Fò sí àkóónú

Solomon

275 ẹsẹ · 27 ọmọ ẹbí

A tún mọ̀ ọ́n sí: Jedidiah

Àwọn ẹsẹ tí ó mẹ́nu kan Solomon

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Ọba Solomoni sì ṣe igba asà wúrà lílù; ẹgbẹ̀ta (600) ṣékélì tí a fi òlùlù wúrà sí ọ̀kánkán asà.

  2. Gbogbo ohun èlò mímú ìjọba Solomoni ọba ni ó jẹ́ kìkì wúrà, àti gbogbo ohun èlò ààfin ní igbó Lebanoni ni ó jẹ́ wúrà mímọ́. Kò sì ṣí èyí tí a fi fàdákà ṣe, nítorí a kò ka fàdákà sí nǹkan kan ní gbogbo ọjọ́ Solomoni.

  3. Ọba Solomoni sì tóbi nínú ọláńlá àti ọgbọ́n ju gbogbo àwọn ọba tí ó kù lórí ilẹ̀ ayé lọ.

  4. Gbogbo àwọn ọba ayé ń wá ojúrere lọ́dọ̀ Solomoni láti gbọ́n ọgbọ́n tí Ọlọ́run ti fi sínú ọkàn rẹ̀.

  5. Solomoni sì ní ẹgbàajì (4,000) ilé fún àwọn ẹṣin àti kẹ̀kẹ́, àti ẹgbàá mẹ́fà (12,000) àwọn ẹṣin, tí ó fi pamọ́ nínú ìlú kẹ̀kẹ́ àti pẹ̀lú rẹ̀ nínú Jerusalẹmu.

  6. A sì mú àwọn ẹṣin Solomoni wa láti ilẹ̀ òkèrè láti Ejibiti àti láti gbogbo ìlú.

  7. Àti gẹ́gẹ́ bí ìyókù iṣẹ́ ìjọba Solomoni, láti ìbẹ̀rẹ̀ títí dé òpin, ṣé a kò kọ wọ́n sínú ìwé ìtàn Natani wòlíì, àti nínú ìsọtẹ́lẹ̀ Ahijah ará Ṣilo àti nínú ìran Iddo, wòlíì tí o so nípa Jeroboamu ọmọ Nebati?

  8. Solomoni jẹ ọba ní Jerusalẹmu lórí gbogbo àwọn Israẹli fún ogójì ọdún

  9. Solomoni sì sùn pẹ̀lú àwọn baba rẹ̀, a sì sin ín ní ìlú Dafidi baba rẹ̀, Rehoboamu, ọmọ rẹ̀ sì jẹ ọba ní ipò rẹ̀.

  10. Nígbà tí Jeroboamu ọmọ Nebati gbọ́ ẹni ti ó wà ní Ejibiti, níbi tí ó ti sá kúrò lọ́dọ̀ ọba Solomoni ó sì padà láti Ejibiti.

  11. Nígbà náà ni ọba Rehoboamu fi ọ̀ràn lọ̀ àwọn àgbàgbà tí ó ti ń sin baba rẹ̀ Solomoni nígbà ayé rẹ̀, ó sì bi wọ́n léèrè pe, “Báwo ni ẹ̀yin yóò ṣe gbà mí ní ìmọ̀ràn láti dá àwọn ènìyàn wọ̀nyí lóhùn?”

  12. “Wí fún Rehoboamu ọmọ Solomoni ọba Juda, sí gbogbo àwọn ọmọ Israẹli ní Juda àti Benjamini,

  13. Ó fún ìjọba Juda ní agbára, ó sì ti Rehoboamu ọmọ Solomoni lẹ́yìn fún ọdún mẹ́ta nítorí ọdún mẹ́ta ni wọ́n fi rìn ní ọ̀nà ti Dafidi àti Solomoni ní àkókò yí.

