Fò sí àkóónú

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Samuel: Reproves Saul; foretells that his kingdom shall not be established

5 ẹsẹ · 22 abala

Àwọn ẹsẹ nípa Reproves Saul; foretells that his kingdom shall not be established

  1. Samuẹli sì wí pé, “Kí ni ìwọ ṣe yìí.” Saulu sì dáhùn pé, “Nígbà tí mo rí pé àwọn ènìyàn náà ń túká, àti tí ìwọ kò sì wá ní àkókò ọjọ́ tí ìwọ dá, tí àwọn Filistini sì kó ara wọ́n jọ ní Mikmasi,

  2. mo rò pé, ‘Àwọn Filistini yóò sọ̀kalẹ̀ tọ̀ mí wá ní Gilgali nísinsin yìí, bẹ́ẹ̀ ni èmi kò ì tí ì wá ojúrere Olúwa.’ Báyìí ni mo mú ara mi ní ipá láti rú ẹbọ sísun náà.”

  3. Samuẹli sì wí fún un pé, “Ìwọ hu ìwà aṣiwèrè, ìwọ kò sì pa òfin tí Olúwa Ọlọ́run rẹ fi fún ọ mọ́; bí o kò bá ṣe bẹ́ẹ̀, òun ìbá fi ìdí ìjọba rẹ kalẹ̀ lórí Israẹli láéláé.

  4. Ṣùgbọ́n nísinsin yìí ìjọba rẹ kì yóò dúró pẹ́, Olúwa ti wá ọkùnrin tí ó wù ú ní ọkàn rẹ̀ fún ara rẹ̀, ó sì ti yàn án láti ṣe olórí fún àwọn ènìyàn rẹ̀, nítorí pé ìwọ kò pa òfin Olúwa mọ́.”

  5. Nígbà náà ni Samuẹli kúrò ní Gilgali, ó sì gòkè lọ sí Gibeah ti Benjamini, Saulu sì ka àwọn ènìyàn tí ó wà lọ́dọ̀ rẹ̀, wọ́n sì jẹ́ ẹgbẹ̀ta (600).