Skip to content

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Servants

291 ẹsẹ · 147 abala

Àwọn ẹsẹ Bíbélì pàtàkì

Sẹ́ nípa ìwé
  1. “Èmi ó sì súnmọ́ yin fún ìdájọ́. Èmi yóò sì yára ṣe ẹlẹ́rìí sí àwọn oṣó, sí àwọn panṣágà, sí àwọn abúra èké, àti àwọn tí ó fi ọ̀yà alágbàṣe pọn wọn lójú, àti àwọn tí ó ni àwọn opó àti àwọn aláìní baba lára, àti sí ẹni tí kò jẹ́ kí àjèjì rí ìdájọ́ òdodo gbà, tí wọn kò sì bẹ̀rù mi,” ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí.

  2. Ẹni tí ó wà lábẹ́ àṣẹ sá ni èmi, èmi sí ní ọmọ-ogun lẹ́yìn mi. Bí mo wí fún ẹni kan pé, ‘Lọ,’ a sì lọ, àti fún ẹni kejì pé, ‘Wá,’ a sì wá, àti fún ọmọ ọ̀dọ̀ mi pé, ‘Ṣe èyí,’ a sì ṣe é.”

  3. Nígbà tí kò tì í ní agbára láti san án, nígbà náà ni olúwa rẹ̀ pàṣẹ pé kí a ta òun àti ìyàwó àti àwọn ọmọ rẹ̀ pẹ̀lú gbogbo ohun tí ó ní láti fi san gbèsè náà.

  4. “Ṣùgbọ́n òun kọ̀ fún un. Ó pàṣẹ kí a mú ọkùnrin náà, kí a sì jù ú sínú túbú títí tí yóò fi san gbèsè náà tán pátápátá.

  5. Kò ha ṣe ẹ̀tọ́ fún ọ láti ṣàánú fún àwọn ẹlòmíràn, gẹ́gẹ́ bí èmi náà ti ṣàánú fún ọ?’

  6. “Nítorí ìjọba ọ̀run dàbí ọkùnrin tí ó jẹ́ baálé kan, tí ó jíjáde lọ ní kùtùkùtù òwúrọ̀, tí ó gba àwọn alágbàṣe sínú ọgbà àjàrà rẹ̀.

  7. Òun pinnu láti san dínárì kan fún iṣẹ́ òòjọ́ kan. Lẹ́yìn èyí ó sì rán wọn lọ sínú ọgbà àjàrà rẹ̀.

  8. “Ní wákàtí kẹta ọjọ́ bí ó ti ń kọjá níwájú ilé ìgbanisíṣẹ́, ó rí díẹ̀ nínú àwọn aláìríṣẹ́ tí wọ́n dúró ní ọjà.

  9. Gẹ́gẹ́ bí Ọmọ Ènìyàn kò ṣe wá sí ayé, kí ẹ lè ṣe ìránṣẹ́ fún un, ṣùgbọ́n láti ṣe ìránṣẹ́ fún yín, àti láti fi ẹ̀mí rẹ ṣe ìràpadà ọ̀pọ̀ ènìyàn.”

  10. Alábùkún fún ni ọmọ ọ̀dọ̀ ti olúwa rẹ̀ dé tí ó sì bá a lórí iṣẹ́ ṣíṣe.

  11. Tí ó sì bẹ̀rẹ̀ si í fi ìyà jẹ́ àwọn ìránṣẹ́ ẹlẹgbẹ́ rẹ̀, tí ó ń jẹ, tí ó sì ń mu àmupara.

  12. Nígbà náà ni olúwa ọmọ ọ̀dọ̀ yóò wá ní ọjọ́ àti wákàtí tí kò retí.

  13. Ó sì ké sí àwọn náà lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, wọ́n fi Sebede baba wọn sílẹ̀ nínú ọkọ̀ pẹ̀lú àwọn alágbàṣe, wọ́n sì tọ̀ ọ́ lẹ́yìn.

  14. Àwọn kan sì bẹ̀rẹ̀ sí í tu itọ́ sí i lára. Wọ́n dì í lójú. Wọ́n ń kàn án lẹ́ṣẹ̀ẹ́ lójú. Wọ́n fi ṣe ẹlẹ́yà pé, “Sọtẹ́lẹ̀!” Àwọn olùṣọ́ sì ń fi àtẹ́lẹwọ́ wọn gbá a lójú.

  15. Ẹ dúró sínú ilé náà, kí ẹ máa jẹ, kí ẹ sì máa mu ohunkóhun tí wọ́n bá fi fún yín, nítorí ọ̀yà alágbàṣe tọ́ sí i. Ẹ má ṣe lọ láti ilé dé ilé.

  16. “Ṣùgbọ́n nígbà tí ojú rẹ̀ wálẹ̀, ó ní ‘Mélòó mélòó àwọn alágbàṣe baba mí ni ó ní oúnjẹ àjẹyó, àti àjẹtì, èmi sì ń kú fún ebi níhìn-ín.

  17. “Ẹni tí ó bá ṣe olóòtítọ́ nínú ohun kínkínní, ó ṣe olóòtítọ́ ní púpọ̀ pẹ̀lú: ẹni tí ó bá sì ṣe aláìṣòótọ́ ní ohun kínkínní, ó ṣe aláìṣòótọ́ ní ohun púpọ̀ pẹ̀lú.

  18. Ǹjẹ́ bí ẹ̀yin kò bá ti jẹ́ olóòtítọ́ nínú ọrọ̀ ayé yìí, ta ni yóò fi ọ̀rọ̀ tòótọ́ fún yín?

  19. Bí ẹ̀yin kò bá sì ti jẹ́ olóòtítọ́ nínú ohun tí í ṣe ti ẹlòmíràn, ta ni yóò fún yín ní ohun tí í ṣe ti ẹ̀yin tìkára yín?

  20. “Nígbà tí ó gba ìjọba tan, tí ó padà dé, ó pàṣẹ pé, kí a pe àwọn ọmọ ọ̀dọ̀ wọ̀nyí tí òun ti fi owó fún wá sọ́dọ̀ rẹ̀, nítorí kí ó le mọ iye èrè tí olúkúlùkù ti jẹ nínú iṣẹ́ òwò wọn.

  21. “Èyí èkínní sì wá, ó wí pé, ‘Olúwa, owó mina rẹ jèrè owó mina mẹ́wàá sí i.’

  22. “Èyí èkejì sì wá, ó wí pé, ‘Olúwa, owó mina rẹ jèrè owó mina márùn.’

  23. Nítorí ta ni ó pọ̀jù, ẹni tí ó jókòó tí oúnjẹ, tàbí ẹni tí ó ń ṣe ìránṣẹ́. Ẹni tí ó jókòó ti oúnjẹ kọ́ bí? Ṣùgbọ́n èmi ń bẹ láàrín yín bí ẹni tí ń ṣe ìránṣẹ́.

  24. Ṣùgbọ́n alágbàṣe, tí kì í ṣe olùṣọ́-àgùntàn, ẹni tí àwọn àgùntàn kì í ṣe tirẹ̀, ó rí ìkookò ń bọ̀, ó sì fi àgùntàn sílẹ̀, ó sì fọ́n wọn ká kiri.

  25. Òun sálọ nítorí tí ó jẹ́ alágbàṣe, kò sì náání àwọn àgùntàn.