Fò sí àkóónú

Solomon

275 ẹsẹ · 27 ọmọ ẹbí

A tún mọ̀ ọ́n sí: Jedidiah

Àwọn ẹsẹ tí ó mẹ́nu kan Solomon

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Wọ́n ń ṣiṣẹ́ Ọlọ́run wọn àti iṣẹ́ ìyàsímímọ́, bẹ́ẹ̀ náà ni fún àwọn akọrin àti àwọn aṣọ́nà, wọ́n ń ṣe gẹ́gẹ́ bí Dafidi àti Solomoni ọmọ rẹ̀ ti pàṣẹ fún wọn.

  2. Kì í ha á ṣe àwọn ìgbéyàwó bí irú èyí ni ọba Solomoni fi dá ẹ̀ṣẹ̀? Láàrín àwọn orílẹ̀-èdè, kò sí ọba kan bí i tirẹ̀. Ọlọ́run rẹ̀ fẹ́ràn rẹ̀, Ọlọ́run sì fi jẹ ọba lórí i gbogbo Israẹli, ṣùgbọ́n àwọn obìnrin àjèjì ti sọ ọ́ sínú òfin ẹ̀ṣẹ̀.

  3. Ti Solomoni. Fi ìdájọ́ fún àwọn ọba, Ọlọ́run, ọmọ-aládé ni ìwọ fi òdodo rẹ fún.

  4. Orin fún ìgòkè. Ti Solomoni. Bí kò ṣe pé Olúwa bá kọ́ ilé náà àwọn tí ń kọ́ ọ ń ṣiṣẹ́ lásán ni; bí kò ṣe pé Olúwa bá pa ìlú mọ́, olùṣọ́ jí lásán.

  5. Àwọn òwe ti Solomoni, ọmọ Dafidi, ọba Israẹli.

  6. Àwọn òwe Solomoni. Ọlọ́gbọ́n ọmọ ń mú inú baba rẹ̀ dùn, ṣùgbọ́n aṣiwèrè ọmọ ń ba inú ìyá rẹ̀ jẹ́.

  7. Wọ̀nyí ni àwọn òwe mìíràn tí Solomoni pa, tí àwọn ọkùnrin Hesekiah ọba Juda dà kọ.

  8. Orin, àwọn orin tí í ṣe orin Solomoni.

  9. Èmi dúdú mo sì ní ẹwà. Ẹ̀yin ọmọbìnrin Jerusalẹmu dúdú bí àgọ́ ìlú Kedari, bí aṣọ títa ti Solomoni.

  10. Wò ó! Àkéte rẹ̀ tí í ṣe ti Solomoni, àwọn akọni ọgọ́ta ni ó wà yí i ká, àwọn akọni Israẹli,

  11. Solomoni ọba ṣe àkéte fún ara rẹ̀; o fi igi Lebanoni ṣe é.

  12. Ẹ jáde wá, ẹ̀yin ọmọbìnrin Sioni, kí ẹ sì wo ọba Solomoni tí ó dé adé, adé tí ìyá rẹ̀ fi dé e ní ọjọ́ ìgbéyàwó rẹ̀, ní ọjọ́ ayọ̀ ọkàn rẹ̀.

  13. Solomoni ní ọgbà àjàrà kan ní Baali-Hamoni ó gbé ọgbà àjàrà rẹ̀ fún àwọn alágbàtọ́jú olúkúlùkù ni ó ń mú èso rẹ̀ wá ẹgbẹ̀rún (1,000) fàdákà.

  14. Ṣùgbọ́n ọgbà àjàrà mi jẹ́ tèmi, ó wà fún mi; ẹgbẹ̀rún ṣékélì jẹ́ tìrẹ, ìwọ Solomoni, igba sì jẹ́ ti àwọn alágbàtọ́jú èso.

  15. Àwọn ọ̀wọ́n méjì, agbada ńlá kan àti àwọn màlúù idẹ méjìlá tí ó wà lábẹ́ ìjókòó alágbéká tí Solomoni ọba ṣe fún ilé Olúwa, idẹ ni gbogbo ohun èlò wọ̀nyí, ó ju èyí tí a lè wọ́n lọ.

  16. Jese ni baba Dafidi ọba. Dafidi ni baba Solomoni, ẹni tí ìyá rẹ̀ jẹ́ aya Uriah tẹ́lẹ̀ rí.

  17. Solomoni ni baba Rehoboamu, Rehoboamu ni baba Abijah, Abijah ni baba Asa,

  18. Bẹ́ẹ̀ ni mo wí fún yín pé, a kò ṣe Solomoni lọ́ṣọ̀ọ́ nínú gbogbo ògo rẹ̀ tó ọ̀kan nínú àwọn nǹkan wọ̀nyí.

  19. Ọbabìnrin gúúsù yóò sì dìde ní ọjọ́ ìdájọ́ sí ìran yìí yóò sì dá a lẹ́bi; nítorí tí ó wá láti ilẹ̀ ìkangun ayé láti gbọ́ ọ̀rọ̀ ọgbọ́n láti ẹnu Solomoni. Ṣùgbọ́n báyìí ẹni tí ó pọ̀jù Solomoni ń bẹ níhìn-ín yìí.

  20. Ọbabìnrin gúúsù yóò dìde ní ọjọ́ ìdájọ́ pẹ̀lú àwọn ènìyàn ìran yìí, yóò sì dá wọn lẹ́bi: nítorí tí ó ti ìhà ìpẹ̀kun ayé wá láti gbọ́ ọgbọ́n Solomoni: sì kíyèsi i, ẹni tí ó pọ̀jù Solomoni lọ ń bẹ níhìn-ín yìí.

  21. “Ẹ kíyèsi àwọn lílì bí wọ́n ti ń dàgbà; wọn kì í ṣiṣẹ́, wọn kì í rànwú; ṣùgbọ́n kí èmi wí fún yín, a kò ṣe Solomoni pàápàá lọ́ṣọ̀ọ́ ní gbogbo ògo rẹ̀ tó ọ̀kan nínú ìwọ̀nyí.

  22. Jesu sì ń rìn ní tẹmpili, ní ìloro Solomoni.

  23. Bí arọ ti a mú láradá sì ti di Peteru àti Johanu mú, gbogbo ènìyàn jùmọ̀ súre tọ̀ wọ́n lọ ni ìloro ti a ń pè ní ti Solomoni, pẹ̀lú ìyàlẹ́nu ńlá.

  24. A sì ti ọwọ́ àwọn aposteli ṣe iṣẹ́ àmì àti iṣẹ́ ìyanu púpọ̀ láàrín àwọn ènìyàn. Gbogbo wọn sì fi ọkàn kan wà ní ìloro Solomoni.

  25. Ṣùgbọ́n Solomoni ni ó kọ́ ilé fún un.