Skip to content

Tamar

13 ẹsẹ · 21 ọmọ ẹbí

Àwọn ẹsẹ tí ó mẹ́nu kan Tamar

  1. Ó sì ṣe, lẹ́yìn èyí, Absalomu ọmọ Dafidi ní àbúrò obìnrin kan tí ó ṣe arẹwà, orúkọ rẹ̀ a sì máa jẹ́ Tamari; Amnoni ọmọ Dafidi sì fẹ́ràn rẹ̀.

  2. Amnoni sì banújẹ́ títí ó fi ṣe àìsàn nítorí Tamari àbúrò rẹ̀ obìnrin; nítorí pé wúńdíá ni; ó sì ṣe ohun tí ó ṣòro lójú Amnoni láti bá a dàpọ̀.

  3. Ó sì wí fún un pé, “Èéṣe tí ìwọ ọmọ ọba ń fi ń rù lójoojúmọ́ báyìí? Ǹjẹ́ o kò ní sọ fún mi?” Amnoni sì wí fún un pé, “Èmi fẹ́ Tamari àbúrò Absalomu arákùnrin mi.”

  4. Jonadabu sì wí fún un pé, “Dùbúlẹ̀ ní ibùsùn rẹ kí ìwọ sì díbọ́n pé, ìwọ kò sàn, baba rẹ yóò sì wá wò ọ́, ìwọ ó sì wí fún un pé, ‘Jọ̀wọ́ jẹ́ kí Tamari àbúrò mi wá kí ó sì fún mi ní oúnjẹ kí ó sì ṣe oúnjẹ náà níwájú mi kí èmi ó rí i, èmi ó sì jẹ ẹ́ ní ọwọ́ rẹ̀.’ ”

  5. Amnoni sì dùbúlẹ̀, ó sì díbọ́n pé òun ṣàìsàn, ọba sì wá wò ó, Amnoni sì wí fún ọba pé, “Jọ̀wọ́, jẹ́ kí Tamari àbúrò mi ó wá, kí ó sì dín àkàrà méjì lójú mi, èmi ó sì jẹ ní ọwọ́ rẹ̀.”

  6. Dafidi sì ránṣẹ́ sí Tamari ní ilé pé, “Lọ sí ilé Amnoni ẹ̀gbọ́n rẹ, kí ó sì se oúnjẹ fún un.”

  7. Tamari sì lọ sí ilé Amnoni ẹ̀gbọ́n rẹ̀, òun sì ń bẹ ní ìdùbúlẹ̀. Tamari sì mú ìyẹ̀fun, ó sì pò ó, ó sì fi ṣe àkàrà lójú rẹ̀, ó sì dín àkàrà náà.

  8. Amnoni sì wí fún Tamari pé, “Mú oúnjẹ náà wá sí yàrá, èmi ó sì jẹ ẹ́ lọ́wọ́ rẹ.” Tamari sì mú àkàrà tí ó ṣe, ó sì mú un tọ Amnoni ẹ̀gbọ́n rẹ̀ ní yàrá.

  9. Tamari sì bu eérú sí orí rẹ̀, ó sì fa aṣọ aláràbarà tí ń bẹ lára rẹ̀ ya, ó sì ká ọwọ́ rẹ̀ lé orí, ó sì ń kígbe bí ó ti ń lọ.

  10. Absalomu ẹ̀gbọ́n rẹ̀ sì bí i léèrè pé, “Amnoni ẹ̀gbọ́n rẹ bá ọ sùn bí? Ǹjẹ́ àbúrò mi, dákẹ́; ẹ̀gbọ́n rẹ ní í ṣe; má fi nǹkan yìí sí ọkàn rẹ.” Tamari sì jókòó ní ìbànújẹ́ ní ilé Absalomu ẹ̀gbọ́n rẹ̀.

  11. Absalomu kò sì bá Amnoni sọ nǹkan rere, tàbí búburú, nítorí pé Absalomu kórìíra Amnoni nítorí èyí tí ó ṣe, àní tí ó fi agbára mú Tamari àbúrò rẹ̀.

  12. Jonadabu ọmọ Ṣimea arákùnrin Dafidi sì dáhùn ó sì wí pé, “Kí olúwa mi ọba má ṣe rò pé wọ́n ti pa gbogbo àwọn ọ̀dọ́mọdékùnrin àwọn ọmọ ọba; nítorí pé Amnoni nìkan ṣoṣo ni ó kú, nítorí láti ẹnu Absalomu wá ni a ti pinnu rẹ̀ láti ọjọ́ tí ó ti fi agbára mú Tamari àbúrò rẹ̀.

  13. Àwọn wọ̀nyí ni àwọn ọmọ Dafidi yàtọ̀ sí àwọn ọmọ tí àlè bí fún un. Tamari sì ni arábìnrin wọn.