Fò sí àkóónú

Solomon

275 ẹsẹ · 27 ọmọ ẹbí

A tún mọ̀ ọ́n sí: Jedidiah

Àwọn ẹsẹ tí ó mẹ́nu kan Solomon

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Solomoni sì yà àgbàlá níwájú ilé Olúwa sọ́tọ̀, níbẹ̀ sì ni ó ti ṣe ìrúbọ ẹbọ sísun àti ọ̀rá ẹbọ àlàáfíà, nítorí pẹpẹ idẹ tí ó ti ṣe kò lè gba ẹbọ sísun, àti ọrẹ oúnjẹ, àti ọ̀rá náà.

  2. Bẹ́ẹ̀ ni Solomoni ṣe àsè ní àkókò náà fún ọjọ́ méje àti gbogbo àwọn ọmọ Israẹli pẹ̀lú rẹ̀ àti ìjọ ènìyàn ńlá, àwọn ènìyàn láti Lebo-Hamati títí dé odò Ejibiti.

  3. Ní ọjọ́ kẹtàlélógún tí oṣù keje, ó sì rán àwọn ènìyàn padà sí ilé wọn, pẹ̀lú ayọ̀ àti ìdùnnú nínú wọn fún ohun rere tí Olúwa ti ṣe fún Dafidi àti Solomoni, àti fún àwọn ènìyàn Israẹli.

  4. Nígbà tí Solomoni ti parí ilé Olúwa àti ibi ilé ọba, nígbà tí ó sì ti ṣe àṣeyọrí láti gbé jáde gbogbo ohun tí ó ní lọ́kàn láti ṣe nínú ilé Olúwa àti nínú ilé òun tìkára rẹ̀,

  5. Olúwa sì farahàn Solomoni ní òru ó sì wí pé: “Èmi ti gbọ́ àdúrà rẹ mo sì ti yàn ibí yìí fún ara mi gẹ́gẹ́ bí ilé fún ẹbọ.

  6. Lẹ́yìn ogún ọdún lásìkò ìgbà tí Solomoni kọ́ ilé Olúwa àti ilé òun fúnra rẹ̀.

  7. Solomoni tún ìlú tí Hiramu ti fi fún un kọ́, ó sì kó àwọn ọmọ Israẹli jọ níbẹ̀ kí wọn kí ó lè máa gbé nínú ibẹ̀.

  8. Nígbà náà Solomoni lọ sí Hamati-Ṣoba ó sì borí rẹ̀.

  9. Àti gẹ́gẹ́ bí Baalati àti gbogbo ìlú ìṣúra tí Solomoni ní, àti gbogbo ìlú fún kẹ̀kẹ́ rẹ̀ àti fún àwọn ẹṣin rẹ̀ ohunkóhun tí ó bá yẹ ní kókó ní Jerusalẹmu, ní Lebanoni àti ní gbogbo àyíká agbègbè tí ó ń darí.

  10. èyí ni wí pé, àwọn ọmọ wọn tí ó kù sílé ní ilẹ̀ náà, tí àwọn ọmọ Israẹli kò parun àwọn ni Solomoni bu iṣẹ́ ìrú fún títí di òní yìí.

  11. Ṣùgbọ́n Solomoni kò mú ọmọ ọ̀dọ̀ lára àwọn ọmọ Israẹli, wọn jẹ́ ọ̀gágun rẹ̀, olùdarí àwọn oníkẹ̀kẹ́ àti olùdarí kẹ̀kẹ́ àti àwọn ẹlẹ́ṣin rẹ̀.

  12. Wọ́n sì tún jẹ́ olórí aláṣẹ fún ọba Solomoni, àádọ́ta ó lé nígba (250) àwọn alákòóso lórí àwọn ènìyàn.

  13. Solomoni gbé ọmọbìnrin Farao sókè láti ìlú Dafidi lọ sí ibi tí ó ti kọ́ fún un, nítorí ó wí pé, “Aya mi kò gbọdọ̀ gbé nínú ilé Dafidi ọba Israẹli nítorí ibi tí àpótí ẹ̀rí Olúwa bá tí wọ̀, ibi mímọ́ ni.”

  14. Lórí pẹpẹ Olúwa tí ó ti kọ́ níwájú ìloro náà, Solomoni sì rú ẹbọ sísun sí Olúwa,

  15. Gbogbo iṣẹ́ Solomoni ni a gbé jáde láti ọjọ́ ìfi ìpìlẹ̀ ilé Olúwa lélẹ̀ títí ó fi di ọjọ́ ìparí. Bẹ́ẹ̀ ni ilé Olúwa sì parí.

  16. Nígbà náà ni Solomoni lọ sí Esioni-Geberi àti Elati ní Edomu létí òkun.

  17. Hiramu sì fi ọ̀kọ̀ ránṣẹ́ sì i nípa àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀, àwọn ọkùnrin tí ó mòye Òkun. Èyí pẹ̀lú àwọn ènìyàn Solomoni, lọ sí Ofiri wọ́n sì gbé àádọ́ta lé ní irinwó (450) tálẹ́ǹtì wúrà wá, padà èyí tí wọ́n sì mú tọ ọba Solomoni wá.

  18. Nígbà tí ayaba Ṣeba gbọ́ nípa òkìkí Solomoni, ó sì wá sí Jerusalẹmu láti dán an wò pẹ̀lú ìbéèrè tí ó le. Ó dé pẹ̀lú ẹgbẹ́ ńlá kan pẹ̀lú ìbákasẹ tí ó ru tùràrí, ọ̀pọ̀lọpọ̀ iye wúrà, àti òkúta iyebíye, ó wá sí ọ̀dọ̀ Solomoni ó sì sọ̀rọ̀ pẹ̀lú rẹ̀ nípa gbogbo ohun tí ó ní lọ́kàn rẹ̀.

  19. Solomoni sì dá a lóhùn gbogbo ìbéèrè rẹ̀; kò sì sí èyíkéyìí tí kò lè ṣe àlàyé fún.

  20. Nígbà tí ayaba Ṣeba rí ọgbọ́n Solomoni àti pẹ̀lú ilé tí ó ti kọ́,

  21. Nígbà náà ni ó sì fún ọba ní ọgọ́fà tálẹ́ǹtì wúrà. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ iye tùràrí, àti òkúta iyebíye. Kò sì tí ì sí irú tùràrí yí gẹ́gẹ́ bí èyí tí ayaba Ṣeba fi fún ọba Solomoni.

  22. Àwọn ènìyàn Hiramu àti àwọn ọkùnrin Solomoni gbé wúrà wá láti Ofiri, wọ́n sì tún gbé igi algumu pẹ̀lú àti òkúta iyebíye wá.

  23. Ọba Solomoni fún ayaba Ṣeba ní gbogbo ohun tí ó béèrè fún àti ohun tí ó wù ú; ó sì fi fún un ju èyí tí ó mú wá fún un lọ. Nígbà náà ni ó lọ ó sì padà pẹ̀lú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ sí ìlú rẹ̀.

  24. Ìwọ̀n wúrà tí Solomoni gbà ní ọdún kan sì jẹ́ ọ̀tàlélẹ́gbẹ̀ta ó lé mẹ́fà (666) tálẹ́ǹtì,

  25. láì tí ì ka àkójọpọ̀ owó ìlú tí ó wọlé láti ọ̀dọ̀ àwọn oníṣòwò àti àwọn ọlọ́jà. Àti pẹ̀lú gbogbo àwọn ọba Arabia àti àwọn baálẹ̀ ilẹ̀ náà mu wúrà àti fàdákà wá fún Solomoni.