  14. Nígbà tí Ṣiṣaki ọba Ejibiti dojúkọ Jerusalẹmu, ó gbé àwọn ìṣúra ilé Olúwa, àti àwọn ìṣúra ààfin ọba. Ó gbé gbogbo rẹ̀, pẹ̀lú àwọn àpáta wúrà tí Solomoni dá.

  15. Síbẹ̀ Jeroboamu ọmọ Nebati, oníṣẹ́ Solomoni ọmọ Dafidi, ṣọ̀tẹ̀ sí ọ̀gá rẹ̀.

  16. Àwọn ènìyàn lásán sì kó ara wọn jọ sí ọ̀dọ̀ rẹ̀, àwọn ọmọ ẹni búburú, wọ́n sì kẹ̀yìn sí Rehoboamu ọmọ Solomoni ní ìgbà tí ó sì kéré tí kò lè pinnu fúnra rẹ̀, tí kò lágbára tó láti takò wọ́n.

  17. Bẹ́ẹ̀ ni ayọ̀ ńlá sì wà ní Jerusalẹmu: nítorí láti ọjọ́ Solomoni, ọmọ Dafidi, ọba Israẹli, irú èyí kò sí ní Jerusalẹmu.

  18. Ó mú ère gbígbẹ́ tí ó ti gbẹ́ ó sì gbé e sínú ilé Olúwa, ní èyí tí Ọlọ́run ti sọ fún Dafidi àti sí ọmọ rẹ̀ Solomoni, “Nínú ilé Olúwa yìí àti ní Jerusalẹmu, tí mo ti yàn kúrò nínú gbogbo àwọn ẹ̀yà Israẹli, èmi yóò fi orúkọ mi síbẹ̀ títí láé.

  19. Ó sì wí fún àwọn ọmọ Lefi, ẹni tí ń kọ́ gbogbo àwọn Israẹli ẹni tí a ti yà sí mímọ́ fún Olúwa pé ẹ gbé àpótí ẹ̀rí ìyàsọ́tọ̀ sí ilé Olúwa tí Solomoni ọmọ Dafidi ọba Israẹli ti kọ́. Kò gbọdọ̀ jẹ́ ẹrù àgbéká ní èjìká rẹ̀. Nísinsin yìí ẹ sin Olúwa Ọlọ́run yín àti àwọn ènìyàn rẹ̀ Israẹli.

  20. Ẹ múra sílẹ̀ nípa ìdílé ní ẹsẹẹsẹ yín gẹ́gẹ́ bí àpẹẹrẹ tí a kọ́ láti ọwọ́ Dafidi ọba Israẹli àti gẹ́gẹ́ bí ọmọ rẹ̀ Solomoni.

  21. Àwọn ọmọ àwọn ìránṣẹ́ Solomoni. Àwọn ọmọ Sotai, Sofereti, Peruda,

  22. Àwọn ìránṣẹ́ tẹmpili àti àwọn ọmọ àwọn ìránṣẹ́ Solomoni jẹ́ irinwó ó dín mẹ́jọ (392).

  23. Àwọn ọmọ àwọn ìránṣẹ́ Solomoni: àwọn ọmọ Sotai, Sofereti; Perida,

  24. Àwọn ìránṣẹ́ tẹmpili àti àwọn ọmọ ìránṣẹ́ Solomoni jẹ́ irinwó ó dín mẹ́jọ (392).

  25. Wọ̀nyí ni àwọn olórí agbègbè ìjọba tí wọ́n tẹ̀dó sí Jerusalẹmu (díẹ̀ nínú àwọn ọmọ Israẹli àwọn àlùfáà, àwọn ọmọ Lefi, àwọn ìránṣẹ́ tẹmpili àti àwọn ìran àwọn ìránṣẹ́ Solomoni ń gbé àwọn ìlú Juda, olúkúlùkù ń gbé lórí ilẹ̀ ìní rẹ̀ ní àwọn ìlú náà.