Skip to content

Bathshua

12 ẹsẹ · 7 ọmọ ẹbí

A tún mọ̀ ọ́n sí: Bathsheba, Bath, Bath-shua

Àwọn ẹsẹ tí ó mẹ́nu kan Bathshua

  1. Dafidi sì ránṣẹ́ ó sì béèrè obìnrin náà. Ẹnìkan sì wí pé, “Èyí ha kọ́ ni Batṣeba, ọmọbìnrin Eliamu, aya Uriah ará Hiti.”

  2. Dafidi sì ṣìpẹ̀ fún Batṣeba aya rẹ̀, ó sì wọlé tọ̀ ọ́, ó sì bá a dàpọ̀, òun sì bí ọmọkùnrin kan, Dafidi sì sọ orúkọ rẹ̀ ní Solomoni, Olúwa sì fẹ́ ẹ.

  3. Nígbà náà ni Natani béèrè lọ́wọ́ Batṣeba, ìyá Solomoni pé, “Ǹjẹ́ ìwọ kò gbọ́ pé Adonijah, ọmọ Haggiti ti jẹ ọba láìjẹ́ pé Dafidi olúwa wa mọ̀ sí i?

  4. Bẹ́ẹ̀ ni Batṣeba lọ rí ọba ní inú yàrá rẹ̀, ọba sì gbó gidigidi níbi tí Abiṣagi ará Ṣunemu ti ń ṣe ìránṣẹ́ fún ọba.

  5. Batṣeba sì tẹríba, ó sì kúnlẹ̀ níwájú ọba. Ọba sì béèrè pé, “Kí ni ìwọ ń fẹ́?”

  6. Nígbà náà ni Dafidi ọba wí pé, “Pe Batṣeba wọlé wá.” Ó sì wá síwájú ọba, ó sì dúró níwájú rẹ̀.

  7. Nígbà náà ni Batṣeba tẹríba, ó sì kúnlẹ̀ níwájú ọba pé, “Kí olúwa mi Dafidi ọba kí ó pẹ́!”

  8. Wàyí, Adonijah ọmọ Haggiti tọ Batṣeba, ìyá Solomoni wá. Batṣeba sì bi í pé, “Àlàáfíà ni o bá wa bí?” Ó sì dáhùn pé, “Bẹ́ẹ̀ ni, àlàáfíà ni.”

  9. Batṣeba sì dáhùn pé, “Ó dára èmi yóò bá ọba sọ̀rọ̀ nítorí rẹ̀.”

  10. Nígbà tí Batṣeba sì tọ Solomoni ọba lọ láti bá a sọ̀rọ̀ nítorí Adonijah, ọba sì dìde láti pàdé rẹ̀, ó sì tẹríba fún un, ó sì jókòó lórí ìtẹ́ rẹ̀. Ó sì tẹ́ ìtẹ́ kan fún ìyá ọba, ó sì jókòó lọ́wọ́ ọ̀tún rẹ̀.

  11. Wọ̀nyí ni ọmọ wẹ́wẹ́ tí a bí fún un ní Jerusalẹmu: Ṣimea, Ṣobabu, Natani àti Solomoni. Àwọn mẹ́rin wọ̀nyí sì ni a bí láti ọ̀dọ̀ Bati-Ṣua ọmọbìnrin Ammieli.

  12. Fún adarí orin. Saamu ti Dafidi. Nígbà ti wòlíì Natani tọ wá, lẹ́yìn tí Dafidi dá ẹ̀ṣẹ̀ àgbèrè rẹ̀ pẹ̀lú Batṣeba. Ṣàánú fún mi, Ọlọ́run, gẹ́gẹ́ bí ìdúró ṣinṣin ìfẹ́ rẹ̀, gẹ́gẹ́ bí ọ̀pọ̀ àánú rẹ̀ kí o sì pa gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ mi rẹ́.