Skip to content

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Samuel

135 ẹsẹ · 22 abala

Àwọn ẹsẹ Bíbélì pàtàkì

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Samuẹli sì wí fún wọn pé, “Olúwa ni ẹlẹ́rìí sí i yín, àti ẹni àmì òróró rẹ̀ ni ẹlẹ́rìí lónìí pé, ẹ̀yin kò rí ohunkóhun lọ́wọ́ mi.” Wọ́n sì sọ wí pé, “Òun ni ẹlẹ́rìí.”

  2. Samuẹli sì wí pé, “Kí ni ìwọ ṣe yìí.” Saulu sì dáhùn pé, “Nígbà tí mo rí pé àwọn ènìyàn náà ń túká, àti tí ìwọ kò sì wá ní àkókò ọjọ́ tí ìwọ dá, tí àwọn Filistini sì kó ara wọ́n jọ ní Mikmasi,

  3. mo rò pé, ‘Àwọn Filistini yóò sọ̀kalẹ̀ tọ̀ mí wá ní Gilgali nísinsin yìí, bẹ́ẹ̀ ni èmi kò ì tí ì wá ojúrere Olúwa.’ Báyìí ni mo mú ara mi ní ipá láti rú ẹbọ sísun náà.”

  4. Samuẹli sì wí fún un pé, “Ìwọ hu ìwà aṣiwèrè, ìwọ kò sì pa òfin tí Olúwa Ọlọ́run rẹ fi fún ọ mọ́; bí o kò bá ṣe bẹ́ẹ̀, òun ìbá fi ìdí ìjọba rẹ kalẹ̀ lórí Israẹli láéláé.

  5. Ṣùgbọ́n nísinsin yìí ìjọba rẹ kì yóò dúró pẹ́, Olúwa ti wá ọkùnrin tí ó wù ú ní ọkàn rẹ̀ fún ara rẹ̀, ó sì ti yàn án láti ṣe olórí fún àwọn ènìyàn rẹ̀, nítorí pé ìwọ kò pa òfin Olúwa mọ́.”

  6. Nígbà náà ni Samuẹli kúrò ní Gilgali, ó sì gòkè lọ sí Gibeah ti Benjamini, Saulu sì ka àwọn ènìyàn tí ó wà lọ́dọ̀ rẹ̀, wọ́n sì jẹ́ ẹgbẹ̀ta (600).

  7. Nígbà tí Dafidi ti sálọ tí ó sì ti bọ́, ó sì lọ sọ́dọ̀ Samuẹli ní Rama ó sì sọ gbogbo ohun tí Saulu ti ṣe fún un. Òun àti Samuẹli lọ sí Naioti láti dúró níbẹ̀.

  8. Samuẹli sì kú; gbogbo ènìyàn Israẹli sì kó ara wọn jọ, wọ́n sì sọkún rẹ̀ wọ́n sì sin ín nínú ilé rẹ̀ ní Rama. Dafidi sì dìde, ó sì sọ̀kalẹ̀ lọ sí ijù Parani.

  9. Samuẹli sì ti kú, gbogbo Israẹli sì sọkún rẹ̀, wọ́n sì sin ín ní Rama ní ìlú rẹ̀. Saulu sì ti mú àwọn abókùúsọ̀rọ̀ ọkùnrin, àti àwọn abókùúsọ̀rọ̀ obìnrin kúrò ní ilẹ̀ náà.

  10. Àwọn Filistini sì kó ara wọn jọ, wọ́n wá, wọ́n sì dó sí Ṣunemu: Saulu sì kó gbogbo Israẹli jọ, wọ́n sì tẹ̀dó ní Gilboa.

  11. Nígbà tí Saulu sì rí ogun àwọn Filistini náà òun sì bẹ̀rù, àyà rẹ̀ sì wárìrì gidigidi.

  12. Nígbà tí Saulu sì béèrè lọ́dọ̀ Olúwa, Olúwa kò dá a lóhùn nípa àlá, nípa Urimu tàbí nípa àwọn wòlíì.

  13. Saulu sì wí fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ pé, “Ẹ bá mi wá obìnrin kan tí ó ní ẹ̀mí abókùúsọ̀rọ̀ èmi yóò sì tọ̀ ọ́ lọ, èmi yóò béèrè lọ́wọ́ rẹ̀!” Àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ sì wí fún un pé, “Wò ó, obìnrin kan wà ní Endori tí ó ní ẹ̀mí abókùúsọ̀rọ̀.”

