Skip to content

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Treaty

40 ẹsẹ · 4 abala

Àwọn ẹsẹ Bíbélì pàtàkì

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Máa ṣọ́ra kí o má ba à bá àwọn ti ó n gbé ilẹ̀ náà tí ìwọ ń lọ dá májẹ̀mú, nítorí wọn yóò jẹ́ ìdẹwò láàrín rẹ.

  2. “Máa ṣọ́ra kí ẹ má ṣe bá àwọn ènìyàn tí ń gbé ilẹ̀ náà dá májẹ̀mú; nígbà tí wọ́n bá ń ṣe àgbèrè tọ òrìṣà wọn, tí wọ́n sì rú ẹbọ sí wọn, wọn yóò pè yín, ẹ̀yin yóò sì jẹ ẹbọ wọn.

  3. Kí àwọn ayọ́lẹ̀wò náà tó sùn ní alẹ́, ó gòkè tọ̀ wọ́n lọ lókè àjà.

  4. Ó sì sọ fún wọn, “Èmi mọ̀ pé Olúwa ti fún un yín ní ilẹ̀ yìí àti pé ẹ̀rù u yín ti sọ wá di ojo dé ibi pé ìdí gbogbo àwọn tí ó n gbé ilẹ̀ yìí ti di omi nítorí i yín.

  5. Àwa ti gbọ́ bí Olúwa ti mú omi Òkun Pupa gbẹ níwájú u yín nígbà tí ẹ̀yin jáde kúrò ní ilẹ̀ Ejibiti, àti ohun tí ẹ̀yin ṣe sí Sihoni àti Ogu, àwọn ọba méjèèjì ti Amori ti ìlà-oòrùn Jordani, tí ẹ̀yin parun pátápátá.

  6. Bí a ti gbọ́ nǹkan wọ̀nyí, ọkàn wa pami kò sì sí okun kankan fún wa mọ́ nítorí i yín, nítorí pé Olúwa Ọlọ́run yín ni Ọlọ́run ní òkè ọ̀run àti ní ayé.

  7. Ǹjẹ́ nísinsin yìí, ẹ jọ̀wọ́ ẹ búra fún mi ní ti Olúwa pé ẹ̀yin yóò ṣe àánú fún ìdílé mi, nítorí pé mo ti ṣe yín ní oore. Ẹ̀yin yóò fún mi ní àmì tó dájú:

  8. pé ẹ̀yin yóò dá ẹ̀mí baba àti ìyá mi sí; arákùnrin mi àti arábìnrin mi, àti ohun gbogbo tí wọ́n ní, àti pé ẹ̀yin yóò gbà wá là lọ́wọ́ ikú.”

  9. “Ẹ̀mí wa fún ẹ̀mí in yín!” àwọn ọkùnrin náà mú dá a lójú. “Tí ìwọ kò bá sọ ohun tí àwa ń ṣe, àwa yóò sì fi òtítọ́ àti àánú bá ọ lò nígbà tí Olúwa bá fún wa ní ilẹ̀ náà.”

  10. Nígbà náà ní ó fi okùn sọ̀ wọ́n kalẹ̀ ní ojú u fèrèsé, nítorí ilé tí ó ń gbé wà ní ara odi ìlú.

  11. Ó sì ti sọ fún wọn pé, “Ẹ lọ sí orí òkè, kí ẹ sì fi ara pamọ́ níbẹ̀ fún ọjọ́ mẹ́ta kí àwọn tí ń lépa yín má ba à rí i yín títí tí wọn yóò fi darí. Lẹ́yìn náà kí ẹ máa bá ọ̀nà yín lọ.”

  12. Àwọn arákùnrin náà sì sọ fún un pé, “Kí ọrùn un wa ba à lè mọ́ kúrò nínú ìbúra tí ìwọ mú wa bú yìí.

