Skip to content

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Servants

291 ẹsẹ · 147 abala

Àwọn ẹsẹ Bíbélì pàtàkì

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Ohunkóhun tí ẹ̀yin bá ń ṣe, ẹ máa fi tọkàntọkàn ṣe é fún Olúwa, kí í ṣe fún ènìyàn;

  2. kí ẹ mọ̀ pé lọ́wọ́ Olúwa ni ẹ̀yin ó gba èrè, nítorí ẹ̀yin ń sìn Olúwa Kristi.

  3. fún àwọn àgbèrè, fún àwọn aláyídà, fún àwọn onísòwò-ẹrú, fún àwọn èké, fún àwọn abúra èké, àti bí ohun mìíràn bá wà tí ó lòdì sí ẹ̀kọ́ tí ó yè kooro.

  4. Jẹ́ kí gbogbo àwọn tí i ṣe ẹrú lábẹ́ ìsìnrú máa ka àwọn olówó tí ó ni wọ́n yẹ sí ọlá gbogbo, kí a má bà á sọ̀rọ̀-òdì sí orúkọ Ọlọ́run àti ẹ̀kọ́ rẹ̀.

  5. Àwọn ti ó ní ọ̀gá onígbàgbọ́, kí wọn má ṣe ṣàìbọ̀wọ̀ fún wọn nítorí tí wọn jẹ́ arákùnrin; ṣùgbọ́n kí wọn túbọ̀ máa sìn wọ́n, nítorí àwọn tí í ṣe alábápín iṣẹ́ rere wọn jẹ́ onígbàgbọ́ àti olùfẹ́. Nǹkan wọ̀nyí ni kí ó máa kọ́ ni, kí o sì máa fi gbani níyànjú.

  6. Kọ́ àwọn ẹrú láti ṣe ìgbọ́ràn sí àwọn olówó wọn nínú ohun gbogbo, láti máa gbìyànjú láti tẹ́ wọn lọ́rùn, wọn kò gbọdọ̀ gbó olówó wọn lẹ́nu,

  7. wọn kò gbọdọ̀ jà wọ́n lólè ohunkóhun, ṣùgbọ́n kí wọ́n jẹ́ ẹni tó ṣe é gbẹ́kẹ̀lé, kí wọn ó làkàkà ní gbogbo ọ̀nà láti jẹ́ kí ìkọ́ni nípa Ọlọ́run àti Olùgbàlà ní ìtumọ̀ rere.

  8. Nígbà kan rí, kò wúlò fún ọ, ṣùgbọ́n ní báyìí, ó ti wúlò fún ọ àti fún èmi pàápàá.

  9. Kì í wá ṣe bí ẹrú mọ́, ṣùgbọ́n bí ẹni ti ó sàn ju ẹrú lọ, gẹ́gẹ́ bí arákùnrin. Ó ṣọ̀wọ́n fún mi jọjọ, ṣùgbọ́n ó ṣọ̀wọ́n fún ọ jù nípa ti ara àti gẹ́gẹ́ bí arákùnrin nínú Olúwa.

  10. Nítorí náà nígbà tí Kristi wá sí ayé, ó wí pé, “Ìwọ kò fẹ́ ẹbọ àti ọrẹ, ṣùgbọ́n ara ni ìwọ ti pèsè fún mi,

  11. Kíyèsi i, ọ̀yà àwọn alágbàṣe tí wọ́n ti ṣe ìkórè oko yín, èyí tí ẹ kò san, ń ké rara; àti igbe àwọn tí ó ṣe ìkórè sì ti wọ inú etí Olúwa àwọn ọmọ-ogun.

  12. Ẹ̀yin ọmọ ọ̀dọ̀, ẹ máa tẹríba fún àwọn ọ̀gá yín pẹ̀lú ìbẹ̀rù gbogbo, kì í ṣe fún àwọn ẹni rere àti oníwà tútù nìkan, ṣùgbọ́n fún àwọn òǹrorò pẹ̀lú.

  13. Nítorí pé èyí ní ìgbóríyìn fún, bí ènìyàn bá fi ara da ìrora, ìjìyà lọ́nà àìtọ́, nítorí ọkàn rere sí Ọlọ́run.

  14. Ṣùgbọ́n ògo kín ni ó jẹ́, nígbà tí ẹ ba ṣẹ̀ tí a sì lù yín, bí ẹ bá fi sùúrù gbà á? Ṣùgbọ́n nígbà tí ẹ̀yin bá ń ṣe rere tí ẹ sì ń jìyà, bí ẹ bá fi sùúrù gbà á, ẹ̀yín ní ọpẹ́ lọ́dọ̀ Ọlọ́run.

  15. Sí èyí ni a pè yín: nítorí Kristi pẹ̀lú jìyà fún un yin, ó fi àpẹẹrẹ sílẹ̀ fún un yín, kí ẹ̀yin lè máa tọ ipasẹ̀ rẹ̀:

  16. Wọn a máa ṣe ìlérí òmìnira fún wọn, nígbà tí àwọn pàápàá jẹ́ ẹrú ìdíbàjẹ́; nítorí ènìyàn tí di ẹrú ohunkóhun tí ó bá ṣe ọ̀gá rẹ̀.