Skip to content

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Servants

291 ẹsẹ · 147 abala

Àwọn ẹsẹ Bíbélì pàtàkì

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Bí a bá rí i lọ́wọ́ èyíkéyìí nínú àwọn ìránṣẹ́ rẹ, kíkú ni yóò kú, àwọn tí ó kù yóò sì di ẹrú fún olúwa à rẹ.”

  2. Àwọn ti ó bẹ̀rù ọ̀rọ̀ Olúwa lára àwọn ìjòyè Farao yára lọ láti kó àwọn ẹrú àti àwọn ẹran ọ̀sìn wọn wá sí abẹ́ ààbò.

  3. Gbogbo àwọn ìjòyè rẹ̀ wọ̀nyí yóò tọ̀ mí wá, wọn yóò wólẹ̀ ni iwájú, mi wọn yóò sì máa wí pé, ‘Lọ àti àwọn ènìyàn tí ó tẹ̀lé ọ!’ Lẹ́yìn náà èmi yóò jáde.” Nígbà náà ni Mose fi ìbínú jáde kúrò ní iwájú Farao.

  4. Ẹrú tí ẹ̀yin bá rà lè jẹ́ nínú rẹ̀ lẹ́yìn tí ẹ̀yin bá ti kọ ọ́ ní ilà,

  5. ṣùgbọ́n àtìpó àti alágbàṣe kò ni jẹ nínú rẹ̀.

  6. ṣùgbọ́n ọjọ́ keje ni ọjọ́ ìsinmi Olúwa Ọlọ́run rẹ: nínú rẹ̀ ìwọ kò gbọdọ̀ ṣe iṣẹ́kíṣẹ́ kan: ìwọ, àti ọmọ rẹ ọkùnrin àti ọmọ rẹ obìnrin, ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ ọkùnrin àti ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ obìnrin, àti ẹran ọ̀sìn rẹ, àti àlejò rẹ, tí ń bẹ nínú ibodè rẹ.

  7. Ìwọ kò gbọdọ̀ ṣe ojúkòkòrò sí ilé ẹnìkéjì rẹ. Ìwọ kò gbọdọ̀ ṣe ojúkòkòrò sí aya ẹnìkéjì rẹ, ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ̀ ọkùnrin àti ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ̀ obìnrin, akọ màlúù rẹ̀ àti kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ rẹ̀ àti ohun gbogbo tí í ṣe ti ẹnìkéjì rẹ.”

  8. “Bí ìwọ bá yá ọkùnrin Heberu ní ìwẹ̀fà, òun yóò sìn ọ́ fún ọdún mẹ́fà. Ṣùgbọ́n ní ọdún keje, òun yóò lọ ni òmìnira láìsan ohunkóhun padà.

  9. Bí ó bá wá ní òun nìkan, òun nìkan náà ni yóò padà lọ ní òmìnira; ṣùgbọ́n tí ó bá mú ìyàwó wá, ó ní láti mú ìyàwó rẹ̀ padà lọ.

  10. Bí olówó rẹ̀ bá fún un ní aya, tí aya náà sì bímọ ọkùnrin àti obìnrin, aya àti àwọn ọmọ rẹ̀ yóò jẹ́ ti olówó rẹ̀, yóò sì lọ ní òmìnira ní òun nìkan.

  11. “Bí ẹrú náà bá sì wí ní gbangba pé, mo fẹ́ràn olúwa mi, ìyàwó mi àti àwọn ọmọ, èmi kò sì fẹ́ ẹ́ gba òmìnira mọ́,

  12. nígbà náà ni olúwa rẹ̀ yóò mu wá sí iwájú ìdájọ́. Òun yóò sì mú un lọ sí ẹnu-ọ̀nà tàbí lọ sí ibi ọ̀wọ̀n, yóò sì fi ìlu lu etí rẹ̀, òun yóò sì máa sin olówó rẹ̀ títí ayé.

