹ̀rù bà wọ́n gidigidi.
- Gẹnẹsisi 20:9nǹkan bí 1897 ṣáájú Kristi
Nígbà náà ni Abimeleki pe Abrahamu ó sì wí fún un pé, “Èwo ni èyí tí ìwọ ṣe sí wa yìí? Ẹ̀ṣẹ̀ wo ni mo ṣẹ̀ ọ́ tí ìwọ fi mú ìdálẹ́bi ńlá wá sí orí èmi àti ìjọba mi? Kò yẹ kí ìwọ hu irú ìwà yìí sí mi.”
- Gẹnẹsisi 20:10nǹkan bí 1897 ṣáájú Kristi
Abimeleki sì bi Abrahamu pé, “Kín ló dé tí ìwọ fi ṣe èyí?”
- Gẹnẹsisi 20:11nǹkan bí 1897 ṣáájú Kristi
Abrahamu sì dáhùn pé, “Mo ṣe èyí nítorí mo rò nínú ara mi pé, ẹ̀yin tí ẹ wà níhìn-ín, ẹ kò bẹ̀rù Ọlọ́run, pé, ẹ sì le pa mí nítorí aya mi.
- Gẹnẹsisi 20:12nǹkan bí 1897 ṣáájú Kristi
Yàtọ̀ fún ìyẹn, òtítọ́ ni pé arábìnrin mi ni. Ọmọ baba kan ni wá, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé, a kì í ṣe ọmọ ìyá kan. Mo sì fẹ́ ẹ ní aya.
- Gẹnẹsisi 20:13nǹkan bí 1897 ṣáájú Kristi
Nígbà tí Ọlọ́run sì mú mi rìn kiri kúrò ní ilé baba mi, mo wí fún un pé, ‘Èyí ni ọ̀nà tí ó lè gbà fihàn pé ó fẹ́ràn mi. Gbogbo ibi tí a bá dé máa sọ pé, “Arákùnrin rẹ ni mí.” ’ ”
- Gẹnẹsisi 20:14nǹkan bí 1897 ṣáájú Kristi
Nígbà náà ni Abimeleki mú àgùntàn àti màlúù wá, àti ẹrúkùnrin àti ẹrúbìnrin, ó sì kó wọn fún Abrahamu, ó sì dá Sara aya rẹ̀ padà fún un.
- Gẹnẹsisi 20:15nǹkan bí 1897 ṣáájú Kristi
Abimeleki sì tún wí fún un pé, “Gbogbo ilẹ̀ mí nìyí níwájú rẹ, máa gbé ní ibikíbi tí o fẹ́ níbẹ̀.”
- Gẹnẹsisi 20:16nǹkan bí 1897 ṣáájú Kristi
Abimeleki sì wí fún Sara pé, “Mo fi ẹgbẹ̀rún (1,000) owó ẹyọ fàdákà fún arákùnrin rẹ. Èyí ni owó ìtánràn ẹ̀ṣẹ̀ mi sí ọ níwájú gbogbo ẹni tí ó wà pẹ̀lú rẹ àti pé, a dá ọ láre pátápátá.”
- Gẹnẹsisi 20:17nǹkan bí 1897 ṣáájú Kristi
Nígbà náà, Abrahamu gbàdúrà sí Ọlọ́run, Ọlọ́run sì wo Abimeleki àti aya rẹ̀ àti àwọn ẹrúbìnrin rẹ̀ sàn. Wọ́n sì tún ń bímọ,
- Gẹnẹsisi 20:18nǹkan bí 1897 ṣáájú Kristi
nítorí Olúwa ti sé gbogbo ará ilé Abimeleki nínú nítorí Sara aya Abrahamu.
Olúwa sì bẹ Sara wò bí ó ti wí, Olúwa sì ṣe fún Sara gẹ́gẹ́ bí ó ti ṣèlérí.
Sara sì lóyún, ó sì bí ọmọkùnrin kan fún Abrahamu ní ọjọ́ ogbó rẹ̀, ní àkókò náà gan an tí Ọlọ́run ti ṣèlérí fún un.
Abrahamu sì sọ orúkọ ọmọ náà tí Sara bí fun un ní Isaaki.
Nígbà tí Isaaki pé ọmọ ọjọ́ mẹ́jọ, Abrahamu sì kọ ọ́ ní ilà gẹ́gẹ́ bí Ọlọ́run ti pàṣẹ fún un.
Ẹni ọgọ́rùn-ún ọdún ni Abrahamu nígbà tí ó bí Isaaki.
Sara sì wí pé, “Ọlọ́run ti pa mí lẹ́rìn-ín. Gbogbo ẹni tí ó bá sì gbọ́ pé mo bímọ yóò rẹ́rìn-ín pẹ̀lú mi.”
Ó sì fi kún un pé, “Ta ni ó le sọ fún Abrahamu pé, Sara yóò di ọlọ́mọ? Síbẹ̀síbẹ̀, mo sì tún bí ọmọ fún Abrahamu ní ìgbà ogbó rẹ.”
- Gẹnẹsisi 21:8nǹkan bí 1893 ṣáájú Kristi
Nígbà tí ọmọ náà dàgbà, ó sì gbà á lẹ́nu ọmú, ní ọjọ́ tí a gba Isaaki lẹ́nu ọmú, Abrahamu ṣe àsè ńlá.
- Gẹnẹsisi 21:9nǹkan bí 1893 ṣáájú Kristi
Ṣùgbọ́n Sara rí ọmọ Hagari ará Ejibiti tí ó bí fún Abrahamu tí ó fi ṣe ẹlẹ́yà,
- Gẹnẹsisi 21:10nǹkan bí 1893 ṣáájú Kristi
ó sì wí fún Abrahamu pé, “Lé ẹrúbìnrin yìí àti ọmọ rẹ̀ jáde, nítorí ọmọ ẹrú yìí kò ní bá ọmọ mi Isaaki pín ogún.”