  13. Nígbà tí àwa bá wọ ilé è rẹ, ìwọ yóò so okùn aláwọ̀ aró yìí sí ojú fèrèsé èyí tí ìwọ fi sọ̀ wá kalẹ̀, kí ìwọ kí ó mú baba rẹ, ìyá rẹ, àwọn arákùnrin in rẹ àti gbogbo ìdílé è rẹ kí wọ́n wá sí inú ilé è rẹ.

  14. Bí ẹnikẹ́ni bá jáde sí ìta láti inú ilé è rẹ sí inú ìgboro ìlú, ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ yóò sì wà ní orí ara rẹ̀; ẹ̀bi rẹ̀ yóò sì wà lórí i rẹ̀. Fún ẹnikẹ́ni tí ó bá wà nínú ilé pẹ̀lú rẹ, ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ yóò wà ní orí i wa bí ẹnikẹ́ni bá fi ọwọ́ kàn án.

  15. Ṣùgbọ́n bí ìwọ bá sọ ohun tí àwa ń ṣe, àwa yóò bọ́ nínú ìbúra tí ìwọ mú wa bú.”

  16. Ó dáhùn pé, “Ó dára bẹ́ẹ̀. Ẹ jẹ́ kí ó rí gẹ́gẹ́ bí ẹ̀yin tí sọ.” Ó sì rán wọn lọ wọ́n sì lọ. Ó sì so okùn òdòdó náà sí ojú fèrèsé.

  17. Ní ẹ̀yìn ọjọ́ mẹ́ta tí wọ́n ti ṣe àdéhùn pẹ̀lú àwọn ará Gibeoni, àwọn ọmọ Israẹli gbọ́ pé aládùúgbò wọn ni wọ́n, tí ń gbé ní tòsí wọn.

  18. Bẹ́ẹ̀ ní àwọn ọmọ Israẹli jáde, wọ́n sì dé ìlú wọn ní ọjọ́ kẹta: Gibeoni, Kefira, Beeroti àti Kiriati-Jearimu.

  19. Ṣùgbọ́n àwọn ọmọ Israẹli kò si kọlù wọ́n, nítorí pé àwọn àgbàgbà ìjọ ènìyàn ti búra fún wọn ní orúkọ Olúwa Ọlọ́run Israẹli. Gbogbo ènìyàn sì kùn sí àwọn àgbàgbà náà,

  20. ṣùgbọ́n gbogbo àwọn olórí dáhùn pé, “Àwa ti búra fún wọn ní orúkọ Olúwa Ọlọ́run Israẹli, a kò sì lè fọwọ́ kàn wọ́n nísinsin yìí.

  21. Èyí ní àwa yóò ṣe sí wọn, àwa yóò dá wọn sí, kí ìbínú kí ó má ba à wá sórí wa, nítorí ìbúra tí a búra fún wọn.”

  22. Wọ́n tẹ̀síwájú, “Ẹ dá wọn sí, ṣùgbọ́n ẹ jẹ́ kí wọn jẹ́ gégigégi àti apọnmi fún gbogbo ìlú.” Àwọn àgbàgbà náà sì mú ìlérí wọn ṣẹ fún wọn.

  23. Nígbà tí Hiramu ọba Tire sì gbọ́ pé, a ti fi òróró yan Solomoni ní ọba ní ipò Dafidi baba rẹ̀, ó sì rán àwọn ikọ̀ rẹ̀ sí Solomoni, nítorí ó ti fẹ́ràn Dafidi ní ọjọ́ rẹ̀ gbogbo.

  24. Solomoni sì ránṣẹ́ yìí padà sí Hiramu pé,

  25. “Ìwọ mọ̀ pé Dafidi baba mi kò le kọ́ ilé fún orúkọ Olúwa Ọlọ́run rẹ̀, nítorí ogun tí ó wà yí i káàkiri, títí Olúwa fi fi gbogbo àwọn ọ̀tá rẹ̀ sábẹ́ àtẹ́lẹsẹ̀ rẹ̀.