  13. “Bí ọkùnrin kan bá ta ọmọbìnrin rẹ̀ bí ìwẹ̀fà, ọmọbìnrin yìí kò ní gba òmìnira bí i ti ọmọkùnrin.

  14. Bí òun kò bá sì tẹ́ olówó rẹ̀ lọ́rùn, ẹni tí ó fẹ́ ẹ fún ara rẹ̀, yóò jẹ́ kí wọn ó rà á padà, òun kò ní ẹ̀tọ́ láti tà á bí ẹrú fún àjèjì, nítorí pé òun ni kò ṣe ojúṣe rẹ̀ pẹ̀lú ìwẹ̀fà náà.

  15. Bí ó bá fẹ́ ẹ fún ọmọkùnrin rẹ̀, kò ní máa lò ó bí ìwẹ̀fà mọ́, ṣùgbọ́n yóò máa ṣe sí i gẹ́gẹ́ bí ọmọ rẹ̀ obìnrin.

  16. Bí ó bá fẹ́ obìnrin mìíràn, kò gbọdọ̀ kùnà ojúṣe rẹ̀ nípa fífún un ní oúnjẹ àti aṣọ, bẹ́ẹ̀ ni kò gbọdọ̀ kùnà ojúṣe rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọkọ sí aya.

  17. Bí ó bá kùnà láti ṣe àwọn nǹkan mẹ́ta wọ̀nyí fún un, òun yóò lọ ní òmìnira láìsan owó kankan padà.

  18. “Ẹnikẹ́ni ti ó bá jí ènìyàn gbé, tí ó sì tà á tàbí tí ó fi pamọ́, pípa ni a ó pa á.

  19. “Bí ọkùnrin kan bá fi ọ̀pá lu ẹrúkùnrin tàbí ẹrúbìnrin rẹ̀, ti ẹrú náà sì kú lójú ẹsẹ̀, a ó fi ìyà jẹ ẹ́.

  20. Ṣùgbọ́n a kò ní fi ìyà jẹ ẹ́, ti ẹrú náà bá yè, tí ó dìde lẹ́yìn ọjọ́ kan tàbí méjì, nítorí ẹrú náà jẹ́ dúkìá rẹ̀.

  21. “Bí ọkùnrin kan bá lu ẹrúkùnrin tàbí ẹrúbìnrin rẹ̀ ní ojú, ti ojú náà sì fọ́, ó ni láti jẹ́ kí ẹrú náà lọ ní òmìnira fún ìtánràn ojú rẹ̀ ti ó fọ́.

  22. Bí ó bá sì lu ẹrúkùnrin tàbí ẹrúbìnrin rẹ̀ ti eyín rẹ̀ fi ká, ó ni láti jẹ́ kí ó lọ ní òmìnira ni ìtánràn fún eyín rẹ̀ tí ó ká.

  23. Bí akọ màlúù bá kan ẹrúkùnrin tàbí ẹrúbìnrin pa, olówó rẹ̀ yóò san ọgbọ̀n ṣékélì fàdákà fún ẹni tó ni ẹrú, a ó sì sọ akọ màlúù náà ni òkúta pa.

  24. Ṣùgbọ́n ti ó bá ṣẹlẹ̀ ni ojú ọ̀sán, a ó kà á si ìpànìyàn. Ọkùnrin ti ó lù ú pa náà yóò ni ẹ̀bi ìtàjẹ̀ sílẹ̀. “Olè gbọdọ̀ san ohun tí ó jí padà. Ṣùgbọ́n tí kò bá ni ohun ti ó lè fi san án padà, a ó tà á, a ó sì fi sanwó ohun tí ó jí gbé padà.

  25. “ ‘Ìwọ kò gbọdọ̀ rẹ́ aládùúgbò rẹ jẹ bẹ́ẹ̀ ni ìwọ kò gbọdọ̀ jà á lólè. “ ‘Ìwọ kò gbọdọ̀ dá owó iṣẹ́ alágbàṣe dúró di ọjọ́ kejì.