  14. Saulu sì pa ara dà, ó sì mú aṣọ mìíràn wọ̀, ó sì lọ, àwọn ọmọkùnrin méjì sì pẹ̀lú rẹ̀, wọ́n sì wá sí ọ̀dọ̀ obìnrin náà lóru: òun sì wí pé, “Èmi bẹ̀ ọ́, fi ẹ̀mí abókùúsọ̀rọ̀ wo nǹkan fún mi, kí o sì mú ẹni tí èmí ó dárúkọ rẹ̀ fún ọ wá sókè fún mi.”

  15. Obìnrin náà sì dá a lóhùn pé, “Wò ó, ìwọ sá à mọ ohun tí Saulu ṣe, bí òun ti gé àwọn abókùúsọ̀rọ̀ obìnrin, àti àwọn abókùúsọ̀rọ̀ ọkùnrin kúrò ní ilẹ̀ náà; ǹjẹ́ èéha ṣe tí ìwọ dẹkùn fún ẹ̀mí mi, láti mú kí wọ́n pa mí.”

  16. Saulu sì búra fún un nípa Olúwa pé, “Bí Olúwa ti ń bẹ láààyè, ìyà kan kì yóò jẹ́ ọ́ nítorí nǹkan yìí.”

  17. Obìnrin náà sì bi í pé, “Ta ni ẹ̀mí ó mú wá sókè fún ọ?” Òun sì wí pé, “Mú Samuẹli gòkè wá fún mi.”

  18. Nígbà tí obìnrin náà sì rí Samuẹli, ó kígbe lóhùn rara: obìnrin náà sì bá Saulu sọ̀rọ̀ pè, “Èéṣe tí ìwọ fi tàn mí jẹ? Nítorí pé Saulu ni ìwọ jẹ́.”

  19. Ọba sì wí fún un pé, “Má ṣe bẹ̀rù; kín ni ìwọ rí?” Obìnrin náà sì wí fún Saulu pé, “Èmi rí ọlọ́run kan tí ń ti ilẹ̀ wá.”

  20. Ó sì bi í pé, “Báwo ni ó ti rí i sí.” Ó sì wí pé, “Ọkùnrin arúgbó kan ni ó ń bọ; ó sì fi agbádá bora.” Saulu sì mọ̀ pé, Samuẹli ni; ó sì tẹríba, ó sì wólẹ̀.

  21. Samuẹli sì i wí fún Saulu pé, “Èéṣe tí ìwọ fi ń yọ mí lẹ́nu láti mú mi wá sókè?” Saulu sì dáhùn ó sì wí pé, “Ìpọ́njú ńlá bá mi; nítorí tí àwọn Filistini ń bá mi jagun, Ọlọ́run sì kọ̀ mí sílẹ̀, kò sì dá mi lóhùn mọ́, nípa ọwọ́ àwọn wòlíì, tàbí nípa àlá; nítorí náà ni èmi ṣe pè ọ́, kí ìwọ lè fi ohun tí èmi yóò ṣe hàn mi.”

  22. Samuẹli sì wí pé, “Ó ti ṣe ń bi mí léèrè nígbà tí ó jẹ́ pé, Olúwa ti kọ̀ ọ́ sílẹ̀, o sì di ọ̀tá rẹ̀.

  23. Olúwa sì ṣe fún ara rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ó ti ti ipa ọwọ́ mi sọ: Olúwa sì yá ìjọba náà kúrò ní ọwọ́ rẹ̀, ó sì fi fún aládùúgbò rẹ́, àní Dafidi.

  24. Nítorí pé ìwọ kò gbọ́ ohùn Olúwa ìwọ kò sì ṣe iṣẹ́ ìbínú rẹ̀ sí Amaleki nítorí náà ni Olúwa sì ṣe nǹkan yìí sí ọ lónìí yìí.

  25. Olúwa yóò sì fi Israẹli pẹ̀lú ìwọ lé àwọn Filistini lọ́wọ́, ní ọ̀la ni ìwọ àti àwọn ọmọ rẹ ọkùnrin yóò pẹ̀lú mi: Olúwa yóò sì fi ogun Israẹli lé àwọn Filistini lọ́wọ́.”