Skip to content

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Servants

291 ẹsẹ · 147 abala

Àwọn ẹsẹ Bíbélì pàtàkì

Sẹ́ nípa ìwé
  1. “ ‘Kò sí ẹnikẹ́ni lẹ́yìn ìdílé àlùfáà tí ó le jẹ ọrẹ mímọ́ náà, bẹ́ẹ̀ ni, àlejò àlùfáà tàbí alágbàṣe rẹ̀ kò le jẹ ẹ́.

  2. Ohunkóhun tí ilẹ̀ náà bá mú jáde ní ọdún ìsinmi ni yóò jẹ́ oúnjẹ fún yín àní fún ẹ̀yin tìkára yín, àwọn ìránṣẹ́kùnrin àti ìránṣẹ́bìnrin yín, àwọn alágbàṣe àti àwọn tí ń gbé pẹ̀lú yín fún ìgbà díẹ̀.

  3. Ẹ ya àádọ́ta ọdún náà sọ́tọ̀ kí ẹ sì kéde òmìnira fún gbogbo ẹni tí ń gbé ilẹ̀ náà. Yóò jẹ́ ọdún ìdásílẹ̀ fún yín. Kí olúkúlùkù padà sí ilẹ̀ ìní rẹ̀ àti sí ọ̀dọ̀ àwọn ẹbí rẹ̀.

  4. “ ‘Bí arákùnrin yín kan bá tálákà dé bi pé ó ta ara rẹ̀ fún ọ bí ẹrú. Má ṣe lò ó bí ẹrú.

  5. Jẹ́ kí ó wà lọ́dọ̀ rẹ bí alágbàṣe tàbí àlejò láàrín yín, kí ó máa ṣiṣẹ́ sìn ọ́ títí di ọdún ìdásílẹ̀.

  6. Nígbà náà ni kí ó yọ̀ǹda òun àti àwọn ọmọ rẹ̀, kí wọ́n padà sí ìdílé wọn àti sí ilẹ̀ ìní baba wọn.

  7. “ ‘Àwọn ẹrúkùnrin àti ẹrúbìnrin yín lè jẹ́ láti orílẹ̀-èdè tí ó yí yín ká, ẹ lè ra àwọn ẹrú wọ̀nyí lọ́wọ́ wọn.

  8. Bákan náà, ẹ sì le è ra àwọn àlejò tí ń gbé láàrín yín, àti àwọn ìdílé wọn tí a bí sáàrín yín. Wọn yóò sì di ohun ìní yín.

  9. Ẹ lè fi wọ́n sílẹ̀ bí ogún fún àwọn ọmọ yín, wọ́n sì lè sọ wọ́n di ẹrú títí láé. Ṣùgbọ́n ẹ kò gbọdọ̀ rorò mọ́ ọmọ Israẹli kankan.

  10. “ ‘Bí àlejò kan láàrín yín tàbí ẹni tí ń gbé àárín yín fún ìgbà díẹ̀ bá lọ́rọ̀ tí ọmọ Israẹli sì tálákà dé bi pé ó ta ara rẹ̀ lẹ́rú fún àlejò tàbí ìdílé àlejò náà.

  11. Ó lẹ́tọ̀ọ́ si ki a rà á padà lẹ́yìn ìgbà tí ó ti ta ara rẹ̀. Ọ̀kan nínú ìbátan rẹ̀ le è rà á padà.

  12. Àbúrò baba rẹ̀ ọkùnrin tàbí àbúrò rẹ̀ obìnrin tàbí ẹnikẹ́ni tí ó bá tan nínú ìdílé rẹ̀ le è rà wọ̀n padà. Bí ó bá sì ti lọ́rọ̀, ó lè ra ara rẹ̀ padà.

  13. Kí òun àti olówó rẹ̀ ka iye ọdún tí ó ta ara rẹ̀ títí dé ọdún ìdásílẹ̀ kí iye owó ìdásílẹ̀ rẹ̀ jẹ́ iye tí wọ́n ń san lórí alágbàṣe fún iye ọdún náà.

  14. Bí iye ọdún rẹ̀ tí ó ṣẹ́kù bá pọ̀, kí iye owó fún ìràpadà rẹ̀ pọ̀.

  15. Bí ó bá sì ṣe pé kìkì ọdún díẹ̀ ni ó kù títí di ọdún jubili, kí ó ṣe ìṣirò rẹ̀, kí ó sì san owó náà bí iye ìṣirò rẹ̀ padà.

  16. Bí ẹ ti ń ṣe sí i lọ́dọọdún, ẹ rí i dájú pé olówó rẹ̀ kò korò mọ́ ọ.

  17. “ ‘Bí a kò bá rà á padà nínú gbogbo ọ̀nà wọ̀nyí, kí ẹ tú òun àti àwọn ọmọ rẹ̀ sílẹ̀ ní ọdún ìdásílẹ̀.

  18. Nítorí pé ìránṣẹ́ ni àwọn ọmọ Israẹli jẹ́ fún mi. Ìránṣẹ́ mi ni wọ́n, tí mo mú jáde láti Ejibiti wá. Èmi ni Olúwa Ọlọ́run yín.

  19. Ìwọ kò gbọdọ̀ ṣe ojúkòkòrò sí aya ẹnìkéjì rẹ, bẹ́ẹ̀ ni ìwọ kò gbọdọ̀ ṣe ojúkòkòrò sí ilé ẹnìkéji rẹ, oko rẹ̀, àti ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ̀ ọkùnrin, àti ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ̀ obìnrin, akọ màlúù rẹ̀ àti kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ rẹ̀, àti ohun gbogbo tí í ṣe ti ẹnìkéji rẹ.”

  20. Bí kò ṣe kí ẹ jẹ ẹ́ níwájú Olúwa Ọlọ́run yín, níbi tí Olúwa Ọlọ́run yín, yóò yàn: ìwọ, àwọn ọmọkùnrin rẹ, àwọn ọmọbìnrin rẹ, àwọn ìránṣẹ́kùnrin àti ìránṣẹ́bìnrin rẹ àti àwọn ọmọ Lefi láti ìlú u yín, kí ẹ sì máa yọ̀ níwájú Olúwa Ọlọ́run yín, nínú gbogbo ìdáwọ́lé e yín.

  21. Bí Heberu ara yín kan, yálà ọkùnrin tàbí obìnrin bá ta ara rẹ̀ fún ọ, tí ó sì sìn ọ́ fún ọdún mẹ́fà. Ní ọdún keje, jẹ́ kí ó di òmìnira.

  22. Nígbà tí ó bá dá a sílẹ̀ má ṣe jẹ́ kí ó lọ lọ́wọ́ òfo.

  23. Fi tọkàntọkàn fún un láti inú agbo ewúrẹ́ rẹ, ilẹ̀ ìpakà rẹ, àti ibi ìfúntí rẹ. Fún un gẹ́gẹ́ bí Olúwa Ọlọ́run rẹ ti bùkún fún ọ tó.

  24. Ṣùgbọ́n bí ìránṣẹ́ rẹ bá sọ fún ọ pé, “Èmi kò fẹ́ fi ọ́ sílẹ̀,” nítorí pé ó fẹ́ràn ìwọ àti ìdílé rẹ, tí ó sì tẹ́ ọ lọ́rùn,

  25. kí ìwọ kí ó mú ìlu kan lu etí rẹ̀ mọ́ ara ìlẹ̀kùn, yóò sì di ẹrú rẹ láéláé. Bẹ́ẹ̀ náà ni kí o ṣe sí ìránṣẹ́ ẹrúbìnrin rẹ.